Jóòbù 19:1-29
19 Jóòbù fèsì pé:
2 “Ìgbà wo lẹ ò ní mú ọkàn mi* bínú mọ́,+Tí ẹ ò ní fi ọ̀rọ̀+ fọ́ mi sí wẹ́wẹ́?
3 Ìgbà mẹ́wàá yìí lẹ ti bá mi wí;*Ojú ò tì yín láti fọwọ́ tó le mú mi.+
4 Tí mo bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe,Èmi ni mo ni àṣìṣe náà.
5 Tí ẹ bá ṣì ń gbé ara yín ga jù mí lọ,Tí ẹ̀ ń sọ pé ó tọ́ láti fi mí ṣẹlẹ́yà,
6 Nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé Ọlọ́run ló ṣì mí lọ́nà,Ó sì ti fi àwọ̀n tó fi ń dọdẹ mú mi.
7 Wò ó! Mò ń ké ṣáá pé, ‘Ìwà ipá!’ àmọ́ kò sẹ́ni tó dáhùn;+Mò ń kígbe ṣáá pé mo nílò ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ìdájọ́ òdodo.+
8 Ó ti fi ògiri olókùúta dí ọ̀nà mi, mi ò sì lè kọjá;Ó ti fi òkùnkùn+ bo àwọn òpópónà mi.
9 Ó ti bọ́ ògo mi kúrò lára mi,Ó sì ti ṣí adé kúrò lórí mi.
10 Ó wó mi lulẹ̀ yí ká títí mo fi ṣègbé;Ó sì fa ìrètí mi tu bí igi.
11 Ó bínú sí mi gidigidi,Ó sì kà mí sí ọ̀tá rẹ̀.+
12 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kóra jọ, wọ́n sì gbéjà kò mí,Wọ́n pàgọ́ yí ibùdó mi ká.
13 Ó ti lé àwọn arákùnrin mi jìnnà réré sí mi,Àwọn tó sì mọ̀ mí ti kúrò lọ́dọ̀ mi.+
14 Àwọn ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́* ti lọ,Àwọn tí mo sì mọ̀ dáadáa ti gbàgbé mi.+
15 Mo ti di àjèjì sí àwọn àlejò inú ilé mi+ àti àwọn ẹrúbìnrin mi;Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni mo jẹ́ lójú wọn.
16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, àmọ́ kò dáhùn;Ẹnu mi ni mo fi bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú mi.
17 Kódà ìyàwó mi ti kórìíra èémí mi gidigidi,+Mo sì ti di òórùn burúkú sí àwọn arákùnrin mi.*
18 Àwọn ọmọdé pàápàá fojú àbùkù wò mí;Tí mo bá dìde, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.
19 Gbogbo ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ kórìíra mi,+Àwọn tí mo sì nífẹ̀ẹ́ ti kẹ̀yìn sí mi.+
20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ awọ ara mi àti ẹran ara mi,+Awọ eyín mi ni mo sì fi yè bọ́.
21 Ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ ṣàánú mi,Torí ọwọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti kàn mí.+
22 Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí mi bíi ti Ọlọ́run,+Tí ẹ̀ ń gbéjà kò mí láìdáwọ́ dúró?*+
23 Ká ní wọ́n kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀ ni,Ká ní wọ́n lè kọ ọ́ sínú ìwé!
24 Ká ní wọ́n lè fi kálàmù irin àti òjé gbẹ́ ẹSára àpáta, kó lè wà níbẹ̀ títí láé!
25 Torí ó dá mi lójú pé olùràpadà*+ mi wà láàyè;Ó máa wá tó bá yá, ó sì máa dìde lórí ayé.*
26 Tí awọ ara mi bá ti ṣí kúrò,*Tí mo ṣì ní ẹran lára, màá rí Ọlọ́run,
27 Ẹni tí màá rí fúnra mi,Ẹni tí màá fi ojú ara mi rí, kì í ṣe ojú ẹlòmíì.+
Àmọ́ nínú lọ́hùn-ún, ó ti sú mi pátápátá!*
28 Torí ẹ sọ pé, ‘Báwo la ṣe ń ṣe inúnibíni sí i?’+
Nígbà tó jẹ́ pé èmi ni orísun ìṣòro náà.
29 Kí ẹ̀yin fúnra yín bẹ̀rù idà,+Torí idà ń mú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wá;Ó yẹ kí ẹ mọ̀ pé adájọ́ wà.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “mú mi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “bú mi.”
^ Tàbí “Àwọn mọ̀lẹ́bí mi.”
^ Ní Héb., “àwọn ọmọ ilé ọlẹ̀ mi,” ìyẹn, ilé ọlẹ̀ tí mo tinú rẹ̀ jáde (ilé ọlẹ̀ ìyá mi).
^ Ní Héb., “Tí ẹran ara mi kò sì tẹ́ yín lọ́rùn?”
^ Tàbí “olùtúnrà.”
^ Ní Héb., “dìde lórí iyẹ̀pẹ̀.”
^ Ní Héb., “pa run.”
^ Tàbí “Àmọ́ àwọn kíndìnrín mi ti kọṣẹ́ nínú mi.”

