Jóòbù 13:1-28
13 “Àní ojú mi ti rí gbogbo èyí,Etí mi ti gbọ́, ó sì ti yé mi.
2 Ohun tí ẹ mọ̀ ni èmi náà mọ̀;Mi ò kéré sí yín.
3 Ní tèmi, màá kúkú bá Olódùmarè fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀;Ọlọ́run ni mo fẹ́ ro ẹjọ́ mi fún.+
4 Ẹ̀ ń fi irọ́ bà mí lórúkọ jẹ́;Oníṣègùn tí kò wúlò ni gbogbo yín.+
5 Ká ní ẹ lè dákẹ́ láìsọ nǹkan kan ni,Ìyẹn ì bá fi hàn pé ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n!+
6 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ tẹ́tí gbọ́ àlàyé mi,Kí ẹ sì fiyè sí àrọwà ètè mi.
7 Ṣé ẹ máa sọ̀rọ̀ tí kò tọ́ láti gbèjà Ọlọ́run,Ṣé ẹ fẹ́ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn láti gbè é lẹ́yìn?
8 Ṣé ẹ máa gbè sẹ́yìn rẹ̀,*Ṣé ẹ fẹ́ máa gbèjà Ọlọ́run tòótọ́ ni?
9 Tó bá yẹ̀ yín wò, ṣé ibi tó dáa ló máa já sí?+
Àbí ẹ máa tàn án jẹ bí ẹ ṣe máa tan ẹni kíkú?
10 Tí ẹ bá gbìyànjú láti ṣe ojúsàájú níkọ̀kọ̀,+Ó dájú pé ó máa bá yín wí.
11 Ṣé iyì rẹ̀ pàápàá kò ní kó jìnnìjìnnì bá yín,Ṣé ẹ̀rù rẹ̀ kò sì ní bà yín?
12 Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n* yín jẹ́ òwe tó dà bí eérú;Àwọn ohun tí ẹ fi ń gbèjà ara yín* ò lágbára, wọ́n dà bí ohun tí wọ́n fi amọ̀ ṣe.
13 Ẹ dákẹ́ níwájú mi, kí n lè sọ̀rọ̀.
Kí ohunkóhun tó bá wá fẹ́ ṣẹlẹ̀ sí mi ṣẹlẹ̀!
14 Kí ló dé tí mo fi ara mi sínú ewu,*Tí mo sì fi ẹ̀mí* mi sọ́wọ́ mi?
15 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè pa mí, màá ṣì dúró;+Màá ro ẹjọ́ mi* níwájú rẹ̀.
16 Ó máa wá di ìgbàlà mi,+Torí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run* kò lè wá síwájú rẹ̀.+
17 Ẹ fetí sílẹ̀ dáadáa sí ọ̀rọ̀ mi;Ẹ fiyè sí ohun tí mo fẹ́ sọ.
18 Ẹ wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀ báyìí;Mo mọ̀ pé èmi ni mo jàre.
19 Ta ló máa bá mi fà á?
Màá kú tí mo bá dákẹ́!*
20 Ohun méjì péré ni kí o ṣe fún mi, ìwọ Ọlọ́run,*Kí n má bàa fi ara mi pa mọ́ níwájú rẹ:
21 Gbé ọwọ́ rẹ tó wúwo jìnnà réré sí mi,Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kó jìnnìjìnnì bá mi.+
22 Nínú kí o pè, kí n sì dá ọ lóhùn,Tàbí kí o jẹ́ kí n sọ̀rọ̀, kí o sì dá mi lóhùn.
23 Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀, kí sì ni àṣìṣe mi?
Jẹ́ kí n mọ ìṣìnà mi àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
24 Kí ló dé tí o fi ojú rẹ pa mọ́,+Tí o sì kà mí sí ọ̀tá rẹ?+
25 Ṣé o máa fẹ́ dẹ́rù ba ewé tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri ni,Àbí o fẹ́ máa sáré lé àgékù pòròpórò tó ti gbẹ?
26 Torí ò ń fẹ̀sùn tó le kàn mí, o sì ń kọ ọ́ sílẹ̀ ṣáá,O sì mú kí n jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá nígbà tí mo ṣì kéré.
27 O ti ẹsẹ̀ mi mọ́ inú àbà,Ò ń ṣọ́ gbogbo ọ̀nà mi lójú méjèèjì,O sì ń wá ipasẹ̀ mi jáde lọ́kọ̀ọ̀kan.
28 Torí náà, èèyàn* ń jẹrà bí ohun tó ti rà,Bí aṣọ tí òólá* ti jẹ.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ṣe ojúsàájú sí i.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀ ìrántí.”
^ Ní Héb., “kókó rubutu orí apata yín.”
^ Ní Héb., “Kí ló dé tí mo fi eyín mi gbé ẹran ara mi?”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “gbèjà ara mi.”
^ Tàbí “apẹ̀yìndà.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Tí ẹnì kan bá ṣe bẹ́ẹ̀, màá dákẹ́, màá sì kú.”
^ Ní Héb., “Ohun méjì péré ni kí o má ṣe fún mi.”
^ Ní Héb., “ó,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Jóòbù ló ń tọ́ka sí.
^ Tàbí “kòkòrò.”

