Jóòbù 16:1-22
16 Jóòbù fèsì pé:
2 “Mo ti gbọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan báyìí rí.
Olùtùnú tó ń dani láàmú ni gbogbo yín!+
3 Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ asán* lópin ni?
Kí ló ń bí ẹ nínú tí o fi ń fèsì báyìí?
4 Èmi náà lè sọ̀rọ̀ bíi tiyín.
Ká ní ẹ̀yin lẹ wà ní ipò tí mo wà,*Mo lè sọ̀rọ̀ sí yín, tó máa mú kí ẹ ronú,Mo sì lè mi orí sí yín.+
5 Kàkà bẹ́ẹ̀, màá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi fún yín lókun,Ìtùnú ètè mi á sì mú kí ara tù yín.+
6 Tí mo bá sọ̀rọ̀, kò dín ìrora mi kù,+Tí mo bá sì dákẹ́, mélòó ló máa dín kù nínú ìrora mi?
7 Àmọ́, ó ti tán mi lókun báyìí;+Ó ti run gbogbo agbo ilé mi.*
8 O tún gbá mi mú, ó sì ti jẹ́rìí sí i,Débi pé ara mi tó rù kan eegun dìde, ó sì jẹ́rìí níṣojú mi.
9 Ìbínú rẹ̀ ti fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ó sì ń dì mí sínú.+
Ó ń wa eyín pọ̀ sí mi.
Ọ̀tá mi ń fi ojú rẹ̀ gún mi lára.+
10 Wọ́n ti la ẹnu wọn gbàù sí mi,+Tẹ̀gàntẹ̀gàn ni wọ́n sì gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́,Wọ́n kóra jọ rẹpẹtẹ láti ta kò mí.+
11 Ọlọ́run fi mí lé àwọn ọ̀dọ́kùnrin lọ́wọ́,Ó sì tì mí sọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.+
12 Wàhálà kankan ò bá mi, àmọ́ ó fọ́ mi sí wẹ́wẹ́;+Ó rá mi mú ní ẹ̀yìn ọrùn, ó sì fọ́ mi túútúú;Èmi ló dájú sọ.
13 Àwọn tafàtafà rẹ̀ yí mi ká;+Ó gún àwọn kíndìnrín mi,+ àánú ò sì ṣe é;Ó da òróòro mi sórí ilẹ̀.
14 Ó ń dá ihò sí mi lára, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn;Ó pa kuuru mọ́ mi bíi jagunjagun.
15 Mo ti rán aṣọ ọ̀fọ̀* pọ̀ láti fi bo ara mi,+Mo sì ti bo iyì* mi mọ́ inú iyẹ̀pẹ̀.+
16 Ojú mi ti pọ́n torí mò ń sunkún,+Òkùnkùn biribiri* sì wà ní ìpéǹpéjú mi,
17 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ mi ò hùwà ipá kankan,Àdúrà mi sì mọ́.
18 Ìwọ ilẹ̀, má bo ẹ̀jẹ̀ mi!+
Má sì jẹ́ kí igbe mi rí ibi ìsinmi kankan!
19 Kódà ní báyìí, ẹlẹ́rìí mi wà ní ọ̀run;Ẹni tó lè jẹ́rìí sí mi wà ní ibi tó ga.
20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi fi mí ṣe ẹlẹ́yà,+Bí mo ṣe ń da omi lójú sí Ọlọ́run.*+
21 Kí ẹnì kan gbọ́ ẹjọ́ èèyàn àti Ọlọ́runBí èèyàn ṣe ń gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan àti ẹnì kejì rẹ̀.+
22 Torí àwọn ọdún tó ń bọ̀ kéré,Màá sì gba ọ̀nà ibi tí mi ò ti ní pa dà wá mọ́.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọ̀rọ̀ líle.”
^ Tàbí “Tí ọkàn yín bá wà ní ipò tí ọkàn mi wà.”
^ Tàbí “àwọn tó kóra jọ sọ́dọ̀ mi.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “okun.” Ní Héb., “ìwo.”
^ Tàbí “Òjìji ikú.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Bí ojú mi ṣe ń wo Ọlọ́run, tí mi ò lè sùn.”