Òwe 7:1-27

  • Rọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ Ọlọ́run, kí o sì wà láàyè (1-5)

  • Ó fa ojú ọ̀dọ́kùnrin aláìmọ̀kan mọ́ra (6-27)

    • “Bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á” (22)

7  Ọmọ mi, pa àwọn ọ̀rọ̀ mi mọ́,Kí o sì fi àwọn àṣẹ mi ṣe ìṣúra rẹ. +   Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì wà láàyè;+Pa ẹ̀kọ́* mi mọ́ bí ọmọlójú rẹ.   So wọ́n mọ́ ìka rẹ;Kọ wọ́n sí wàláà ọkàn rẹ. +   Sọ fún ọgbọ́n pé, “Arábìnrin mi ni ọ́,”Kí o sì pe òye ní “ìbátan mi,”   Láti dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ obìnrin oníwàkiwà,*+Lọ́wọ́ obìnrin oníṣekúṣe* àti àwọn ọ̀rọ̀ dídùn* rẹ̀.+   Lójú fèrèsé* ilé mi,Mo bojú wolẹ̀ látojú fèrèsé,*   Bí mo ṣe ń wo àwọn aláìmọ̀kan,*Mo kíyè sí ọ̀dọ́kùnrin kan tí kò ní làákàyè* láàárín àwọn ọ̀dọ́.+   Ó gba ojú ọ̀nà tó wà nítòsí ìyànà ilé obìnrin náà kọjá,Ó sì rìn lọ sí ọ̀nà ilé obìnrin náà   Ní ìrọ̀lẹ́, ní àṣálẹ́,+Nígbà tí ilẹ̀ ń ṣú, tí òkùnkùn sì ń kùn. 10  Ni mo bá rí obìnrin kan tó wá pàdé rẹ̀,Ó múra bí* aṣẹ́wó,+ ó ní ọkàn àrékérekè. 11  Ó jẹ́ aláriwo àti aláfojúdi.+ Kì í* dúró sílé. 12  Ó lè wà níta nísìnyí, àmọ́ ká tó ṣẹ́jú pẹ́, á ti dé ojúde ìlú,Kò sí oríta tí kì í dúró sí.+ 13  Obìnrin náà gbá a mú, ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu;Ó fi ọ̀dájú sọ fún un pé: 14  “Mo ti rú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀.+ Òní ni mo san àwọn ẹ̀jẹ́ mi. 15  Ìdí nìyẹn tí mo fi jáde wá pàdé rẹ,Láti wá ọ, mo sì ti rí ọ! 16  Mo ti tẹ́ àwọn aṣọ tó dára lé ibùsùn mi,Aṣọ ọ̀gbọ̀* aláràbarà láti Íjíbítì.+ 17  Mo ti fi òjíá, álóè àti sínámónì wọ́n ibùsùn mi.+ 18  Wá, jẹ́ ká jọ ṣeré ìfẹ́ títí di àárọ̀;Jẹ́ ká gbádùn ìfẹ́ láàárín ara wa, 19  Nítorí ọkọ mi ò sí nílé;Ó ti rin ìrìn àjò lọ sí ọ̀nà jíjìn. 20  Ó gbé àpò owó dání,Kò sì ní pa dà títí di ọjọ́ òṣùpá àrànmọ́jú.” 21  Ó fi ọ̀rọ̀ tó ń yíni lérò pa dà ṣì í lọ́nà.+ Ó fi ọ̀rọ̀ dídùn fa ojú rẹ̀ mọ́ra. 22  Lójijì, ó tẹ̀ lé obìnrin náà, bí akọ màlúù tí wọ́n ń mú lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa á,Bí òmùgọ̀ tí wọ́n fẹ́ fìyà jẹ nínú àbà,*+ 23  Títí ọfà fi gún ẹ̀dọ̀ rẹ̀ ní àgúnyọ;Bí ẹyẹ tó kó sínú pańpẹ́, kò mọ̀ pé ẹ̀mí òun máa lọ sí i.+ 24  Ní báyìí, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ mi;Ẹ fiyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ. 25  Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀. Má rìn gbéregbère wọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀,+ 26  Nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣekú pa,+Àwọn tó ti pa sì pọ̀ gan-an.+ 27  Ilé rẹ̀ lọ sí Isà Òkú;*Ó sọ̀ kalẹ̀ sínú yàrá ikú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “òfin.”
Ní Héb., “àjèjì obìnrin.” Wo Owe 2:16.
Ní Héb., “ilẹ̀ òkèèrè.” Wo Owe 2:16.
Tàbí “fífanimọ́ra.”
Tàbí “wíńdò.”
Ìyẹn, fèrèsé tó ní asẹ́ onígi.
Tàbí “aláìní ìrírí.”
Ní Héb., “tí ọkàn kù fún.”
Tàbí “wọṣọ.”
Ní Héb., “Ẹsẹ̀ rẹ̀ kì í.”
Tàbí “Aṣọ àtàtà.”
Tàbí “ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.