Jóòbù 40:1-24
40 Jèhófà ń fún Jóòbù lésì nìṣó pé:
2 “Ṣó yẹ kí ẹni tó ń wá ẹ̀sùn bá Olódùmarè fa ọ̀rọ̀?+
Kí ẹni tó fẹ́ bá Ọlọ́run wí fèsì.”+
3 Jóòbù dá Jèhófà lóhùn pé:
4 “Wò ó! Mi ò já mọ́ nǹkan kan.+
Kí ni màá fi dá ọ lóhùn?
Mo fi ọwọ́ bo ẹnu mi.+
5 Mo ti sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, àmọ́ mi ò ní dáhùn mọ́;Lẹ́ẹ̀kejì, mi ò sì ní sọ̀rọ̀ mọ́.”
6 Ni Jèhófà bá dá Jóòbù lóhùn látinú ìjì, ó ní:+
7 “Jọ̀ọ́, gbára dì, kí o ṣe bí ọkùnrin;Màá bi ọ́ ní ìbéèrè, kí o sì dá mi lóhùn.+
8 Ṣé o máa sọ pé mi ò ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́ ni?*
Ṣé o máa dá mi lẹ́bi kí o lè jàre?+
9 Ṣé o ní apá tó lágbára bíi ti Ọlọ́run tòótọ́,+
Àbí ṣé ohùn rẹ lè sán ààrá bíi tirẹ̀?+
10 Jọ̀ọ́, fi ògo àti ọlá ńlá ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́;Kí o sì fi iyì àti ẹwà wọ ara rẹ láṣọ.
11 Tú ìbínú rẹ tó ń ru jáde;Wo gbogbo ẹni tó ń gbéra ga, kí o sì rẹ̀ wọ́n nípò wálẹ̀.
12 Wo gbogbo ẹni tó ń gbéra ga, kí o sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,Kí o sì tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀ níbi tí wọ́n dúró sí.
13 Fi wọ́n pa mọ́ sínú erùpẹ̀;Dè wọ́n* síbi tó fara sin,
14 Nígbà náà, èmi pàápàá á sọ fún ọ* pé,Ọwọ́ ọ̀tún rẹ lè gbà ọ́ là.
15 Wò ó, Béhémótì* nìyí, tí mo dá bí mo ṣe dá ọ.
Ó ń jẹ koríko bí akọ màlúù.
16 Wo bí ìbàdí rẹ̀ ṣe lágbáraÀti bí àwọn iṣan ikùn rẹ̀ ṣe lágbára tó!
17 Ó ń mú kí ìrù rẹ̀ le bí igi kédárì;A hun àwọn iṣan itan rẹ̀ pọ̀.
18 Àwọn egungun rẹ̀ dà bí ọ̀pá bàbà oníhò;Apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá irin tó lágbára.
19 Ó wà ní ipò kìíní* lára àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run;Aṣẹ̀dá rẹ̀ nìkan ló lè mú idà rẹ̀ sún mọ́ ọn.
20 Torí àwọn òkè ló ń pèsè oúnjẹ fún un,Níbi tí gbogbo àwọn ẹran igbó ti ń ṣeré.
21 Ó dùbúlẹ̀ sábẹ́ àwọn igi lótọ́sì,Lábẹ́ òjìji àwọn esùsú* níbi irà.
22 Àwọn igi lótọ́sì ṣíji bò ó,Àwọn igi pọ́pílà tó wà ní àfonífojì sì yí i ká.
23 Tí odò bá ń ru gùdù, kì í bẹ̀rù.
Ọkàn rẹ̀ balẹ̀, bí Jọ́dánì+ tiẹ̀ ń ya lu ẹnu rẹ̀.
24 Ṣé ẹnikẹ́ni lè mú un tó bá ń wò,Àbí kó fi ìwọ̀* kọ́ ọ ní imú?
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìdájọ́ mi kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni.”
^ Ní Héb., “De ojú wọn.”
^ Tàbí “yìn ọ́.”
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ erinmi.
^ Ní Héb., “Òun ni ìbẹ̀rẹ̀.”
^ Iyẹn, koríko etí omi.
^ Ní Héb., “ìdẹkùn.”