Òwe 15:1-33

  • Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀ (1)

  • Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo (3)

  • Àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú Ọlọ́run dùn (8)

  • Láìsí ìfinúkonú, èrò á dasán (22)

  • Máa ṣe àṣàrò kí o tó dáhùn (28)

15  Ìdáhùn pẹ̀lẹ́* máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀,+Àmọ́ ọ̀rọ̀ líle* ń ru ìbínú sókè.+   Ahọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ lọ́nà rere,+Àmọ́ ẹnu àwọn òmùgọ̀ máa ń tú ọ̀rọ̀ ẹ̀gọ̀ jáde.   Ojú Jèhófà wà níbi gbogbo,Ó ń ṣọ́ ẹni burúkú àti ẹni rere.+   Ahọ́n pẹ̀lẹ́* jẹ́ igi ìyè,+Àmọ́ ọ̀rọ̀ békebèke máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.*   Òmùgọ̀ kì í ka ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀ sí,+Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń gba ìbáwí.*+   Ọ̀pọ̀ ìṣúra ló wà nínú ilé olódodo,Àmọ́ èso* ẹni burúkú máa ń fa wàhálà bá a.+   Ètè ọlọ́gbọ́n máa ń tan ìmọ̀ kálẹ̀,+Àmọ́ ọkàn àwọn òmùgọ̀ kì í ṣe bẹ́ẹ̀.+   Ẹbọ ẹni burúkú jẹ́ ohun ìríra lójú Jèhófà,+Àmọ́ àdúrà àwọn adúróṣinṣin máa ń múnú Rẹ̀ dùn.+   Jèhófà kórìíra ọ̀nà ẹni burúkú,+Àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń wá òdodo.+ 10  Ìbáwí dà bí ohun tí kò dára* lójú ẹni tó ń ṣìnà,+Ẹni tó bá sì kórìíra ìbáwí á kú.+ 11  Isà Òkú* àti ibi ìparun* ṣí sílẹ̀ gbayawu lójú Jèhófà.+ Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ọkàn èèyàn!+ 12  Ẹlẹ́gàn kì í fẹ́ràn ẹni tó ń tọ́ ọ sọ́nà.*+ Kì í fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọlọ́gbọ́n.+ 13  Inú dídùn ló ń mórí yá,Àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn máa ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì.+ 14  Ọkàn tó ní òye máa ń wá ìmọ̀,+Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ ni àwọn òmùgọ̀ fi ń ṣe oúnjẹ jẹ.*+ 15  Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìyà ń jẹ,+Àmọ́ ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn* máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.+ 16  Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀, kó sì bẹ̀rù Jèhófà+Ju kó ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ pẹ̀lú àníyàn.*+ 17  Oúnjẹ tí a fi nǹkan ọ̀gbìn sè níbi tí ìfẹ́ wà+Sàn ju akọ màlúù àbọ́sanra* níbi tí ìkórìíra wà.+ 18  Onínúfùfù máa ń dá wàhálà sílẹ̀,+Àmọ́ ẹni tí kì í tètè bínú máa ń mú kí ìjà rọlẹ̀.+ 19  Ọ̀nà ọ̀lẹ dà bí igbó ẹ̀gún,+Àmọ́ ipa ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin dà bí ọ̀nà tó tẹ́jú.+ 20  Ọlọ́gbọ́n ọmọ máa ń mú inú bàbá rẹ̀ dùn,+Àmọ́ òmùgọ̀ èèyàn máa ń kórìíra ìyá rẹ̀.+ 21  Ẹni tí kò ní làákàyè* máa ń fi ìwà òmùgọ̀ ṣayọ̀,+Àmọ́ ẹni tó ní òye máa ń rìn lọ tààrà.+ 22  Láìsí ìfinúkonú,* èrò á dasán,Àmọ́ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn,* àṣeyọrí á wà.+ 23  Inú èèyàn máa ń dùn tí ìdáhùn rẹ̀ bá tọ̀nà,*+Ọ̀rọ̀ tó bá sì bọ́ sí àkókò mà dára o!+ 24  Ẹni tó ní ìjìnlẹ̀ òye ń tọ ọ̀nà ìyè tó lọ sókè,+Kí ó lè yẹra fún Isà Òkú* nísàlẹ̀.+ 25  Jèhófà máa ya ilé àwọn agbéraga lulẹ̀,+Àmọ́ kò ní jẹ́ kí wọ́n sún ààlà opó sẹ́yìn.+ 26  Jèhófà kórìíra èrò àwọn ẹni ibi,+Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára mọ́ lójú Rẹ̀.+ 27  Ẹni tó ń jẹ èrè tí kò tọ́ ń fa wàhálà* bá agbo ilé rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀ yóò máa wà láàyè.+ 28  Ọkàn olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn,*+Àmọ́ ẹnu ẹni burúkú máa ń tú ọ̀rọ̀ burúkú jáde. 29  Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú,Àmọ́ ó máa ń gbọ́ àdúrà àwọn olódodo.+ 30  Ojú tó ń dán* máa ń mú ọkàn yọ̀;Ìròyìn tó dára máa ń mú kí egungun lágbára.*+ 31  Ẹni tó ń fetí sí ìbáwí tó ń fúnni ní ìyè,Àárín àwọn ọlọ́gbọ́n ló ń gbé.+ 32  Ẹni tó bá ń kọ ìbáwí kórìíra ẹ̀mí* rẹ̀,+Àmọ́ ẹni tó bá ń gba ìbáwí ní òye.*+ 33  Ìbẹ̀rù Jèhófà ń kọ́ni lọ́gbọ́n,+Ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń ṣáájú ògo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Ọ̀rọ̀ tútù.”
Tàbí “ọ̀rọ̀ tó ń dunni.”
Tàbí “Ahọ́n tó ń woni sàn.”
Ní Héb., “ń wó ẹ̀mí palẹ̀.”
Tàbí “ìtọ́sọ́nà.”
Tàbí “owó tó ń wọlé fún.”
Tàbí “ohun tó le jù.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “àti Ábádónì.”
Tàbí “tó ń bá a wí.”
Tàbí “ń wá.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀ ń yọ̀.”
Tàbí “ìdàrúdàpọ̀.”
Ní Héb.,“tí wọ́n bọ́ ní ibùjẹ ẹran.”
Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”
Tàbí “pé àwọn èèyàn bára wọn sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.”
Tàbí “olùdámọ̀ràn.”
Ní Héb., “nínú ìdáhùn ẹnu rẹ̀.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ń kó ìtìjú.”
Tàbí “ń fara balẹ̀ ro bó ṣe máa dáhùn; máa ń ronú kí ó tó sọ̀rọ̀.”
Tàbí “Ẹ̀rín músẹ́.”
Ní Héb., “sanra.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ọkàn.”