Òwe 13:1-25
13 Ọlọ́gbọ́n ọmọ máa ń gba ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀,+Àmọ́ ẹlẹ́gàn kì í fetí sí ìbáwí.*+
2 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa jẹ́ kó rí ohun rere gbà,+Àmọ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn oníbékebèke máa ń jẹ́ kí wọ́n hùwà ipá.
3 Ẹni tó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀* ń dáàbò bo ẹ̀mí* rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó ń la ẹnu rẹ̀ gbàgà yóò pa run.+
4 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ọ̀lẹ ń fẹ́, síbẹ̀ kò* ní nǹkan kan,+Àmọ́ ẹni* tó ń ṣiṣẹ́ kára yóò ní ànító.*+
5 Olódodo kórìíra irọ́,+Àmọ́ ìwà ẹni burúkú ń fa ìtìjú àti àbùkù.
6 Òdodo ń dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ tọ́,+Àmọ́ ìwà burúkú máa ń dojú ẹlẹ́ṣẹ̀ dé.
7 Ẹnì kan wà tó ń ṣe bíi pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀ kò ní nǹkan kan;+Ẹlòmíì sì wà tó ń ṣe bíi pé aláìní lòun, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ.
8 Ọrọ̀ ni ọlọ́rọ̀ fi ń ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà,+Àmọ́ ẹnikẹ́ni kì í halẹ̀ mọ́ aláìní.*+
9 Ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo mọ́lẹ̀ rekete,*+Àmọ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú ni a ó pa.+
10 Wàhálà ni ìkọjá àyè máa ń dá sílẹ̀,+Àmọ́ ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.*+
11 Ọrọ̀ tí èèyàn fi ìkánjú kó jọ* kì í pẹ́ tán,+Àmọ́ ọrọ̀ tí èèyàn ń kó jọ díẹ̀díẹ̀* á máa pọ̀ sí i.
12 Ìrètí* pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn,+Àmọ́ nígbà tí ìfẹ́ ọkàn ẹni bá ṣẹ, igi ìyè ni.+
13 Ẹni tí kò bá ka ìtọ́ni* sí á jìyà rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá bọ̀wọ̀ fún àṣẹ yóò gba èrè rẹ̀.+
14 Ẹ̀kọ́* ọlọgbọ́n jẹ́ orísun ìyè+Kì í jẹ́ kéèyàn kó sínú ìdẹkùn ikú.
15 Ìjìnlẹ̀ òye ń mú kéèyàn jèrè ojú rere,Àmọ́ ọ̀nà àwọn oníbékebèke korò.
16 Aláròjinlẹ̀ máa ń fi ìmọ̀ hùwà,+Àmọ́ òmùgọ̀ máa ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+
17 Òjíṣẹ́ burúkú máa ń kó sínú ìjàngbọ̀n,+Àmọ́ aṣojú tó jẹ́ olóòótọ́ ń mú ìwòsàn wá.+
18 Ẹni tí kò bá ka ìbáwí sí á di òtòṣì, á sì kan àbùkù,Àmọ́ ẹni tó bá ń gba ìtọ́sọ́nà* ni a ó gbé ga.+
19 Nígbà tí ìfẹ́ ọkàn ẹni bá ṣẹ, ó máa ń dùn mọ́ni,*+Àmọ́ òmùgọ̀ kì í fẹ́ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.+
20 Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n,+Àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.+
21 Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+Àmọ́ aásìkí ni èrè àwọn olódodo.+
22 Ẹni rere máa ń fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,Àmọ́ ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó kó jọ fún àwọn olódodo.+
23 Ọ̀pọ̀ oúnjẹ ló ń jáde látinú oko tí àwọn aláìní dá,Àmọ́ àìsí ìdájọ́ òdodo lè gbá a* lọ.
24 Ẹni tó bá fa ọ̀pá* sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa ń bá a wí dáadáa.*+
25 Olódodo ń jẹ àjẹtẹ́rùn,*+Àmọ́ inú àwọn ẹni burúkú ṣófo.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”
^ Tàbí “ohun tó ń sọ.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ̀ kò.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “ni a ó mú sanra.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “aláìní kì í gbọ́ ìbáwí.”
^ Ní Héb., “ń yọ̀.”
^ Tàbí “fèrò wérò.”
^ Tàbí “Ọrọ̀ tó wá látinú asán.”
^ Ní Héb., “ń fi ọwọ́ kó jọ.”
^ Tàbí “Ìfojúsọ́nà.”
^ Tàbí “ọ̀rọ̀.”
^ Tàbí “Òfin.”
^ Tàbí “ìbáwí.”
^ Tàbí “mọ́ ọkàn.”
^ Tàbí “aláìní.”
^ Tàbí “ìbáwí; ìfìyàjẹni.”
^ Tàbí kó jẹ́, “kánmọ́kánmọ́.”
^ Tàbí “Olódodo ń jẹ, ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn.”

