Òwe 6:1-35

  • Ṣọ́ra fún ṣíṣe onídùúró ẹni tó fẹ́ yá owó (1-5)

  • “Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ” (6-11)

  • Ìkà àti aláìwúlò ẹ̀dá (12-15)

  • Ohun méje tí Jèhófà kórìíra (16-19)

  • Ṣọ́ra fún obìnrin burúkú (20-35)

6  Ọmọ mi, tí o bá ti ṣe onídùúró* fún ọmọnìkejì rẹ,+Tí o bá ti bọ àjèjì lọ́wọ́,*+   Tí ìlérí rẹ bá ti dẹkùn mú ọ,Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ bá ti mú ọ,+   Ohun tí wàá ṣe nìyí, ọmọ mi, kí o lè gba ara rẹ sílẹ̀,Nítorí o ti kó sọ́wọ́ ọmọnìkejì rẹ: Lọ rẹ ara rẹ sílẹ̀, kí o sì tètè bẹ ọmọnìkejì rẹ.+   Má ṣe jẹ́ kí oorun kun ojú rẹ,Má sì jẹ́ kí ìpéǹpéjú rẹ tòògbé.   Gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tó bọ́ lọ́wọ́ ọdẹ,Àti bí ẹyẹ tó bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.   Tọ èèrà lọ, ìwọ ọ̀lẹ;+Kíyè sí àwọn ọ̀nà rẹ̀, kí o sì gbọ́n.   Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní olùdarí, aláṣẹ tàbí alákòóso,   Ó ń ṣètò oúnjẹ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn,+Ó sì ń kó oúnjẹ rẹ̀ jọ nígbà ìkórè.   Ìgbà wo ni ìwọ ọ̀lẹ máa dùbúlẹ̀ dà? Ìgbà wo lo máa dìde lójú oorun rẹ? 10  Oorun díẹ̀, ìtòògbé díẹ̀,Kíkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,+ 11  Ipò òṣì rẹ yóò sì dé bí olè,Àti àìní rẹ bí ọkùnrin tó dìhámọ́ra.+ 12  Ìkà àti aláìwúlò ẹ̀dá ń rìn kiri tòun ti èké ọ̀rọ̀;+ 13  Bó ṣe ń ṣẹ́jú,+ bẹ́ẹ̀ ló ń fi ẹsẹ̀ sọ̀rọ̀, tó sì ń nàka. 14  Pẹ̀lú ọkàn burúkú,Ó ń gbèrò ibi ní gbogbo ìgbà,+ ó sì ń dá awuyewuye sílẹ̀.+ 15  Torí náà, àjálù rẹ̀ yóò dé lójijì;Ojú ẹsẹ̀ ni yóò wó lulẹ̀, kò sì ní ṣeé wò sàn.+ 16  Ohun mẹ́fà wà tí Jèhófà kórìíra;Bẹ́ẹ̀ ni, ohun méje tó jẹ́ ohun ìríra fún un:* 17  Ojú ìgbéraga,+ ahọ́n èké+ àti ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,+ 18  Ọkàn tó ń gbèrò ìkà+ àti ẹsẹ̀ tó ń sáré tete láti ṣe ibi, 19  Ẹlẹ́rìí èké tí kò lè ṣe kó má parọ́+Àti ẹni tó ń dá awuyewuye sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.+ 20  Ọmọ mi, pa àṣẹ bàbá rẹ mọ́,Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+ 21  So wọ́n mọ́ ọkàn rẹ nígbà gbogbo;Dè wọ́n mọ́ ọrùn rẹ. 22  Nígbà tí o bá ń rìn, á máa darí rẹ;Nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, á máa ṣọ́ ẹ;Nígbà tí o bá sì jí, á máa bá ẹ sọ̀rọ̀.* 23  Nítorí àṣẹ jẹ́ fìtílà,+Òfin jẹ́ ìmọ́lẹ̀,+Àwọn ẹ̀kọ́ inú ìbáwí sì ni ọ̀nà ìyè.+ 24  Wọ́n máa dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ obìnrin burúkú,+Lọ́wọ́ ahọ́n obìnrin oníṣekúṣe* tó ń sọ ọ̀rọ̀ tó fani mọ́ra.+ 25  Má ṣe jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́+Tàbí kí o jẹ́ kó fi ojú rẹ̀ tó ń fani mọ́ra mú ọ, 26  Ní tìtorí aṣẹ́wó, èèyàn á di ẹni tí kò ní ju búrẹ́dì kan ṣoṣo lọ,+Ní ti obìnrin alágbèrè, ẹ̀mí* tó ṣeyebíye ló fi ń ṣe ìjẹ. 27  Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí àyà rẹ̀, kí ẹ̀wù rẹ̀ má sì jó?+ 28  Tàbí ṣé ọkùnrin kan lè rìn lórí ẹyin iná, kó má sì jó o lẹ́sẹ̀? 29  Bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún ẹni tó bá ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya ọmọnìkejì rẹ̀;Kò sí ẹni tó fọwọ́ kàn án tó máa lọ láìjìyà.+ 30  Àwọn èèyàn kì í pẹ̀gàn olèTó bá jẹ́ pé ebi tó ń pa á ló mú kó jalè kó lè tẹ́ ọkàn* rẹ̀ lọ́rùn. 31  Síbẹ̀, tí wọ́n bá rí i, á san án pa dà ní ìlọ́po méje;Gbogbo ohun tó níye lórí nínú ilé rẹ̀ ló máa kó sílẹ̀.+ 32  Ẹni tó bá bá obìnrin ṣe àgbèrè kò ní làákàyè;*Ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ń fa ìparun bá ara* rẹ̀.+ 33  Ọgbẹ́ àti àbùkù ló máa gbà,+Ìtìjú rẹ̀ kò sì ní pa rẹ́.+ 34  Nítorí owú máa ń mú kí ọkọ bínú;Kò ní ṣojú àánú nígbà tó bá ń gbẹ̀san.+ 35  Kò ní gba àsandípò;*Láìka bí ẹ̀bùn náà ṣe pọ̀ tó, kò ní tù ú lójú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ìyẹn, nínú ẹ̀jẹ́.
Tàbí “onígbọ̀wọ́.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “òfin.”
Tàbí “kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́.”
Ní Héb., “ilẹ̀ òkèèrè.” Wo Owe 2:16.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ara.”
Ní Héb., “jẹ́ ẹni tí ọkàn kù fún.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ìràpadà.”