Òwe 3:1-35

  • Jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà (1-12)

    • Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà (9)

  • Ọgbọ́n ń fúnni láyọ̀ (13-18)

  • Ọgbọ́n ń dáàbò boni (19-26)

  • Ìwà tó yẹ ká máa hù sáwọn èèyàn (27-35)

    • Máa ṣe rere fún àwọn èèyàn nígbà tí o bá lè ṣe é (27)

3  Ọmọ mi, má gbàgbé ẹ̀kọ́* mi,Sì jẹ́ kí ọkàn rẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́,   Nítorí wọ́n á fi ọ̀pọ̀ ọjọ́Àti ẹ̀mí gígùn pẹ̀lú àlàáfíà kún un fún ọ.+   Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́* fi ọ́ sílẹ̀.+ So wọ́n mọ́ ọrùn rẹ;Kọ wọ́n sí wàláà ọkàn rẹ;+   Nígbà náà, wàá rí ojú rere àti òye tó jinlẹ̀ gan-anLójú Ọlọ́run àti èèyàn.+   Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà,+Má sì gbára lé òye tìrẹ.+   Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ,+Á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.+   Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ.+ Bẹ̀rù Jèhófà kí o sì yẹra fún ibi.   Yóò jẹ́ ìwòsàn fún ara* rẹÀti ìtura fún egungun rẹ.   Fi àwọn ohun ìní rẹ tó níye lórí bọlá fún Jèhófà,+Pẹ̀lú àkọ́so* gbogbo irè oko rẹ;*+ 10  Nígbà náà, àwọn ilé ìkẹ́rùsí rẹ á kún fọ́fọ́,+Wáìnì tuntun á sì kún àwọn ẹkù* rẹ ní àkúnwọ́sílẹ̀. 11  Ọmọ mi, má ṣe kọ ìbáwí Jèhófà,+Má sì kórìíra ìtọ́sọ́nà rẹ̀,+ 12  Torí pé àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ló máa ń bá wí,+Bí bàbá ṣe máa ń fún ọmọ tí inú rẹ̀ dùn sí ní ìbáwí.+ 13  Aláyọ̀ ni ẹni tó wá ọgbọ́n rí+Àti ẹni tó ní òye; 14  Kéèyàn ní in sàn ju kéèyàn ní fàdákà,Kéèyàn jèrè rẹ̀ sì sàn ju kéèyàn jèrè wúrà.+ 15  Ó ṣeyebíye ju iyùn* lọ;Kò sí ohun míì tí o fẹ́ tó ṣeé fi wé e. 16  Ẹ̀mí gígùn wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;Ọrọ̀ àti ògo sì wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀. 17  Àwọn ọ̀nà rẹ̀ gbádùn mọ́ni,Àlàáfíà sì wà ní gbogbo ipa ọ̀nà rẹ̀.+ 18  Igi ìyè ni fún àwọn tó dì í mú,Aláyọ̀ ni a ó sì máa pe àwọn tó dì í mú ṣinṣin.+ 19  Ọgbọ́n ni Jèhófà fi dá ayé.+ Òye ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in.+ 20  Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ni àwọn ibú omi fi pínyàTí ìkùukùu ojú sánmà sì ń mú kí ìrì sẹ̀.+ 21  Ọmọ mi, máa fi wọ́n* sọ́kàn. Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́; 22  Wọ́n á fún ọ* ní ìyèWọ́n á sì jẹ́ ọ̀ṣọ́ fún ọrùn rẹ; 23  Nígbà náà, wàá máa rìn láìséwu ní ọ̀nà rẹ,Ẹsẹ̀ rẹ kò sì ní kọ́* ohunkóhun.+ 24  Nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, ẹ̀rù ò ní bà ọ́;+Wàá sùn, oorun rẹ á sì dùn mọ́ ọ.+ 25  O ò ní bẹ̀rù àjálù òjijì+Tàbí ìjì tó ń bọ̀ lórí àwọn ẹni burúkú.+ 26  Nítorí Jèhófà yóò jẹ́ ìgbọ́kànlé rẹ;+Kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kó sí pańpẹ́.+ 27  Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún*+Tó bá wà níkàáwọ́ rẹ* láti ṣe é.+ 28  Má sọ fún ọmọnìkejì rẹ pé, “Máa lọ ná, tó bá dọ̀la kí o pa dà wá, màá fún ọ,”Nígbà tí o lè fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 29  Má gbèrò ibi sí ọmọnìkejì rẹ+Nígbà tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ pé kò séwu. 30  Má ṣe bá ẹnì kankan jà láìnídìí+Nígbà tí kò ṣe aburú kankan sí ọ.+ 31  Má ṣe jowú ẹni tó ń hùwà ipá+Má sì yan èyíkéyìí nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀, 32  Nítorí Jèhófà kórìíra oníbékebèke,+Ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.+ 33  Ègún Jèhófà wà lórí ilé ẹni burúkú,+Àmọ́, ó ń bù kún ilé àwọn olódodo.+ 34  Ó ń fi àwọn afiniṣẹ̀sín ṣe ẹlẹ́yà,+Àmọ́, ó ń ṣojú rere sí àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.+ 35  Àwọn ọlọ́gbọ́n á jogún ọlá,Àmọ́, ẹ̀tẹ́ ni àwọn òmùgọ̀ fi ń ṣayọ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “òfin.”
Tàbí “òtítọ́.”
Ní Héb., “ìdodo.”
Tàbí “èyí tó dára jù lọ nínú.”
Tàbí “owó tó ń wọlé fún ọ.”
Tàbí “àwọn ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì.”
Ó ṣe kedere pé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí àwọn ẹsẹ tó ṣáájú mẹ́nu bà ló ń tọ́ka sí.
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “gbá.”
Tàbí “àwọn tí ó tọ́ sí.”
Tàbí “Tí o bá lágbára.”