Òwe 11:1-31
11 Òṣùwọ̀n èké* jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,Àmọ́ ìwọ̀n* tí ó pé máa ń mú inú rẹ̀ dùn.+
2 Tí ìkọjá àyè bá dé, àbùkù á tẹ̀ lé e,+Àmọ́ ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.+
3 Ìwà títọ́ àwọn adúróṣinṣin ló ń tọ́ wọn sọ́nà,+Àmọ́ ẹ̀tàn àwọn oníbékebèke ni yóò pa wọ́n run.+
4 Ọrọ̀* kò ní ṣeni láǹfààní ní ọjọ́ ìbínú ńlá,+Àmọ́ òdodo ló ń gbani lọ́wọ́ ikú.+
5 Òdodo aláìlẹ́bi ń mú kí ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́,Àmọ́ ẹni burúkú á ṣubú nítorí ìwà burúkú rẹ̀.+
6 Òdodo àwọn adúróṣinṣin ni yóò gbà wọ́n,+Àmọ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn oníbékebèke ni yóò dẹkùn mú wọn.+
7 Nígbà tí ẹni burúkú bá kú, ìrètí rẹ̀ á ṣègbé;Ohun tó sì ń retí pé òun á fi agbára òun ṣe yóò ṣègbé pẹ̀lú.+
8 A gba olódodo lọ́wọ́ wàhálà,Ẹni burúkú sì bọ́ síbẹ̀ dípò rẹ̀.+
9 Ẹnu ni apẹ̀yìndà* fi ń fa ìparun bá ọmọnìkejì rẹ̀,Àmọ́ ìmọ̀ ló ń gba àwọn olódodo sílẹ̀.+
10 Ìwà rere àwọn olódodo ń mú kí ìlú yọ̀,Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá ṣègbé, igbe ìdùnnú á ta.+
11 Nítorí ìbùkún àwọn adúróṣinṣin, ìlú á ní ìgbéga,+Àmọ́ ẹnu àwọn ẹni burúkú á wó o lulẹ̀.+
12 Ẹni tí kò ní làákàyè* ń kórìíra* ọmọnìkejì rẹ̀,Àmọ́ ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa ń dákẹ́.+
13 Abanijẹ́ ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kiri,+Àmọ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán* máa ń pa àṣírí mọ́.*
14 Nígbà tí kò bá sí ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n, àwọn èèyàn á ṣubú,Àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn,* àṣeyọrí* á wà.+
15 Ẹni tó bá ṣe onídùúró* fún àjèjì yóò rí láburú,+Àmọ́ ẹni tó bá yẹra fún* bíbọ ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ́ yóò rí ààbò.
16 Obìnrin onínúure* ń gba ògo,+Àmọ́ àwọn ìkà èèyàn ń gbẹ́sẹ̀ lé ọrọ̀.
17 Ẹni tó ń ṣoore* ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní,*+Àmọ́ ìkà èèyàn ń fa wàhálà* bá ara rẹ̀.+
18 Ẹni burúkú ń jẹ èrè asán,+Àmọ́ ẹni tó ń gbin òdodo ń jẹ èrè gidi.+
19 Ẹni tó dúró gbọn-in lórí òdodo máa rí ìyè,+Àmọ́ ẹni tó ń lépa ohun búburú á rí ikú he.
20 Àwọn tí ọkàn wọn burú jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+Àmọ́ àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́ ń mú inú rẹ̀ dùn.+
21 Jẹ́ kó dá ọ lójú pé:* Ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,+Àmọ́ àwọn ọmọ olódodo yóò yè bọ́.
22 Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀Ni obìnrin tó rẹwà àmọ́ tí kì í lo làákàyè.
23 Ìfẹ́ ọkàn àwọn olódodo ń yọrí sí ire,+Àmọ́ ohun tí àwọn ẹni burúkú ń retí máa ń yọrí sí ìbínú ńlá.
24 Ẹnì kan wà tó ń fúnni lọ́pọ̀lọpọ̀,* ó sì ń ní sí i;+Ẹnì kan sì wà tó ń fawọ́ ohun tó yẹ kó fúnni sẹ́yìn, àmọ́ ó di aláìní.+
25 Ẹni* tó bá lawọ́ máa láásìkí,*+Ẹni tó bá sì ń mára tu àwọn míì,* ara máa tu òun náà.+
26 Àwọn èèyàn á gégùn-ún fún ẹni tó bá kó oúnjẹ pa mọ́,Àmọ́ wọ́n á súre fún ẹni tó bá ń tà á.
27 Ẹni tó ń wá bó ṣe máa ṣe rere lójú méjèèjì ń wá ojú rere,+Àmọ́ ẹni tó bá ń wá ibi, ó dájú pé ibi ló máa wá sórí rẹ̀.+
28 Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀ máa ṣubú,+Àmọ́ olódodo máa rú yọ bí ewé tútù.+
29 Ẹni tó bá ń fa wàhálà* bá agbo ilé rẹ̀ á jogún òfo,*+Òmùgọ̀ èèyàn ló sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ ọlọ́gbọ́n.
30 Èso olódodo jẹ́ igi ìyè,+Ẹni tó bá sì ń jèrè ọkàn* jẹ́ ọlọ́gbọ́n.+
31 Tó bá jẹ́ pé ẹ̀san wà fún olódodo lóòótọ́,Mélòómélòó ni ti ẹni burúkú àti ẹlẹ́ṣẹ̀!+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “òkúta ìwọ̀n.”
^ Tàbí “ìrẹ́nijẹ.”
^ Tàbí “Àwọn ohun iyebíye.”
^ Tàbí “ẹni tí kò gba Ọlọ́run gbọ́.”
^ Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”
^ Tàbí “pẹ̀gàn.”
^ Ní Héb., “olóòótọ́ ní ẹ̀mí.”
^ Ní Héb., “bo ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀.”
^ Tàbí “olùdámọ̀ràn.”
^ Tàbí “ìgbàlà.”
^ Tàbí “onígbọ̀wọ́.”
^ Ní Héb., “kórìíra.”
^ Tàbí “tó rẹwà.”
^ Tàbí “Ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”
^ Tàbí “ń ṣe ọkàn rẹ̀ lóore.”
^ Tàbí “ìtìjú.”
^ Ní Héb., “Ọwọ́ sí ọwọ́.”
^ Ní Héb., “tó ń fọ́n ká.”
^ Tàbí “Ọkàn.”
^ Ní Héb., “ni a ó mú sanra.”
^ Ní Héb., “bomi rin àwọn míì fàlàlà.”
^ Tàbí “kó ìtìjú.”
^ Ní Héb., “ẹ̀fúùfù.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.