Òwe 10:1-32
10 Òwe Sólómọ́nì.+
Ọlọ́gbọ́n ọmọ ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn,+Àmọ́ òmùgọ̀ ọmọ ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìyá rẹ̀.
2 Àwọn ìṣúra téèyàn fi ìwà ìkà kó jọ kò ní ṣe é láǹfààní,Àmọ́ òdodo ló ń gbani lọ́wọ́ ikú.+
3 Jèhófà ò ní jẹ́ kí ebi pa olódodo,*+Bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ẹni burúkú tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́.
4 Ọwọ́ tó dilẹ̀ ń sọni di òtòṣì,+Àmọ́ ọwọ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára ń sọni di ọlọ́rọ̀.+
5 Ọmọ tó ní ìjìnlẹ̀ òye ń kó irè oko jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn,Àmọ́ ọmọ tó ń dójú tini ń sùn fọnfọn nígbà ìkórè.+
6 Ìbùkún wà lórí olódodo,+Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.
7 Ìrántí* olódodo yẹ fún ìbùkún,+Àmọ́ orúkọ àwọn ẹni burúkú yóò jẹrà.+
8 Ọlọ́gbọ́n ọkàn yóò gba ẹ̀kọ́,*+Àmọ́ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+
9 Ẹni tó ń rìn nínú ìwà títọ́ yóò máa rìn nínú ààbò,+Àmọ́ àṣírí ẹni tó ń sọ ọ̀nà ara rẹ̀ di wíwọ́ yóò tú.+
10 Ẹni tó ń dínjú ń fa ẹ̀dùn ọkàn,+Ẹni tó sì ń sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.+
11 Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè,+Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.+
12 Ìkórìíra ló ń dá awuyewuye sílẹ̀,Àmọ́ ìfẹ́ máa ń bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.+
13 Ọgbọ́n wà ní ètè olóye,+Àmọ́ ọ̀pá wà fún ẹ̀yìn ẹni tí kò ní làákàyè.*+
14 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń fi ìmọ̀ ṣe ìṣúra,+Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń fa ìparun.+
15 Ohun ìní* ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi rẹ̀.
Ipò òṣì àwọn aláìní ni ìparun wọn.+
16 Iṣẹ́ olódodo ń yọrí sí ìyè;Àmọ́ iṣẹ́ ọwọ́ ẹni burúkú ń yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀.+
17 Ẹni tó ń gba ìbáwí jẹ́* ipa ọ̀nà ìyè fún àwọn èèyàn,Àmọ́ ẹni tó ń kọ ìbáwí ń kó àwọn èèyàn ṣìnà.
18 Ẹni tó ń bo ìkórìíra rẹ̀ mọ́ra ń parọ́,+Ẹni tó sì ń tan ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́* ká jẹ́ òmùgọ̀.
19 Tí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀, àṣìṣe ò ní ṣàì wáyé,+Àmọ́ ẹni tó bá ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ á máa fi ọgbọ́n hùwà.+
20 Ahọ́n olódodo dà bíi fàdákà tó dára jù lọ,+Àmọ́ ọkàn ẹni burúkú kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan.
21 Ẹnu olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn,*+Àmọ́ àwọn òmùgọ̀ ń kú nítorí wọn kò ní làákàyè.+
22 Ìbùkún Jèhófà ló ń sọni di ọlọ́rọ̀,+Kì í sì í fi ìrora* kún un.
23 Híhùwà àìnítìjú dà bí eré lójú òmùgọ̀,Àmọ́ ọgbọ́n wà fún ẹni tó ní òye.+
24 Ohun tí ẹni burúkú ń bẹ̀rù yóò ṣẹlẹ̀ sí i;Àmọ́ a ó ṣe ohun tí ọkàn àwọn olódodo fẹ́ fún wọn.+
25 Nígbà tí ẹ̀fúùfù bá fẹ́ kọjá, ẹni burúkú kò ní sí mọ́,+Àmọ́ olódodo jẹ́ ìpìlẹ̀ títí láé.+
26 Bí ọtí kíkan ṣe ń ṣe eyín àti bí èéfín ṣe ń ṣe ojú,Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ ṣe rí sí ẹni tó rán an níṣẹ́.*
27 Ìbẹ̀rù Jèhófà ń mú kí ẹ̀mí ẹni gùn,+Àmọ́ ọdún àwọn ẹni burúkú ni a ó gé kúrú.+
28 Ìfojúsọ́nà* àwọn olódodo ń mú ayọ̀ wá,+Àmọ́ ìrètí àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+
29 Ọ̀nà Jèhófà jẹ́ ibi ààbò fún aláìlẹ́bi,+Àmọ́ ìparun ló jẹ́ fún àwọn aṣebi.+
30 Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn olódodo ṣubú,+Àmọ́ àwọn ẹni burúkú ò ní gbé ilẹ̀ ayé mọ́.+
31 Ẹnu olódodo ń mú* ọgbọ́n jáde,Àmọ́, ahọ́n àyídáyidà ni a ó gé kúrò.
32 Ètè olódodo mọ ohun tó tọ́ láti sọ,Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú jẹ́ ẹ̀tàn.

