Òwe 9:1-18
9 Ọgbọ́n tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀;Ó ti gbẹ́ òpó rẹ̀ méjèèje.
2 Ó ti ṣètò gbogbo ẹran rẹ̀;*Ó ti po wáìnì rẹ̀;Ó sì ti tẹ́ tábìlì rẹ̀.
3 Ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jádeLáti ké jáde látorí àwọn ibi gíga ìlú pé:+
4 “Kí ẹni tó bá jẹ́ aláìmọ̀kan wọlé síbí.”
Ó sọ fún àwọn tí kò ní làákàyè* pé:
5 “Ẹ wá, ẹ jẹ oúnjẹ miKí ẹ sì mu nínú wáìnì tí mo ti pò.
6 Ẹ fi àìmọ̀kan yín* sílẹ̀, kí ẹ lè wà láàyè;+Kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà òye nìṣó.”+
7 Ẹni tó bá ń tọ́ afiniṣẹ̀sín sọ́nà ń wá àbùkù,+Ẹni tó bá sì ń bá ẹni burúkú wí yóò rí ìbànújẹ́.
8 Má ṣe bá afiniṣẹ̀sín wí, torí á kórìíra rẹ.+
Bá ọlọ́gbọ́n wí, yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.+
9 Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóò sì gbọ́n sí i. +
Kọ́ olódodo, yóò sì kọ́ ẹ̀kọ́ sí i.
10 Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,+Ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ+ sì ni òye.
11 Ọgbọ́n yóò jẹ́ kí ọjọ́ ayé rẹ di púpọ̀,+Yóò sì fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.
12 Tí o bá gbọ́n, o gbọ́n fún àǹfààní ara rẹ,Àmọ́ tí o bá ya afiniṣẹ̀sín, ìwọ nìkan lo máa jìyà rẹ̀.
13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo.+
Òpè ni, kò sì mọ nǹkan kan rárá.
14 Ó máa ń jókòó sí ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀Lórí ìjókòó ní àwọn ibi gíga ìlú,+
15 Ó ń pe àwọn tó ń kọjá lọ,Àwọn tó ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn, pé:
16 “Kí ẹni tó bá jẹ́ aláìmọ̀kan wọlé síbí.”
Ó sọ fún àwọn tí kò ní làákàyè* pé:+
17 “Omi tí a jí gbé máa ń dùn,Oúnjẹ tí a sì jẹ ní ìkọ̀kọ̀ máa ń gbádùn mọ́ni.”+
18 Àmọ́ wọn kò mọ̀ pé àwọn tí ikú ti pa* wà níbẹ̀,Àti pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ Isà Òkú.*+

