Òwe 1:1-33

  • Ohun tí òwe wà fún (1-7)

  • Ewu tó wà nínú ẹgbẹ́ búburú (8-19)

  • Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké jáde ní gbangba (20-33)

1  Òwe Sólómọ́nì,+ ọmọ Dáfídì,+ ọba Ísírẹ́lì:+   Láti kọ́* ọgbọ́n+ àti ìbáwí;Láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n;   Láti gba ìbáwí+ tó ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye,Òdodo,+ ìdájọ́ òdodo*+ àti ìdúróṣinṣin;*   Láti mú kí àwọn aláìmọ̀kan ní àròjinlẹ̀;+Láti mú kí ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti làákàyè.+   Ọlọ́gbọ́n máa ń fetí sílẹ̀, á sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i;+Olóye máa ń gba ìtọ́sọ́nà ọlọgbọ́n+   Láti lóye òwe àti ọ̀rọ̀ tó díjú,*Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àlọ́ wọn.+   Ìbẹ̀rù* Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀.+ Àwọn òmùgọ̀ ni kì í ka ọgbọ́n àti ìbáwí sí.+   Ọmọ mi, fetí sí ìbáwí bàbá rẹ,+Má sì pa ẹ̀kọ́* ìyá rẹ tì.+   Wọ́n dà bí adé ẹwà fún orí rẹ+Àti ohun ọ̀ṣọ́ tó rẹwà fún ọrùn rẹ.+ 10  Ọmọ mi, tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá fẹ́ fa ojú rẹ mọ́ra, má gbà.+ 11  Tí wọ́n bá sọ pé: “Jẹ́ ká lọ. Ká lọ lúgọ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀. Àá fara pa mọ́, àá sì dúró de àwọn aláìṣẹ̀ tó máa kó sọ́wọ́ wa. 12  A máa gbé wọn mì láàyè bí Isà Òkú* ti ń ṣe,Lódindi, bí àwọn tó ń lọ sínú kòtò. 13  Jẹ́ ká gba gbogbo ìṣúra wọn tó ṣeyebíye;Àá fi ẹrù tí a bá gbà kún ilé wa. 14  Dara pọ̀ mọ́ wa,*Àá sì jọ pín ohun tí a bá jí lọ́gbọọgba.”* 15  Ọmọ mi, má tẹ̀ lé wọn. Jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ jìnnà sí ọ̀nà wọn,+ 16  Nítorí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ láti ṣe ibi;Wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ 17  Asán ni téèyàn bá ta àwọ̀n sílẹ̀ níṣojú ẹyẹ. 18  Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi lúgọ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀;Wọ́n fara pa mọ́ láti gba ẹ̀mí* àwọn ẹlòmíì. 19  Báyìí ni ọ̀nà àwọn tó ń wá èrè tí kò tọ́,Tó máa gba ẹ̀mí* àwọn tó ń kó o jọ.+ 20  Ọgbọ́n tòótọ́+ ń ké jáde ní ojú ọ̀nà.+ Ó ń gbé ohùn rẹ̀ sókè ní àwọn ojúde ìlú.+ 21  Ó ké jáde ní igun* ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà. Ní àtiwọ àwọn ẹnubodè ìlú, ó ń sọ pé:+ 22  “Ìgbà wo ni ẹ̀yin aláìmọ̀kan máa jáwọ́ nínú àìmọ̀kan yín? Ìgbà wo ni ẹ̀yin afiniṣẹ̀sín máa gbádùn fífini ṣẹ̀sín dà? Ìgbà wo sì ni ẹ̀yin òmùgọ̀ máa kórìíra ìmọ̀ dà?+ 23  Gba ìbáwí mi.*+ Nígbà náà, màá tú ẹ̀mí mi jáde fún yín;Màá jẹ́ kí ẹ mọ àwọn ọ̀rọ̀ mi.+ 24  Nítorí mò ń pè, àmọ́ ẹ ò dáhùn,Mo na ọwọ́ mi jáde, àmọ́ kò sẹ́ni tó fiyè sí i,+ 25  Ẹ kì í ka gbogbo ìmọ̀ràn mi síẸ kì í sì í gba ìbáwí mi, 26  Èmi náà á rẹ́rìn-ín nígbà tí àjálù bá dé bá yín;Màá fi yín ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tí ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù bá dé,+ 27  Nígbà tí ohun tí ẹ̀ ń bẹ̀rù bá dé bí ìjì,Tí àjálù yín sì dé bí ìjì líle,Nígbà tí ìdààmú àti wàhálà bá dé bá yín. 28  Ní àkókò yẹn, wọ́n á máa pè mí, àmọ́ mi ò ní dáhùn;Wọ́n á máa fi ìtara wá mi, àmọ́ wọn ò ní rí mi,+ 29  Torí wọ́n kórìíra ìmọ̀,+Wọn ò sì bẹ̀rù Jèhófà.+ 30  Wọn ò gba ìmọ̀ràn mi;Wọn ò ka gbogbo ìbáwí mi sí. 31  Torí náà, wọ́n á jìyà* ọ̀nà tí wọ́n yàn,+Ìmọ̀ràn* wọn á sì yí dà lé wọn lórí. 32  Nítorí ìwà àìníjàánu àwọn aláìmọ̀kan ni yóò pa wọ́n,Àìka-nǹkan-sí àwọn òmùgọ̀ ni yóò sì pa wọ́n run. 33  Àmọ́ ẹni tó ń fetí sí mi á máa gbé lábẹ́ ààbò+Ìbẹ̀rù àjálù kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “mọ.”
Tàbí “ohun tó tọ́.”
Tàbí “àìṣègbè.”
Tàbí “àkàwé.”
Tàbí “Ọ̀wọ̀ fún.”
Tàbí “òfin.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “Da ìpín rẹ pọ̀ mọ́ tiwa.”
Tàbí “jọ lo àpò (pọ́ọ̀sì) kan náà.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “orí.”
Tàbí “Yí pa dà tí mo bá bá ọ wí.”
Ní Héb., “jẹ nínú èso.”
Tàbí “Ètekéte; èrò.”