Jóòbù 41:1-34

  • Ọlọ́run jẹ́ ká mọ bí Léfíátánì ṣe ṣàrà ọ̀tọ̀ (1-34)

41  “Ṣé o lè fi ìwọ ẹja mú Léfíátánì,*+Àbí o lè fi okùn de ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?   Ṣé o lè ki okùn* bọ ihò imú rẹ̀,Àbí o lè fi ìwọ̀* kọ́ ọ lẹ́nu?   Ṣé ó máa bẹ̀ ọ́ gidigidi,Àbí ó máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀?   Ṣé ó máa bá ọ dá májẹ̀mú,Kí o lè sọ ọ́ di ẹrú rẹ títí láé?   Ṣé o máa bá a ṣeré bí ẹyẹ,Àbí o máa so okùn mọ́ ọn fún àwọn ọmọbìnrin rẹ kéékèèké?   Ṣé àwọn ọlọ́jà máa fi gba pààrọ̀?Ṣé wọ́n máa pín in láàárín àwọn oníṣòwò?   Ṣé o lè fi ọ̀kọ̀*+ gún gbogbo awọ ara rẹ̀,Àbí o lè fi àwọn ọ̀kọ̀ ìpẹja gún orí rẹ̀?   Gbé ọwọ́ rẹ lé e;O máa rántí ìjà náà, o ò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé!   Asán ni ìrètí èyíkéyìí tí o bá ní pé o máa kápá rẹ̀. Tí o bá rí i lásán, ṣe ni jìnnìjìnnì á bò ọ́.* 10  Kò sí ẹni tó jẹ́ ru ú sókè. Ta ló wá lè kò mí lójú?+ 11  Ta ló kọ́kọ́ fún mi ní ohunkóhun tí màá fi san án pa dà fún un?+ Tèmi ni ohunkóhun tó wà lábẹ́ ọ̀run.+ 12  Mi ò ní ṣàìsọ̀rọ̀ nípa apá àti ẹsẹ̀ rẹ̀,Nípa agbára ńlá rẹ̀ àti ara rẹ̀ tí a dá lọ́nà ìyanu. 13  Ta ló ti bọ́ ohun tó bò ó lára? Ta ló máa wọ ẹnu rẹ̀ tó là sílẹ̀? 14  Ta ló lè fipá ṣí àwọn ilẹ̀kùn ẹnu* rẹ̀? Gbogbo eyín rẹ̀ ń dẹ́rù bani. 15  Àwọn ìpẹ́ tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ ní ẹ̀yìn rẹ̀,*Wọ́n lẹ̀ mọ́ra pinpin. 16  Ọ̀kọ̀ọ̀kan lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ ìkejì,Débi pé afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárín wọn. 17  Wọ́n lẹ̀ mọ́ra wọn;Wọ́n so mọ́ra wọn, wọn ò sì ṣeé yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. 18  Ìró tó ń ti imú rẹ̀ jáde ń mú kí iná kọ yẹ̀rì,Ojú rẹ̀ sì dà bí ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ tó ń tàn. 19  Mànàmáná ń kọ yẹ̀rì láti ẹnu rẹ̀;Iná ń ta pàrà jáde. 20  Èéfín ń tú jáde látinú ihò imú rẹ̀,Bí iná ìléru tí wọ́n fi koríko etídò dáná sí. 21  Èémí rẹ̀ ń mú kí ẹyin iná jó,Ọwọ́ iná sì ń ti ẹnu rẹ̀ jáde. 22  Ọrùn rẹ̀ lágbára gan-an,Jìnnìjìnnì sì ń sá lọ níwájú rẹ̀. 23  Àwọn ìṣẹ́po ẹran ara rẹ̀ lẹ̀ mọ́ra pẹ́kípẹ́kí;Wọ́n le gbagidi, bí ohun tí a rọ, tó dúró digbí. 24  Ọkàn rẹ̀ le bí òkúta,Àní, ó le bí ìyá ọlọ. 25  Tó bá gbéra, ẹ̀rù máa ń ba àwọn alágbára pàápàá;Tó bá jà pìtìpìtì, ṣìbáṣìbo á bá wọn. 26  Kò sí idà tó bà á tó lè ràn án;Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kọ̀, igaga tàbí orí ọfà kò lè ràn án.+ 27  Ó ka irin sí pòròpóròÀti bàbà sí igi tó ti jẹrà. 28  Ọfà kò lè lé e lọ;Òkúta kànnàkànnà máa ń di àgékù pòròpórò tó bá bà á. 29  Ó ka kùmọ̀ sí àgékù pòròpórò,Ó sì ń fi ẹ̀ṣín rẹ́rìn-ín bó ṣe ń dún pẹkẹpẹkẹ. 30  Abẹ́ rẹ̀ dà bí àwọn àfọ́kù ìkòkò tó mú;Ó tẹ́ ara rẹ̀ sínú ẹrọ̀fọ̀ bí ohun tí wọ́n fi ń pakà.+ 31  Ó ń mú kí ibú hó bí ìkòkò;Ó ń ru òkun gùdù bí ìkòkò òróró ìpara. 32  Ipa ọ̀nà rẹ̀ ń dán lẹ́yìn rẹ̀. Ṣe ni èèyàn á rò pé ibú omi ní irun funfun. 33  Kò sí ohun tó dà bí rẹ̀ ní ayé,Ẹ̀dá tí a dá pé kó má bẹ̀rù ohunkóhun. 34  Ó ń fìbínú wo gbogbo ohun tó ń gbéra ga. Òun ni ọba lórí gbogbo ẹran ńlá inú igbó.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀nì.
Ní Héb., “ewéko etídò.”
Ní Héb., “ẹ̀gún.”
Ìyẹn, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń pa ẹja ńlá.
Tàbí “ṣe ni wàá ṣubú lulẹ̀.”
Ní Héb., “ojú.”
Tàbí kó jẹ́, “Ọ̀wọ́ àwọn ìpẹ́ rẹ̀ ló ń mú kó gbéra ga.”