Òwe 29:1-27

  • Ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ máa ń kó ìtìjú báni (15)

  • Láìsí ìran, àwọn èèyàn á ya ìyàkuyà (18)

  • Ẹni tó ń bínú máa ń dá wàhálà sílẹ̀ (22)

  • Onírẹ̀lẹ̀ máa ń gba ògo (23)

  • Ìbẹ̀rù èèyàn jẹ́ ìdẹkùn (25)

29  Ẹni tó ń mú ọrùn rẹ̀ le* lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbáwí +Yóò pa run lójijì láìsí àtúnṣe.+   Nígbà tí olódodo bá pọ̀, àwọn èèyàn á máa yọ̀,Àmọ́ tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn èèyàn á máa kérora.+   Ẹni tó fẹ́ràn ọgbọ́n ń mú bàbá rẹ̀ yọ̀,+Àmọ́ ẹni tó ń bá àwọn aṣẹ́wó kẹ́gbẹ́ ń fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò.+   Ìdájọ́ òdodo ni ọba fi ń mú kí ilẹ̀ rẹ̀ tòrò,+Àmọ́ ẹni tó ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò da ibẹ̀ rú.   Ẹni tó ń pọ́n ọmọnìkejì rẹ̀Ń ta àwọ̀n fún ẹsẹ̀ rẹ̀.+   Ẹ̀ṣẹ̀ èèyàn búburú ń dẹkùn mú un,+Àmọ́ olódodo ń kígbe ayọ̀, inú rẹ̀ sì ń dùn.+   Ẹ̀tọ́ àwọn aláìní jẹ olódodo lọ́kàn,+Àmọ́ ẹni burúkú kì í ronú irú nǹkan bẹ́ẹ̀.+   Àwọn tó ń fọ́nnu máa ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ nínú ìlú,+Àmọ́ àwọn tó gbọ́n máa ń paná ìbínú.+   Nígbà tí ọlọ́gbọ́n bá ń bá òmùgọ̀ fa ọ̀rọ̀,Ariwo àti yẹ̀yẹ́ á gbòde kan, síbẹ̀ kò ní sí ìsinmi.+ 10  Àwọn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ máa ń kórìíra ẹni tó bá jẹ́ aláìṣẹ̀,*+Wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí* àwọn adúróṣinṣin.* 11  Gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára* òmùgọ̀ ló máa ń sọ jáde,+Àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń mú sùúrù.+ 12  Tí alákòóso bá ti ń fetí sí irọ́,Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò di ẹni burúkú.+ 13  Ohun tí aláìní àti aninilára fi jọra* ni pé: Jèhófà ń tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú àwọn méjèèjì.* 14  Tí ọba bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní bó ṣe tọ́,+Ìtẹ́ rẹ̀ á fìdí múlẹ̀ títí lọ.+ 15  Ọ̀pá* àti ìbáwí ń kọ́ni ní ọgbọ́n,+Àmọ́ ọmọ tí a bá fi sílẹ̀ máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀. 16  Tí àwọn ẹni burúkú bá ti ń pọ̀ sí i, ẹ̀ṣẹ̀ á máa pọ̀ sí i,Àmọ́ àwọn olódodo yóò rí ìṣubú wọn.+ 17  Kọ́ ọmọ rẹ, yóò fún ọ ní ìsinmi;Yóò sì mú inú rẹ dùn* gan-an.+ 18  Níbi tí kò bá ti sí ìran,* àwọn èèyàn á máa ṣe bó ṣe wù wọ́n,+Àmọ́ aláyọ̀ ni àwọn tó ń pa òfin mọ́.+ 19  Ìránṣẹ́ kì í jẹ́ kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ẹnu tọ́ òun sọ́nà,Bó tiẹ̀ yé e, kò ní ṣègbọràn.+ 20  Ṣé o ti rí ẹni tí kì í ronú kó tó sọ̀rọ̀?+ Ìrètí wà fún òmùgọ̀ ju fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ.+ 21  Tí a bá kẹ́ ìránṣẹ́ kan ní àkẹ́jù látìgbà èwe rẹ̀,Tó bá yá, kò ní mọ ọpẹ́ dá. 22  Ẹni tó bá ń tètè bínú máa ń dá wàhálà sílẹ̀;+Onínúfùfù sì máa ń dá ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀.+ 23  Ìgbéraga èèyàn ni yóò rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò gba ògo.+ 24  Ẹni tó ń bá olè kẹ́gbẹ́ kórìíra ara rẹ̀.* Ó lè gbọ́ pé kí àwọn èèyàn wá jẹ́rìí,* àmọ́ kò ní sọ nǹkan kan.+ 25  Ìbẹ̀rù* èèyàn jẹ́* ìdẹkùn,+Àmọ́ ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò rí ààbò.+ 26  Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ bá alákòóso sọ̀rọ̀,*Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èèyàn ti ń rí ìdájọ́ òdodo gbà.+ 27  Aláìṣòótọ́ jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú olódodo,+Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ tọ́ sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lójú èèyàn burúkú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó ń ṣorí kunkun.”
Tàbí “aláìlẹ́bi.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí kó jẹ́, “Àmọ́ adúróṣinṣin máa ń wá ọ̀nà láti dáàbò bo ẹ̀mí rẹ̀. ”
Ní Héb., “Gbogbo ẹ̀mí.”
Ní Héb., “bára pàdé.”
Ìyẹn ni pé, Òun ló fún wọn ní ẹ̀mí.
Tàbí “Ìbáwí; Ìfìyàjẹni.”
Tàbí “mú ọkàn rẹ yọ̀.”
Tàbí “ìran alásọtẹ́lẹ̀; ìfihàn.”
Tàbí “ọkàn òun fúnra rẹ̀.”
Tàbí “gbọ́ ìbúra kan tó ní ègún nínú.”
Ní Héb., “Wíwárìrì nítorí.”
Tàbí “ń dẹ.”
Tàbí kó jẹ́, “ń wá ojú rere alákòóso.” Ní Héb., “ń wá ojú alákòóso.”