Jóòbù 10:1-22
10 “Mo* kórìíra ayé mi gidigidi.+
Mi ò ní pa bó ṣe ń ṣe mi mọ́ra.
Màá sọ̀rọ̀ látinú ẹ̀dùn ọkàn* tó bá mi!
2 Màá sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Má ṣe dá mi lẹ́bi.
Jẹ́ kí n mọ ìdí tí o fi ń bá mi jà.
3 Ṣé ó máa ṣe ọ́ láǹfààní tí o bá fìyà jẹni,Tí o bá kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+Tí o sì fara mọ́ ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú?
4 Ṣé ojú rẹ dà bíi ti èèyàn ni,Àbí o máa ń wo nǹkan bíi ti ẹni kíkú?
5 Ṣé bí ọjọ́ àwọn ẹni kíkú ni àwọn ọjọ́ rẹ rí,Àbí àwọn ọdún rẹ dà bíi ti èèyàn,+
6 Tí o fi ń wá àṣìṣe mi,
Tí o sì ń wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?+
7 O mọ̀ pé mi ò jẹ̀bi,+Kò sì sí ẹni tó lè gbà mí lọ́wọ́ rẹ.+
8 Ọwọ́ rẹ lo fi mọ mí tí o sì fi dá mi,+Àmọ́ ní báyìí, o fẹ́ pa mí run pátápátá.
9 Jọ̀ọ́, rántí pé amọ̀ lo fi mọ mí,+Àmọ́ ní báyìí, o mú kí n pa dà sínú erùpẹ̀.+
10 Ṣebí o dà mí jáde bíi wàràTí o sì mú kí n dì bíi wàràkàṣì?
11 O fi awọ àti ẹran bò mí,O sì fi egungun àti iṣan hun mí pọ̀.+
12 O ti fún mi ní ìyè, o sì ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi;O ti fi ìkẹ́ rẹ dáàbò bo ẹ̀mí* mi.+
13 Àmọ́ o gbèrò ní bòókẹ́lẹ́ láti ṣe àwọn nǹkan yìí.*
Mo mọ̀ pé ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn nǹkan yìí ti wá.
14 Tí mo bá ṣẹ̀, o máa ṣọ́ mi,+O ò sì ní dá mi láre.
15 Tí mo bá jẹ̀bi, mo gbé!
Tí mi ò bá tiẹ̀ mọwọ́ mẹsẹ̀, mi ò lè gbé orí mi sókè,+Torí ìtìjú àti ìyà+ ti bò mí mọ́lẹ̀.
16 Tí mo bá gbé orí mi sókè, o máa dọdẹ mi bíi ti kìnnìún,+O sì tún máa fi agbára rẹ bá mi jà.
17 O mú àwọn ẹlẹ́rìí míì wá láti ta kò mí,O sì túbọ̀ bínú sí mi,
Bí mo ṣe ń tinú ìnira kan bọ́ sínú ìnira míì.
18 Torí náà, kí ló dé tí o mú mi jáde látinú ikùn?+
Ó yẹ kí n ti kú kí ojú kankan tó rí mi.
19 Ṣe ni ì bá dà bíi pé mi ò gbé ayé rí;Mi ò bá kàn ti inú ikùn lọ sí sàréè.’
20 Ṣebí àwọn ọjọ́ mi ò pọ̀?+ Kó fi mí sílẹ̀;Kó gbé ojú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, kí ara lè tù mí díẹ̀*+
21 Kí n tó lọ, tí mi ò sì ní pa dà wá,+Sí ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri,*+
22 Sí ilẹ̀ tí ìṣúdùdù rẹ̀ pọ̀ gidigidi,Ilẹ̀ tó ṣókùnkùn biribiri, tó sì rí rúdurùdu,Níbi tí ìmọ́lẹ̀ pàápàá ti dà bí òkùnkùn.”

