Òwe 28:1-28

  • Àdúrà ẹni tí kò pa òfin mọ́ jẹ́ ohun ìríra (9)

  • Ẹni tó bá jẹ́wọ́ á rí àánú gbà (13)

  • Èèyàn ò lè kánjú di ọlọ́rọ̀ láì jẹ̀bi (20)

  • Ká báni wí sàn ju ká máa pọ́nni (23)

  • Ẹni tó lawọ́ kò ní ṣaláìní (27)

28  Ẹni burúkú ń sá nígbà tí ẹnì kankan kò lé e,Àmọ́ olódodo láyà bíi kìnnìún.*+   Tí ẹ̀ṣẹ̀* bá wà ní ilẹ̀ kan, olórí ibẹ̀ kì í pẹ́ kí òmíì tó jẹ,+Àmọ́ nípasẹ̀ ẹnì kan tó ní òye àti ìmọ̀, olórí* yóò pẹ́ lórí ìtẹ́.+   Tálákà tó ń lu aláìní ní jìbìtì,+Ó dà bí òjò tó ń gbá gbogbo oúnjẹ lọ.   Àwọn tó ń pa òfin tì máa ń yin àwọn ẹni burúkú,Àmọ́ àwọn tó ń pa òfin mọ́ máa ń bínú sí wọn.+   Àwọn ẹni ibi kò lè lóye ìdájọ́ òdodo,Àmọ́ àwọn tó ń wá Jèhófà ń lóye ohun gbogbo.+   Aláìní tó ń rìn nínú ìwà títọ́Sàn ju olówó tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́ lọ.+   Ọmọ tó lóye máa ń pa òfin mọ́,Àmọ́ ẹni tó ń bá àwọn alájẹkì kẹ́gbẹ́ ń dójú ti bàbá rẹ̀.+   Ẹni tó ń gba èlé+ àti èlé gọbọi láti mú kí ọrọ̀ rẹ̀ pọ̀Ń kó o jọ fún ẹni tó ń ṣàánú aláìní.+   Ẹni tí kì í fetí sí òfin,Àdúrà rẹ̀ pàápàá jẹ́ ohun ìríra.+ 10  Ẹni tó bá ń ṣi adúróṣinṣin lọ́nà láti ṣe búburú máa já sínú kòtò òun fúnra rẹ̀,+Àmọ́ àwọn aláìlẹ́bi máa jogún ohun rere.+ 11  Ọlọ́rọ̀ gbọ́n ní ojú ara rẹ̀,+Àmọ́ aláìní tó ní òye lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.+ 12  Nígbà tí olódodo bá borí, ìdùnnú á ṣubú layọ̀,Àmọ́ nígbà tí agbára bá dọ́wọ́ ẹni burúkú, àwọn èèyàn á lọ fara pa mọ́.+ 13  Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí,+Àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.+ 14  Aláyọ̀ ni ẹni tó bá ń kíyè sára* nígbà gbogbo,Àmọ́ ẹni tó bá ń sé ọkàn rẹ̀ le yóò ṣubú sínú ìyọnu.+ 15  Bíi kìnnìún tó ń kùn àti bíárì tó ń kù gììrì mọ́ nǹkanNi ìkà èèyàn tó ń ṣàkóso àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+ 16  Aṣáájú tí kò lóye máa ń ṣi agbára lò,+Àmọ́ ẹni tó kórìíra èrè tí kò tọ́ yóò mú ẹ̀mí ara rẹ̀ gùn.+ 17  Ẹni tí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bá wọ̀ lọ́rùn torí pé ó gba ẹ̀mí èèyàn* yóò máa sá títí á fi wọnú sàréè.*+ Kí ẹnì kankan má ṣe dì í mú. 18  Ẹni tó bá ń rìn láìlẹ́bi ni a ó gbà là,+Àmọ́ ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ wọ́ yóò ṣubú lójijì.+ 19  Ẹni tó bá ń ro ilẹ̀ rẹ̀ yóò ní oúnjẹ tó pọ̀,Àmọ́ ẹni tó ń lé àwọn ohun tí kò ní láárí yóò di òtòṣì paraku.+ 20  Olóòótọ́ èèyàn yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún,+Àmọ́ ọwọ́ ẹni tó ń kánjú láti di olówó kò lè mọ́.+ 21  Kò dáa kéèyàn máa ṣe ojúsàájú;+Àmọ́ èèyàn lè ṣe ohun tí kò tọ́ nítorí búrẹ́dì tí kò tó nǹkan. 22  Onílara* èèyàn ń wá bó ṣe máa di olówó,Kò mọ̀ pé òṣì máa ta òun. 23  Ẹni tó bá ń báni wí+ yóò rí ojú rere níkẹyìn+Ju ẹni tó ń fi ahọ́n rẹ̀ pọ́nni. 24  Ẹni tó bá ja bàbá àti ìyá rẹ̀ lólè tó sì ń sọ pé, “Kò sóhun tó burú níbẹ̀,”+Ẹlẹgbẹ́ ẹni tó ń fa ìparun ni.+ 25  Olójúkòkòrò* máa ń dá ìyapa sílẹ̀,Àmọ́ ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà yóò láásìkí.*+ 26  Ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn ara rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀,+Àmọ́ ẹni tó ń fi ọgbọ́n rìn yóò yè bọ́.+ 27  Ẹni tó bá ń fún aláìní ní nǹkan kò ní ṣaláìní,+Àmọ́ ẹni tó bá ń gbójú kúrò lára wọn yóò gba ọ̀pọ̀ ègún. 28  Nígbà tí agbára bá dọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú, àwọn èèyàn á fara pa mọ́,Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá ṣègbé, olódodo á pọ̀ sí i.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọmọ kìnnìún.”
Tàbí “ọ̀tẹ̀.”
Ní Héb., “òun.”
Tàbí “ẹni tó bá ń bẹ̀rù.”
Tàbí “tí ẹ̀jẹ̀ ọkàn kan bá wọ̀ lọ́rùn.”
Tàbí “kòtò.”
Tàbí “Olójúkòkòrò.”
Tàbí kó jẹ́, “Agbéraga ẹ̀dá.”
Ní Héb., “ni a ó mú sanra.”