Òwe 18:1-24

  • Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, ire ara rẹ̀ ló ń wá, kò sì gbọ́n (1)

  • Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára (10)

  • Ọrọ̀ kì í ṣe ààbò gidi (11)

  • Ọgbọ́n wà nínú fífi etí sí tọ̀túntòsì (17)

  • Ọ̀rẹ́ kan ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ (24)

18  Ẹni tó bá ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ ń wá ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀;Gbogbo ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ ni yóò máa kọ̀.*   Inú òmùgọ̀ kì í dùn sí òye;Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń tú ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ jáde.+   Nígbà tí ẹni burúkú bá dé, ìkórìíra náà á dé,Ìtìjú ló sì máa ń bá àbùkù rìn.+   Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn dà bí odò tó jìn.+ Orísun ọgbọ́n dà bí odò tó ń ṣàn.   Kò dáa kí a ṣe ojúsàájú sí ẹni burúkú+Tàbí kí a fi ẹ̀tọ́ olódodo dù ú.+   Ọ̀rọ̀ ẹnu òmùgọ̀ máa ń dá ìjà sílẹ̀,+Ẹnu rẹ̀ sì máa ń mú kí wọ́n lù ú.+   Ẹnu òmùgọ̀ ni ìparun rẹ̀,+Ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹkùn fún ẹ̀mí* rẹ̀.   Ọ̀rọ̀ abanijẹ́ dà bí òkèlè dídùn;*+Tí a gbé mì sínú ikùn lọ́hùn-ún.+   Ẹni tó bá ya ọ̀lẹ nídìí iṣẹ́ rẹ̀,Ọmọ ìyá ẹni tó ń fa ìparun ni.+ 10  Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára.+ Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.*+ 11  Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi rẹ̀;Lọ́kàn rẹ̀, ó dà bí ògiri tó ń dáàbò boni.+ 12  Ọkàn gíga ló ń ṣáájú ìṣubú,+Ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń ṣáájú ògo.+ 13  Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀,Ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.+ 14  Ẹ̀mí èèyàn lè mú kó fara da àìsàn,+Àmọ́, ta ló lè fara da ẹ̀mí tí ìdààmú bá?*+ 15  Ọkàn ẹni tó ní òye ń gba ìmọ̀,+Etí ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gbọ́ ìmọ̀. 16  Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tó fúnni;+Ó ń jẹ́ kó dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni ńlá. 17  Ẹni tó bá kọ́kọ́ ro ẹjọ́ rẹ̀ ló ń dà bíi pé ó jàre,+Títí ẹnì kejì fi wá, tó sì bi í ní ìbéèrè.*+ 18  Ṣíṣẹ́ kèké máa ń parí awuyewuye+Ó sì ń làjà* láàárín àwọn alágbára tí wọ́n ń fa ọ̀rọ̀. 19  Ọmọ ìyá tí a ṣẹ̀, ó le ju ìlú olódi lọ,+Àwọn ìjà kan sì wà tó dà bí ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè ilé gogoro tó láàbò.+ 20  Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa ń fi ohun rere tẹ́ ikùn rẹ̀ lọ́rùn;+Yóò rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ohun tí ẹnu rẹ̀ sọ. 21  Ahọ́n ní agbára láti fa ikú tàbí ìyè;+Àwọn tó bá fẹ́ràn láti máa lò ó yóò jẹ èrè rẹ̀.+ 22  Ẹni tó bá rí aya rere fẹ́ ti rí ohun rere,+Ó sì rí ojú rere* Jèhófà.+ 23  Aláìní máa ń bẹ̀bẹ̀ tó bá ń sọ̀rọ̀,Àmọ́ ọlọ́rọ̀ máa ń dáhùn lọ́nà líle. 24  Àwọn ọ̀rẹ́ kan wà tí wọ́n ṣe tán láti ṣe ara wọn níkà,+Àmọ́ ọ̀rẹ́ kan wà tó ń fà mọ́ni ju ọmọ ìyá lọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “yóò kórìíra.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ohun téèyàn fẹ́ fi ojú kòkòrò gbé mì.”
Ní Héb., “a sì gbé e ga sókè,” ìyẹn ni pé, ọwọ́ kò lè tó o, kò sí ohun tó máa ṣe é.
Tàbí “ta ló lè fara dà á tí nǹkan bá tojú súni pátápátá?”
Tàbí “wádìí rẹ̀ wò látòkèdélẹ̀.”
Ní Héb., “ṣe ìyàsọ́tọ̀.”
Tàbí “ìtẹ́wọ́gbà.”