Jóòbù 29:1-25

  • Jóòbù rántí bí nǹkan ṣe ń dùn kí àdánwò tó dé (1-25)

    • Ó jẹ́ èèyàn pàtàkì ní ẹnubodè (7-10)

    • Bó ṣe máa ń fi òdodo ṣèdájọ́ (11-17)

    • Gbogbo èèyàn máa ń gbọ́ ìmọ̀ràn rẹ̀ (21-23)

29  Jóòbù ń bá ọ̀rọ̀* rẹ̀ lọ, ó ní:   “Ká sọ pé àwọn oṣù tó ti kọjá ni mo wà,Láwọn ọjọ́ tí Ọlọ́run ń ṣọ́ mi,   Nígbà tó mú kí fìtílà rẹ̀ tàn sí mi lórí,Nígbà tí mo fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ rìn nínú òkùnkùn,+   Nígbà tí mo ṣì lókun,*Nígbà tí mo mọ bó ṣe ń rí kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nínú àgọ́ mi,+   Nígbà tí Olódùmarè ṣì wà pẹ̀lú mi,Nígbà tí àwọn ọmọ* mi yí mi ká,   Nígbà tí bọ́tà bo àwọn ìṣísẹ̀ mi,Tí àwọn àpáta sì ń tú ìṣàn òróró jáde fún mi.+   Nígbà tí mo ṣì máa ń jáde lọ sí ẹnubodè ìlú,+Tí mo sì máa ń jókòó sí ojúde ìlú,+   Àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa rí mi, wọ́n á sì yà sẹ́gbẹ̀ẹ́,*Àwọn àgbà ọkùnrin pàápàá máa dìde, wọ́n á sì wà ní ìdúró.+   Àwọn ìjòyè máa ń dákẹ́;Wọ́n á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn. 10  Àwọn gbajúmọ̀ ọkùnrin panu mọ́;Ahọ́n wọn lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn. 11  Ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ mi máa ń sọ̀rọ̀ mi dáadáa,Àwọn tó sì rí mi máa ń ṣe ẹlẹ́rìí mi. 12  Torí mo máa ń gba aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀,+Pẹ̀lú ọmọ aláìníbaba* àti ẹnikẹ́ni tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+ 13  Ẹni tó ń kú lọ máa ń súre fún mi,+Mo sì ń mú kí inú opó dùn.+ 14  Mo wọ òdodo bí aṣọ;Ìdájọ́ òdodo mi dà bí ẹ̀wù* àti láwàní. 15  Mo di ojú fún afọ́júÀti ẹsẹ̀ fún arọ. 16  Mo jẹ́ bàbá fún àwọn aláìní;+Mo máa ń wádìí ẹjọ́ àwọn tí mi ò mọ̀.+ 17  Mo máa ń fọ́ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹni burúkú,+Mo sì máa ń já ẹran gbà kúrò ní eyín rẹ̀. 18  Mo máa ń sọ pé, ‘Inú ilé mi* ni màá kú sí,+Ọjọ́ ayé mi á sì pọ̀ bí iyanrìn. 19  Màá ta gbòǹgbò wọnú omi,Ìrì á sì wà lórí àwọn ẹ̀ka mi mọ́jú. 20  Ògo mi ń di ọ̀tun ní gbogbo ìgbà,Màá sì máa ta ọfà ọwọ́ mi léraléra.’ 21  Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́ mi,Wọ́n á dákẹ́, wọ́n á máa retí ìmọ̀ràn mi.+ 22  Tí mo bá ti sọ̀rọ̀, wọn kì í tún ní ohunkóhun láti sọ;Ọ̀rọ̀ mi máa ń rọra wọ̀ wọ́n* létí. 23  Wọ́n ń dúró dè mí bí ẹni ń dúró de òjò;Wọ́n la ẹnu wọn sílẹ̀ gbayawu bíi fún òjò ìrúwé.+ 24  Nígbà tí mo rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an;Ìmọ́lẹ̀ ojú mi máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.* 25  Mò ń darí wọn gẹ́gẹ́ bí olórí wọn,Mo sì ń gbé bí ọba láàárín àwọn ọmọ ogun rẹ̀,+Bí ẹni tó ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “òwe.”
Ní Héb., “ṣì wà ní àwọn ọjọ́ tí mo lókun.”
Tàbí “ìránṣẹ́.”
Ní Héb., “fara pa mọ́.”
Tàbí “aláìlóbìí.”
Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”
Ní Héb., “ìtẹ́ mi.”
Ní Héb., “kán sí wọn.”
Tàbí kó jẹ́, “Wọn ò mú kí ìmọ́lẹ̀ ojú mi ṣókùnkùn.”