Òwe 5:1-23

  • Ìkìlọ̀ nítorí obìnrin oníṣekúṣe (1-14)

  • Máa yọ̀ pẹ̀lú aya rẹ (15-23)

5  Ọmọ mi, fiyè sí ọgbọ́n mi. Fetí sílẹ̀ dáadáa* sí òye mi,+  2  Kí o bàa lè dáàbò bo làákàyè rẹKí o sì fi ètè rẹ dáàbò bo ìmọ̀.+  3  Nítorí ètè obìnrin oníwàkiwà* ń kán tótó bí afárá oyin,+Ọ̀rọ̀* rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ.+  4  Àmọ́, nígbẹ̀yìn ó korò bí iwọ*+Ó sì mú bí idà olójú méjì.+  5  Àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ sí ikú. Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí Isà Òkú.*  6  Kì í ronú nípa ọ̀nà ìyè. Ó ti ṣìnà, kò mọ ibi tí ọ̀nà rẹ̀ máa já sí.  7  Ní báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí miẸ má sì kúrò nínú ohun tí mò ń sọ.  8  Jìnnà réré sí i;Má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀,+  9  Kí o má bàa fi iyì rẹ fún àwọn ẹlòmíì+Tàbí kí o fi ọ̀pọ̀ ọdún kórè ohun tó burú;+ 10  Kí àwọn àjèjì má bàa fa ọrọ̀* rẹ gbẹ,+Kí àwọn ohun tí o ṣiṣẹ́ kára fún sì lọ sí ilé àjèjì. 11  Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹNígbà tí okun rẹ bá tán, tí ẹran ara rẹ sì gbẹ+ 12  Tí o sì sọ pé: “Ẹ wo bí mo ṣe kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ẹ wo bí ọkàn mi ti ṣàìka ìbáwí sí! 13  Mi ò fetí sí ohùn àwọn tó ń kọ́ miMi ò sì tẹ́tí sí àwọn olùkọ́ mi. 14  Mo ti dé bèbè ìparunNí àárín ìjọ lápapọ̀.”*+ 15  Mu omi látinú àmù rẹÀti omi tó ń sun* látinú kànga rẹ.+ 16  Ṣé ó yẹ kí ìsun omi rẹ tú síta,Kí ìṣàn omi rẹ sì tú sí àwọn ojúde ìlú?+ 17  Jẹ́ kí wọ́n wà fún ìwọ nìkan,Kì í ṣe fún ìwọ àti àwọn àjèjì.+ 18  Kí orísun omi* rẹ ní ìbùkún,Kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ,+ 19  Abo àgbọ̀nrín tó fani mọ́ra, ewúrẹ́ rírẹwà orí òkè.+ Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ máa dá ọ lọ́rùn* nígbà gbogbo. Kí ìfẹ́ rẹ̀ máa gbà ọ́ lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+ 20  Torí náà, ọmọ mi, kí nìdí tí wàá fi jẹ́ kí obìnrin oníwàkiwà* gbà ọ́ lọ́kànTàbí tí wàá fi gbá àyà obìnrin oníṣekúṣe* mọ́ra?+ 21  Nítorí àwọn ọ̀nà èèyàn wà níwájú Jèhófà;Ó ń ṣàyẹ̀wò gbogbo ipa ọ̀nà rẹ̀.+ 22  Àwọn àṣìṣe ẹni burúkú ló ń dẹkùn mú un,Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ á sì wé mọ́ ọn bí okùn.+ 23  Ó máa kú nítorí kò gba ìbáwíÁ sì ṣìnà nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ tó pọ̀ lápọ̀jù.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ní Héb., “Dẹ etí rẹ.”
^ Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.
^ Ní Héb., “Ẹnu.”
^ Ìyẹn, igi kan tó korò gan-an.
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “agbára.”
^ Ní Héb., “Ní àárín àpéjọ àti ìjọ.”
^ Tàbí “omi tó mọ́ lóló.”
^ Tàbí “ìsun omi.”
^ Tàbí “pa ọ́ bí ọtí.”
^ Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.
^ Ní Héb., “obìnrin ilẹ̀ òkèèrè.” Wo Owe 2:16.