Jóòbù 8:1-22

  • Ọ̀rọ̀ tí Bílídádì kọ́kọ́ sọ (1-22)

    • Ó sọ pé àwọn ọmọ Jóòbù ti ṣẹ̀ (4)

    • ‘Tí o bá mọ́, Ọlọ́run máa dáàbò bò ọ́’ (6)

    • Ó sọ pé Jóòbù kò mọ Ọlọ́run (13)

8  Bílídádì+ ọmọ Ṣúáhì+ wá fèsì pé:   “Ìgbà wo lo ò ní sọ̀rọ̀ báyìí mọ́?+ Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dà bí ìjì tó le!   Ṣé Ọlọ́run máa yí ìdájọ́ po ni,Àbí Olódùmarè máa yí òdodo po?   Tó bá jẹ́ pé àwọn ọmọ rẹ ti ṣẹ̀ ẹ́,Ó jẹ́ kí wọ́n jìyà ìwà ọ̀tẹ̀ wọn;*   Àmọ́ tí o bá lè yíjú sí Ọlọ́run,+Kí o sì bẹ Olódùmarè pé kó ṣojúure sí ọ,   Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lo mọ́, tí o sì jẹ́ olódodo,+Ó máa fetí sí ọ,*Ó sì máa dá ọ pa dà sí ibi tó tọ́ sí ọ.   Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbẹ̀rẹ̀ rẹ kéré,Ọjọ́ iwájú rẹ máa dára gan-an.+   Jọ̀ọ́, béèrè lọ́wọ́ ìran àtijọ́,Kí o sì fiyè sí àwọn ohun tí àwọn bàbá wọn rí.+   Torí ọmọ àná lásán ni wá, a ò sì mọ nǹkan kan,Torí pé òjìji ni àwọn ọjọ́ ayé wa. 10  Ṣé wọn ò ní kọ́ ọ ni,Kí wọ́n sì sọ ohun tí wọ́n mọ̀ fún ọ?* 11  Ṣé òrépèté lè dàgbà níbi tí kò sí irà? Ṣé esùsú* lè dàgbà láìsí omi? 12  Nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń rú yọ, tí wọn ò tíì já a,Ó máa gbẹ dà nù ṣáájú gbogbo ewéko yòókù. 13  Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó gbàgbé Ọlọ́run nìyẹn,*Torí ìrètí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* máa ṣègbé, 14  Ẹni tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ já sí asán,Tí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ ò sì lágbára, àfi bí òwú* aláǹtakùn. 15  Ó máa fara ti ilé rẹ̀, àmọ́ kò ní lè dúró;Ó máa fẹ́ dì í mú, àmọ́ kò ní wà pẹ́. 16  Ó dà bí ewéko tútù nínú oòrùn,Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gbalẹ̀ nínú ọgbà.+ 17  Gbòǹgbò rẹ̀ lọ́ mọ́ra láàárín òkúta tí wọ́n kó jọ pelemọ;Ó ń wá ilé láàárín àwọn òkúta.* 18  Àmọ́ tí wọ́n bá ti fà á tu* kúrò níbi tó wà,Ibẹ̀ máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó sì máa sọ fún un pé, ‘Mi ò rí ọ rí.’+ 19  Àní, bí a ò ṣe ní rí i mọ́+ nìyẹn;*Àwọn míì á wá hù jáde látinú ilẹ̀. 20  Ó dájú pé Ọlọ́run ò ní kọ àwọn olóòótọ́* sílẹ̀;Kò sì ní ti àwọn ẹni ibi lẹ́yìn,* 21  Torí ó ṣì máa fi ẹ̀rín kún ẹnu rẹ,Ó sì máa mú kí ètè rẹ kígbe ayọ̀. 22  Ìtìjú máa bo àwọn tó kórìíra rẹ,Àgọ́ àwọn ẹni burúkú ò sì ní sí mọ́.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Ó fi wọ́n lé ọ̀tẹ̀ wọn lọ́wọ́.”
Tàbí “ta ara rẹ̀ jí fún ọ.”
Ní Héb., “Kí wọ́n sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá?”
Ìyẹn, koríko etí omi.
Ní Héb., “Báyìí ni ọ̀nà gbogbo àwọn tó gbàgbé Ọlọ́run.”
Tàbí “apẹ̀yìndà.”
Ní Héb., “ilé.”
Tàbí “Ó ń wo ilé olókùúta.”
Tàbí “gbé e mì.”
Tàbí “bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe máa yọ́ nìyẹn.”
Tàbí “aláìlẹ́bi.”
Ní Héb., “di ọwọ́ àwọn ẹni ibi mú.”