Jóòbù 14:1-22
14 “Èèyàn tí obìnrin bí,Ọlọ́jọ́ kúkúrú ni,+ wàhálà* rẹ̀ sì máa ń pọ̀ gan-an.+
2 Ó jáde wá bí ìtànná, ó sì rọ dà nù;*+Ó ń sá lọ bí òjìji, ó sì pòórá.+
3 Àní, o ti tẹjú mọ́ ọn,O sì ti bá a* ṣe ẹjọ́.+
4 Ta ló lè mú ẹni tó mọ́ jáde látinú ẹni tí kò mọ́?+
Kò sẹ́ni tó lè ṣe é!
5 Tí a bá ti pinnu àwọn ọjọ́ rẹ̀,Iye oṣù rẹ̀ wà lọ́wọ́ rẹ;O ti pààlà fún un, kó má bàa kọjá rẹ̀.+
6 Gbé ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè sinmi,Títí ó fi máa lo ọjọ́ rẹ̀ tán+ bí alágbàṣe.
7 Torí ìrètí wà fún igi pàápàá.
Tí wọ́n bá gé e lulẹ̀, ó máa hù pa dà,Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ á sì máa dàgbà.
8 Tí gbòǹgbò rẹ̀ bá gbó sínú ilẹ̀,Tí kùkùté rẹ̀ sì kú sínú iyẹ̀pẹ̀,
9 Ó máa hù tó bá gbúròó omi;Ó sì máa yọ ẹ̀ka bí ewéko tó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù.
10 Àmọ́ èèyàn kú, ó sì wà nílẹ̀ láìlágbára;Tí èèyàn bá gbẹ́mìí mì, ibo ló wà?+
11 Omi dàwátì nínú òkun,Odò ń fà, ó sì gbẹ táútáú.
12 Bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ń dùbúlẹ̀, kì í sì í dìde.+
Títí ọ̀run kò fi ní sí mọ́, wọn ò ní jí,Bẹ́ẹ̀ ni a ò ní jí wọn lójú oorun.+
13 Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú* ni,+Kí o fi mí pa mọ́ títí ìbínú rẹ fi máa kọjá,Kí o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!+
14 Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?+
Màá dúró jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ tó pọn dandan pé kí n lò,Títí ìtura mi fi máa dé. +
15 O máa pè, màá sì dá ọ lóhùn.+
Ó máa wù ọ́ gan-an láti rí* iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16 Àmọ́ ní báyìí, ò ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi ṣáá;Ẹ̀ṣẹ̀ mi nìkan lò ń ṣọ́.
17 O sé ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́ inú àpò,O sì fi àtè lẹ àṣìṣe mi pa.
18 Bí òkè ṣe máa ń ṣubú, tó sì ń fọ́ sí wẹ́wẹ́,Tí àpáta sì ń ṣí kúrò ní àyè rẹ̀,
19 Bí omi ṣe ń mú kí òkúta yìnrìn,Tí ọ̀gbàrá rẹ̀ sì ń wọ́ iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ lo ṣe sọ ìrètí ẹni kíkú dòfo.
20 Ò ń borí rẹ̀ títí ó fi ṣègbé;+O yí ìrísí rẹ̀ pa dà, o sì ní kó máa lọ.
21 A bọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kò mọ̀;Wọ́n di ẹni tí kò ní láárí, àmọ́ kò mọ̀.+
22 Ìgbà tó ṣì jẹ́ ẹlẹ́ran ara nìkan ló mọ̀ pé òun ń jẹ̀rora;Ìgbà tí ó* ṣì wà láàyè nìkan ló ń ṣọ̀fọ̀.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ṣìbáṣìbo.”
^ Tàbí kó jẹ́, “a sì ké e kúrò.”
^ Ní Héb., “mi.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “O máa yán hànhàn fún.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀.”