Jóòbù 24:1-25

  • Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ (1-25)

    • ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run ò yan àkókò?’ (1)

    • Ó ní Ọlọ́run fàyè gba ìwà ibi (12)

    • Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ fẹ́ràn òkùnkùn (13-17)

24  “Kí ló dé tí Olódùmarè ò yan àkókò?+ Kí ló dé tí àwọn tó mọ̀ ọ́n kò rí ọjọ́ rẹ̀?*  2  Àwọn èèyàn ń sún ààlà;+Wọ́n ń jí àwọn agbo ẹran gbé lọ sí ibi ìjẹko wọn.  3  Wọ́n ń lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àwọn ọmọ aláìníbaba* dà nù,Wọ́n sì ń gba akọ màlúù opó láti fi ṣe ìdúró.*+  4  Wọ́n ń fipá lé àwọn aláìní kúrò lọ́nà;Àfi kí àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ láyé sá pa mọ́ fún wọn.+  5  Àwọn aláìní ń wá oúnjẹ kiri bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó+ nínú aginjù;Wọ́n ń wá oúnjẹ kiri fún àwọn ọmọ wọn nínú aṣálẹ̀.  6  Àfi kí wọ́n kórè nínú oko ẹlòmíì,*Kí wọ́n sì pèéṣẹ́* nínú ọgbà àjàrà ẹni burúkú.  7  Ìhòòhò ni wọ́n ń sùn mọ́jú, wọn ò ní aṣọ;+Wọn ò rí nǹkan kan fi bora nígbà òtútù.  8  Òjò orí òkè mú kí wọ́n rin gbingbin;Wọ́n rọ̀ mọ́ àpáta torí wọn ò ríbi forí pa mọ́ sí.  9  Wọ́n já ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú;+Wọ́n sì gba aṣọ aláìní láti fi ṣe ìdúró,+ 10  Wọ́n fipá mú kí wọ́n máa rìn kiri ní ìhòòhò, láìwọ aṣọ,Ebi sì ń pa wọ́n, bí wọ́n ṣe gbé àwọn ìtí ọkà. 11  Wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láàárín àwọn ògiri ilẹ̀ onípele nínú ooru ọ̀sán gangan;*Wọ́n ń tẹ àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, síbẹ̀ òùngbẹ ń gbẹ wọ́n.+ 12  Àwọn tó ń kú lọ ń kérora nínú ìlú;Àwọn tó fara pa gan-an* ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́,+Àmọ́ Ọlọ́run ò ka èyí sí àìdáa.* 13  Àwọn kan wà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀;+Wọn ò mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀,Wọn kì í sì í tẹ̀ lé àwọn òpópónà rẹ̀. 14  Apààyàn dìde ní ojúmọmọ;Ó pa ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àti aláìní,+Ó sì ń jalè ní òru. 15  Ojú alágbèrè ń dúró de ìrọ̀lẹ́,+Ó ń sọ pé, ‘Kò sẹ́ni tó máa rí mi!’+ Ó sì ń bo ojú rẹ̀. 16  Wọ́n ń fọ́ ilé* nínú òkùnkùn;Wọ́n ń ti ara wọn mọ́lé ní ọ̀sán. Àjèjì ni wọ́n sí ìmọ́lẹ̀.+ 17  Torí bákan náà ni àárọ̀ àti òkùnkùn biribiri rí fún wọn;Wọ́n mọ àwọn ohun tó ń dẹ́rù bani nínú òkùnkùn biribiri. 18  Àmọ́ omi yára gbé wọn lọ.* Ègún máa wà lórí ilẹ̀ wọn.+ Wọn ò ní pa dà sí àwọn ọgbà àjàrà wọn. 19  Bí ọ̀gbẹlẹ̀ àti ooru ṣe ń mú kí yìnyín yọ́ kó sì gbẹ,Bẹ́ẹ̀ ni Isà Òkú* ń mú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ lọ!+ 20  Ìyá rẹ̀* máa gbàgbé rẹ̀; ìdin máa fi ṣe oúnjẹ. Wọn ò ní rántí rẹ̀ mọ́.+ A sì máa ṣẹ́ àìṣòdodo bí igi. 21  Ó ń rẹ́ àwọn àgàn jẹ,Ó sì ń ni opó lára. 22  Ọlọ́run* máa fi okun rẹ̀ mú àwọn alágbára kúrò;Bí wọ́n tiẹ̀ dìde, kò dájú pé wọ́n á ní ìyè. 23  Ọlọ́run* jẹ́ kí wọ́n dá ara wọn lójú, kí ọkàn wọn sì balẹ̀,+Àmọ́ ojú rẹ̀ tó gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.*+ 24  A gbé wọn ga fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, wọn ò sí mọ́.+ A rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,+ a sì kó wọn jọ bíi gbogbo èèyàn yòókù;A gé wọn kúrò bí orí ọkà. 25  Ta ló wá lè mú mi ní onírọ́,Tàbí kó sọ pé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣòótọ́?”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ìyẹn, ọjọ́ ìdájọ́ rẹ̀.
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Tàbí “ìdógò.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kórè oúnjẹ ẹran nínú oko.”
^ Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
^ Tàbí kó jẹ́, “Wọ́n ń fún òróró láàárín àwọn ògiri ilẹ̀ onípele.”
^ Tàbí “Ọkàn àwọn tó ṣèṣe.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Ọlọ́run ò fi ẹ̀sùn kan ẹnikẹ́ni.”
^ Ní Héb., “dá ilé lu.”
^ Ní Héb., “Ó yára lórí omi.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “Ilé ọlẹ̀.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “Ó.”
^ Ní Héb., “àwọn ọ̀nà wọn.”