Jóòbù 23:1-17

  • Jóòbù fèsì (1-17)

    • Ó fẹ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ níwájú Ọlọ́run (1-7)

    • Ó ní òun ò rí Ọlọ́run (8, 9)

    • “Mò ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ ṣáá, mi ò sì yà kúrò níbẹ̀” (11)

23  Jóòbù fèsì pé:   “Àní lónìí, màá fi orí kunkun ṣàròyé;*+ Okun mi ti tán torí ẹ̀dùn ọkàn mi.   Ká ní mo mọ ibi tí mo ti lè rí Ọlọ́run ni!+ Ǹ bá lọ sí ibùgbé rẹ̀.+   Màá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀,Màá sì fi gbogbo ẹnu mi gbèjà ara mi;   Màá fetí sí ìdáhùn tó bá fún mi,Màá sì fọkàn sí ohun tó bá sọ fún mi.   Ṣé ó máa fi agbára ńlá rẹ̀ bá mi jà? Rárá, ó dájú pé ó máa gbọ́ mi.+   Ibẹ̀ ni òun àti olóòótọ́ ti máa lè yanjú ọ̀rọ̀,Adájọ́ mi sì máa dá mi láre títí láé.   Àmọ́ tí mo bá lọ sí ìlà oòrùn, kò sí níbẹ̀;Mo pa dà, mi ò sì rí i.   Nígbà tó ń ṣiṣẹ́ lápá òsì, mi ò lè rí i;Ó wá yí sí apá ọ̀tún, síbẹ̀ mi ò rí i. 10  Àmọ́, ó mọ ọ̀nà tí mo gbà.+ Lẹ́yìn tó bá dán mi wò, màá wá dà bíi wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́.+ 11  Ẹsẹ̀ mi tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí;Mò ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ ṣáá, mi ò sì yà kúrò níbẹ̀.+ 12  Mi ò pa àṣẹ ẹnu rẹ̀ tì. Mò ń pa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́+ ju ohun tó béèrè lọ́wọ́ mi* pàápàá. 13  Tó bá ti pinnu, ta ló lè dá a dúró?+ * bá fẹ́ ṣe ohun kan, ó máa ṣe é.+ 14  Torí ó máa ṣe gbogbo ohun tó ti pinnu* nípa mi,Irú nǹkan wọ̀nyí sì pọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. 15  Ìdí nìyẹn tí ọkàn mi ò fi balẹ̀ nítorí rẹ̀;Tí mo bá ronú nípa rẹ̀, ẹ̀rù á túbọ̀ bà mí. 16  Ọlọ́run ti sọ mí di ojo,Olódùmarè sì ti mú kí ẹ̀rù bà mí. 17  Àmọ́ òkùnkùn ò tíì pa mí lẹ́nu mọ́,Ìṣúdùdù tó bò mí lójú kò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìṣọ̀tẹ̀ ni àròyé mi.”
Tàbí “ohun tó pa láṣẹ fún mi.”
Tàbí “Tí ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “ohun tó ti pa láṣẹ.”