Òwe 14:1-35

  • Ọkàn èèyàn mọ ìbànújẹ́ rẹ̀ (10)

  • Ọ̀nà tó dà bíi pé ó tọ́ lè yọrí sí ikú (12)

  • Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́ (15)

  • Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá ọlọ́rọ̀ ṣọ̀rẹ́ (20)

  • Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun (30)

14  Ọlọ́gbọ́n obìnrin ń kọ́ ilé rẹ̀,+Àmọ́ òmùgọ̀ obìnrin á fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya tirẹ̀ lulẹ̀.   Ẹni tó ń rìn nínú ìdúróṣinṣin ń bẹ̀rù Jèhófà,Àmọ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́* ń tàbùkù sí I.   Pàṣán ìgbéraga wà ní ẹnu òmùgọ̀,Àmọ́ ètè àwọn ọlọ́gbọ́n yóò dáàbò bò wọ́n.   Tí kò bá sí ẹran ọ̀sìn,* ibùjẹ ẹran á mọ́ tónítóní,Àmọ́ agbára akọ màlúù máa ń mú kí ìkórè pọ̀.   Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ olóòótọ́ kì í parọ́,Àmọ́ ẹlẹ́rìí èké kò lè ṣe kó má parọ́.+   Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n, kò sì rí i,Àmọ́ ìmọ̀ máa ń wá sọ́dọ̀ àwọn olóye pẹ̀lú ìrọ̀rùn.+   Jìnnà sí òmùgọ̀ èèyàn,Torí o ò ní rí ìmọ̀ ní ẹnu rẹ̀.+   Ọgbọ́n ni aláròjinlẹ̀ fi ń lóye ibi tí ọ̀nà rẹ̀ máa já sí,Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń ṣì wọ́n lọ́nà.*+   Òmùgọ̀ ló ń da ẹ̀bi rẹ̀* sáwàdà,+Àmọ́ àwọn adúróṣinṣin máa ń fẹ́ láti pa dà wà níṣọ̀kan.* 10  Ọkàn èèyàn mọ ìbànújẹ́ rẹ̀,*Àjèjì kò sì lè pín nínú ayọ̀ rẹ̀. 11  Ilé àwọn ẹni burúkú máa pa run,+Àmọ́ àgọ́ àwọn adúróṣinṣin máa gbilẹ̀. 12  Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,+Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+ 13  Èèyàn lè máa rẹ́rìn-ín, síbẹ̀ kí ọkàn rẹ̀ máa jẹ̀rora,Ìdùnnú sì lè di ìbànújẹ́. 14  Aláìṣòótọ́ máa gba èrè àwọn ọ̀nà rẹ̀,+Àmọ́ èèyàn rere máa gba èrè ìwà rẹ̀.+ 15  Aláìmọ̀kan* máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́,Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.+ 16  Ọlọ́gbọ́n máa ń ṣọ́ra, ó sì ń yẹra fún ìwà burúkú,Àmọ́ òmùgọ̀ kì í kíyè sára,* ó sì máa ń dá ara rẹ̀ lójú jù. 17  Ẹni tó bá tètè ń bínú máa ń hùwà òmùgọ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò* ni aráyé ń kórìíra. 18  Aláìmọ̀kan* yóò jogún ìwà òmùgọ̀,Àmọ́ a ó fi ìmọ̀ dé àwọn aláròjinlẹ̀ ládé.+ 19  Àwọn èèyàn búburú yóò tẹrí ba níwájú àwọn ẹni rere,Àwọn èèyàn burúkú yóò sì tẹrí ba ní ẹnubodè àwọn olódodo. 20  Àwọn tó sún mọ́ tálákà pàápàá máa ń kórìíra rẹ̀,+Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá olówó ṣọ̀rẹ́.+ 21  Ẹni tó bá ń fojú àbùkù wo ọmọnìkejì rẹ̀ ń dẹ́ṣẹ̀,Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣàánú aláìní jẹ́ aláyọ̀.+ 22  Àwọn tó ń gbèrò ibi máa ṣìnà. Àmọ́ àwọn tó ti pinnu láti máa ṣe rere máa rí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́.+ 23  Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè,Àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ń yọrí sí àìní.+ 24  Adé àwọn ọlọ́gbọ́n ni ọrọ̀ wọn;Àmọ́ ìwà àwọn òmùgọ̀ jẹ́ kìkì ẹ̀gọ̀.+ 25  Ẹlẹ́rìí tòótọ́ ń gba ẹ̀mí* là,Àmọ́ ẹlẹ́tàn kò lè ṣe kó má parọ́. 26  Ìbẹ̀rù Jèhófà máa ń fọkàn ẹni balẹ̀ pẹ̀sẹ̀,+Yóò sì jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀.+ 27  Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ orísun ìyè,Kì í jẹ́ kéèyàn kó sínú ìdẹkùn ikú. 28  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni ògo ọba,+Àmọ́ alákòóso tí kò ní àwọn tó ń jọba lé lórí ti ṣubú. 29  Ẹni tí kì í tètè bínú ní ìjìnlẹ̀ òye,+Àmọ́ ẹni tí kò ní sùúrù ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+ 30  Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun,*Àmọ́ owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.+ 31  Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì ń gan Ẹni tó dà a,+Àmọ́ ẹni tó ń ṣàánú tálákà ń yìn Ín lógo.+ 32  Ìwà ibi ẹni burúkú ló máa gbé e ṣubú,Àmọ́ olódodo máa rí ààbò nítorí ìwà títọ́ rẹ̀.+ 33  Inú ọkàn olóye ni ọgbọ́n fìdí kalẹ̀ sí,+Àmọ́ àárín àwọn òmùgọ̀ ló ti máa ń fi ara rẹ̀ hàn. 34  Òdodo máa ń gbé orílẹ̀-èdè lékè,+Àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ máa ń kó ìtìjú bá orílẹ̀-èdè. 35  Inú ọba máa ń dùn sí ìránṣẹ́ tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye,+Àmọ́ inú rẹ̀ máa ń ru sí èyí tó ń hùwà ìtìjú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́.”
Tàbí “màlúù.”
Tàbí kó jẹ́, “ni wọ́n fi ń ṣi àwọn míì lọ́nà.”
Tàbí “ṣíṣe àtúnṣe.”
Tàbí “máa ń wá ire.”
Tàbí “ìkorò ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “Aláìní ìrírí.”
Tàbí “máa ń bínú fùfù.”
Tàbí “aláròjinlẹ̀.”
Tàbí “aláìní ìrírí.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ní ìlera.”