Jóòbù 38:1-41

  • Jèhófà jẹ́ ká mọ bí èèyàn ṣe kéré tó (1-41)

    • ‘Ibo lo wà nígbà tí mo dá ayé?’ (4-6)

    • Àwọn ọmọ Ọlọ́run hó yèè, wọ́n yìn ín (7)

    • Ìbéèrè nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá (8-32)

    • “Àwọn òfin tó ń darí ọ̀run” (33)

38  Jèhófà wá dá Jóòbù lóhùn látinú ìjì,+ ó ní:   “Ta lẹni yìí tí kò jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi ṣe kedere,Tó ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀?+   Jọ̀ọ́, gbára dì, kí o ṣe bí ọkùnrin;Màá bi ọ́ ní ìbéèrè, kí o sì dá mi lóhùn.   Ibo lo wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?+ Sọ fún mi, tí o bá rò pé o mọ̀ ọ́n.   Ta ló díwọ̀n rẹ̀, tí o bá mọ̀ ọ́n,Àbí ta ló na okùn ìdíwọ̀n sórí rẹ̀?   Inú ibo ni a ri àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́,Àbí ta ló fi òkúta igun ilé rẹ̀ lélẹ̀,+   Nígbà tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀+ jọ fayọ̀ ké jáde,Tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run*+ sì bẹ̀rẹ̀ sí í hó yèè, tí wọ́n ń yìn ín?   Ta ló sì fi àwọn ilẹ̀kùn sé òkun,+Nígbà tó tú jáde látinú ikùn,*   Nígbà tí mo fi ìkùukùu wọ̀ ọ́ láṣọ,Tí mo sì fi ìṣúdùdù tó kàmàmà wé e, 10  Nígbà tí mo pààlà ibi tí mo fẹ́ kó dé,Tí mo sì fi àwọn ọ̀pá àtàwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ sáyè wọn,+ 11  Mo sì sọ pé, ‘Ibi tí o lè dé nìyí, má kọjá ibẹ̀;Ìgbì rẹ tó ń ru sókè kò ní kọjá ibí yìí’?+ 12  Ṣé o ti pàṣẹ fún òwúrọ̀ rí,*Àbí o ti mú kí ilẹ̀ tó ń mọ́ bọ̀ mọ àyè rẹ̀,+ 13  Láti di àwọn ìkángun ayé mú,Kó sì gbọn àwọn ẹni burúkú dà nù kúrò nínú rẹ̀?+ 14  Ó yí pa dà bí amọ̀ tí a gbé èdìdì lé,Àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ sì ṣe kedere bíi ti ara aṣọ. 15  Àmọ́ a mú ìmọ́lẹ̀ àwọn ẹni burúkú kúrò,A sì kán apá wọn tí wọ́n gbé sókè. 16  Ṣé o ti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí àwọn orísun òkun,Àbí o ti lọ káàkiri inú ibú omi?+ 17  Ṣé a ti fi àwọn ẹnubodè ikú+ hàn ọ́ rí,Àbí o ti rí àwọn ẹnubodè òkùnkùn biribiri?*+ 18  Ǹjẹ́ o mọ bí ayé ṣe tóbi tó?+ Sọ fún mi, tí o bá mọ gbogbo èyí. 19  Apá ibo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé?+ Ibo sì ni òkùnkùn wà, 20  Tí o fi máa mú un lọ sí ilẹ̀ rẹ̀,Tí wàá sì mọ àwọn ọ̀nà tó lọ sí ilé rẹ̀? 21  Ṣé o mọ èyí torí pé wọ́n ti bí ọ,Tí iye ọdún* rẹ sì pọ̀ gan-an? 22  Ṣé o ti wọ àwọn ibi tí mo kó yìnyín jọ sí,+Àbí o ti rí àwọn ibi tí mo kó òkúta yìnyín jọ sí,+ 23  Èyí tí mo tọ́jú de ìgbà wàhálà,De ọjọ́ ìjà àti ogun?+ 24  Apá ibo ni ìmọ́lẹ̀* ti ń jáde wá,Ibo sì ni atẹ́gùn ìlà oòrùn ti ń fẹ́ wá sí ayé?+ 25  Ta ló la ọ̀nà fún àkúnya omi,Tó sì la ọ̀nà fún ìjì tó ń sán ààrá látojú ọ̀run,+ 26  Kí òjò lè rọ̀ síbi tí èèyàn kankan ò gbé,Sí aginjù níbi tí kò sí èèyàn kankan,+ 27  Kó lè tẹ́ ilẹ̀ tó ti di ahoro lọ́rùn,Kó sì mú kí koríko hù?+ 28  Ǹjẹ́ òjò ní bàbá,+Ta sì ni bàbá ìrì tó ń sẹ̀?+ 29  Látinú ilé ọlẹ̀ ta ni yìnyín ti jáde,Ta ló sì bí yìnyín wínníwínní ojú ọ̀run,+ 30  Nígbà tó dà bíi pé òkúta ló bo omi,Tí ojú ibú omi sì dì gbagidi?+ 31  Ṣé o lè so àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Kímà,*Àbí o lè tú àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì?*+ 32  Ṣé o lè kó àgbájọ ìràwọ̀* jáde ní àsìkò rẹ̀,Àbí o lè darí àgbájọ ìràwọ̀ Ááṣì* pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀? 33  Ṣé o mọ àwọn òfin tó ń darí ojú ọ̀run,+Àbí o lè fipá mú kí ayé tẹ̀ lé àwọn àṣẹ wọn?* 34  Ṣé o lè ké sí ìkùukùuPé kó mú kí àkúnya omi bò ọ́ mọ́lẹ̀?+ 35  Ṣé o lè rán mànàmáná jáde? Ṣé wọ́n á wá sọ fún ọ pé, ‘Àwa rèé!’ 36  Ta ló fi ọgbọ́n sínú àwọn ìkùukùu,*+Àbí ta ló fún àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run* ní òye?+ 37  Ta ló gbọ́n débi tó fi lè ka àwọn ìkùukùu,*Àbí ta ló lè da omi inú àwọn ìṣà omi ojú ọ̀run,+ 38  Tí eruku bá kóra jọ,Tí àwọn ìṣùpọ̀ iyẹ̀pẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ra? 39  Ṣé o lè ṣọdẹ ẹran fún kìnnìún,Àbí kí o fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ kìnnìún lọ́rùn,+ 40  Tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ sínú ilé wọn,Tàbí tí wọ́n lúgọ sínú ibùba wọn? 41  Ta ló ń pèsè oúnjẹ fún ẹyẹ ìwò,+Tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá ń ké jáde sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́,Tí wọ́n sì ń rìn kiri torí wọn ò rí nǹkan jẹ?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Àkànlò èdè Hébérù tó ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.
Ní Héb., “ilé ọlẹ̀.”
Ní Héb., “láwọn ọjọ́ rẹ.”
Tàbí “òjìji ikú.”
Ní Héb., “ọjọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “mànàmáná.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìràwọ̀ Píléádésì ní àgbájọ ìràwọ̀ Taurus.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Óríónì.
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Béárì Ńlá (ìyẹn, Ursa Major).
Ní Héb., “Másárótì.” Ní 2Ọb 23:5, ọ̀rọ̀ tó jọ èyí, tí wọ́n sì máa ń lò fún ohun tó bá pọ̀ ń tọ́ka sí àwọn àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì.
Tàbí kó jẹ́, “Rẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “sínú èèyàn.”
Tàbí kó jẹ́, “fún ọkàn.”
Tàbí “àwọsánmà.”