Òwe 16:1-33
16 Èèyàn lè gbèrò ohun kan lọ́kàn ara rẹ̀,*Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdáhùn rẹ̀* ti máa wá.+
2 Gbogbo ọ̀nà èèyàn máa ń tọ́* lójú ara rẹ̀,+Àmọ́ Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn.*+
3 Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́,*+Ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.
4 Jèhófà ti mú kí gbogbo nǹkan rí bó ṣe fẹ́,Kódà láti pa ẹni burúkú run ní ọjọ́ àjálù.+
5 Jèhófà kórìíra gbogbo ẹni tó ń gbéra ga.+
Ó dájú* pé wọn ò ní lọ láìjìyà.
6 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,+Ìbẹ̀rù Jèhófà sì máa ń mú kéèyàn yẹra fún ohun búburú.+
7 Tí inú Jèhófà bá dùn sí ọ̀nà èèyàn,Ó máa ń mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.+
8 Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀ àmọ́ kó jẹ́ olóòótọ́+Ju kéèyàn fi èrú kó èrè púpọ̀ jọ.+
9 Èèyàn lè ro bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe máa rí lọ́kàn rẹ̀,Àmọ́ Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ rẹ̀.+
10 Ìpinnu tó ní ìmísí* ló yẹ kó máa wà lẹ́nu ọba;+Kò gbọ́dọ̀ dá ẹjọ́ lọ́nà tí kò tọ́.+
11 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n pípé ti wá;Gbogbo òkúta ìwọ̀n tó wà nínú àpò jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+
12 Àwọn ọba kórìíra ìwà burúkú,+Nítorí òdodo ló ń fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ gbọn-in.+
13 Ọ̀rọ̀ òdodo jẹ́ ìdùnnú àwọn ọba.
Wọ́n fẹ́ràn ẹni tó bá ń sọ òótọ́.+
14 Ìbínú ọba dà bí òjíṣẹ́ ikú,+Àmọ́ ọlọ́gbọ́n ló ń tù ú lójú.*+
15 Ẹni tó bá rí ojú rere ọba, ayé onítọ̀hún á ládùn;Ojú rere rẹ̀ dà bíi ṣíṣú òjò ìgbà ìrúwé.+
16 Ó mà sàn kéèyàn ní ọgbọ́n ju kó ní wúrà o!+
Ó sì dára kéèyàn ní òye ju kó ní fàdákà.+
17 Láti yẹra fún ohun búburú ni ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin.
Ẹni tó bá ń ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀ ń dáàbò bo ẹ̀mí* rẹ̀.+
18 Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun,Ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.+
19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀* láàárín àwọn oníwà pẹ̀lẹ́+Ju kéèyàn pín nínú ẹrù tí àwọn agbéraga kó.
20 Ẹni tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye nínú ọ̀ràn yóò ṣàṣeyọrí,*Aláyọ̀ sì ni ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
21 Ẹni tó ní ọkàn ọgbọ́n ni a ó pè ní olóye,+Ẹni tó sì ń sọ̀rọ̀ rere* ń yíni lérò pa dà.+
22 Ìjìnlẹ̀ òye jẹ́ kànga ìyè fún àwọn tó ni ín,Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń bá wọn wí.
23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń fún ẹnu rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye+Ó sì ń fi ìyíniléròpadà kún ọ̀rọ̀ rẹ̀.
24 Ọ̀rọ̀ dídùn jẹ́ afárá oyin,Ó dùn mọ́ ọkàn,* ó sì ń wo egungun sàn.+
25 Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+
26 Ikùn* lébìrà ló ń mú kó ṣiṣẹ́ kára,Ebi tó ń pa á* sì ń mú kó tẹpá mọ́ṣẹ́.+
27 Èèyàn tí kò ní láárí máa ń hú ohun tí kò dáa jáde;+Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí iná tó ń jóni.+
28 Oníwàhálà* máa ń dá ìyapa sílẹ̀,+Abanijẹ́ sì máa ń tú àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.+
29 Oníwà ipá máa ń tan ọmọnìkejì rẹ̀Á sì kó o ṣìnà.
30 Bó ṣe ń ṣẹ́jú ló ń gbèrò ibi.
Ó fún ètè rẹ̀ pọ̀ bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ ibi.
31 Ewú orí jẹ́ adé ẹwà*+Nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.+
32 Ẹni tí kì í tètè bínú+ sàn ju akíkanjú ọkùnrin,Ẹni tó sì ń kápá ìbínú rẹ̀* sàn ju ẹni tó ṣẹ́gun ìlú.+
33 Orí itan ni à ń ṣẹ́ kèké lé,+Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìpinnu tí ó bá ṣe ti wá.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìdáhùn tí ó tọ́.” Ní Héb., “ìdáhùn ahọ́n.”
^ Ní Héb., “Èèyàn ló máa ń ṣètò ọkàn.”
^ Ní Héb., “mọ́.”
^ Ní Héb., “ẹ̀mí.”
^ Ní Héb., “Yí àwọn iṣẹ́ rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”
^ Ní Héb., “Ọwọ́ sí ọwọ́.”
^ Tàbí “Ìpinnu àtọ̀runwá.”
^ Tàbí “ń yẹra fún un.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ẹni tó rẹlẹ̀ ní ẹ̀mí.”
^ Ní Héb., “rí ire.”
^ Tàbí “tó ń tuni lára.” Ní Héb., “tó sì ní ètè dídùn.”
^ Tàbí “Ó dùn lẹ́nu.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”
^ Tàbí “Ọkàn.”
^ Ní Héb., “Ẹnu rẹ̀.”
^ Tàbí “Elétekéte.”
^ Tàbí “ògo.”
^ Ní Héb., “ṣàkóso ẹ̀mí rẹ̀.”