Jóòbù 12:1-25
12 Jóòbù wá fèsì pé:
2 “Ó dájú pé ẹ̀yin lẹ ní ìmọ̀,*Ọgbọ́n sì máa bá yín kú!
3 Àmọ́ èmi náà ní òye.*
Mi ò kéré sí yín,Ta ni ò mọ àwọn nǹkan yìí?
4 Mo wá di ẹni tí àwọn ọ̀rẹ́ fi ń ṣe ẹlẹ́yà,+Ẹni tó ń ké pe Ọlọ́run pé kó dáhùn.+
Ẹni tó jẹ́ olódodo àti aláìlẹ́bi ni wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà.
5 Ẹni tí ara máa ń tù kórìíra àjálù,Ó rò pé àwọn tí ẹsẹ̀ wọn ò múlẹ̀* nìkan ló máa ń dé bá.
6 Àgọ́ àwọn olè wà ní àlàáfíà,+Àwọn tó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìséwu,+Àwọn tí ọlọ́run wọn wà ní ọwọ́ wọn.
7 Àmọ́ jọ̀ọ́, bi àwọn ẹranko, wọ́n á sì kọ́ ọ;Àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, wọ́n á sì sọ fún ọ.
8 Tàbí kí o fiyè sí ayé,* ó sì máa kọ́ ọ;Àwọn ẹja inú òkun sì máa kéde rẹ̀ fún ọ.
9 Èwo nínú gbogbo àwọn yìí ni kò mọ̀Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí?
10 Ọwọ́ rẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo ohun alààyè* wàÀti ẹ̀mí* gbogbo èèyàn.*+
11 Ṣebí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò,Bí ahọ́n* ṣe ń tọ́ oúnjẹ wò?+
12 Ṣebí ọ̀dọ̀ àwọn àgbà+ la ti ń rí ọgbọ́n,Ṣebí ẹ̀mí gígùn sì ń mú kéèyàn ní òye?
13 Ọgbọ́n àti agbára ńlá wà lọ́dọ̀ rẹ̀;+Ó ní ìmọ̀ràn àti òye.+
14 Tó bá ya nǹkan lulẹ̀, kò ṣeé tún kọ́;+Tó bá ti nǹkan pa, èèyàn kankan ò lè ṣí i.
15 Tó bá dá omi dúró, ohun gbogbo á gbẹ;+Tó bá sì rán an jáde, á bo ayé.+
16 Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni agbára àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ wà;+Òun ló ni ẹni tó ń ṣìnà àti ẹni tó ń kóni ṣìnà;
17 Ó ń mú kí àwọn agbani-nímọ̀ràn lọ láìwọ bàtà,*Ó ń sọ àwọn adájọ́ di òmùgọ̀.+
18 Ó ń tú ìdè tí àwọn ọba fi deni,+Ó sì ń de àmùrè mọ́ ìgbáròkó wọn.
19 Ó ń mú kí àwọn àlùfáà rìn láìwọ bàtà,+Ó sì ń gbàjọba lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fìdí múlẹ̀ gbọn-in nípò agbára;+
20 Ó ń pa àwọn agbani-nímọ̀ràn tí wọ́n fọkàn tán lẹ́nu mọ́,Ó sì ń gba làákàyè àwọn àgbà ọkùnrin;*
21 Ó ń rọ̀jò àbùkù sórí àwọn èèyàn pàtàkì,+Ó sì ń mú kó rẹ àwọn alágbára;*
22 Ó ń tú àwọn ohun tó jinlẹ̀ síta látinú òkùnkùn,+Ó sì ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri;
23 Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, kó lè pa wọ́n run;Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tóbi sí i, kó lè kó wọn lọ sí ìgbèkùn.
24 Ó ń gba òye* àwọn olórí àwọn èèyàn,Ó sì ń mú kí wọ́n rìn kiri ní ilẹ̀ tó ti di ahoro, tí kò sì lójú ọ̀nà.+
25 Wọ́n ń táràrà nínú òkùnkùn,+ níbi tí kò ti sí ìmọ́lẹ̀;Ó ń mú kí wọ́n máa rìn gbéregbère bí ọ̀mùtípara.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “ẹ̀yin ni àwọn èèyàn náà.”
^ Ní Héb., “ọkàn.”
^ Tàbí “tí ẹsẹ̀ wọn ń yọ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “bá ayé sọ̀rọ̀.”
^ Tàbí “ọkàn gbogbo ẹni tó wà láàyè.”
^ Tàbí “èémí.”
^ Ní Héb., “gbogbo ẹran ara èèyàn.”
^ Ní Héb., “òkè ẹnu.”
^ Tàbí “láìsí nǹkan kan lára wọn.”
^ Tàbí “àwọn àgbààgbà.”
^ Ní Héb., “tú àmùrè àwọn alágbára.”
^ Ní Héb., “ọkàn.”

