Àìsáyà 60:1-22
60 “Dìde, ìwọ obìnrin,+ tan ìmọ́lẹ̀, torí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé.
Ògo Jèhófà ń tàn sára rẹ.+
2 Torí, wò ó! òkùnkùn máa bo ayé,Ìṣúdùdù tó kàmàmà sì máa bo àwọn orílẹ̀-èdè;Àmọ́ Jèhófà máa tàn sára rẹ,Wọ́n sì máa rí ògo rẹ̀ lára rẹ.
3 Àwọn orílẹ̀-èdè máa lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ,+Àwọn ọba+ sì máa lọ sínú ẹwà rẹ tó ń tàn.*+
4 Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò yí ká!
Gbogbo wọn ti kóra jọ; wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.
Àwọn ọmọkùnrin rẹ ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,+Ẹ̀gbẹ́ ni wọ́n sì gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ sí.+
5 Ní àkókò yẹn, o máa rí i, o sì máa tàn yinrin,+Ọkàn rẹ máa lù kìkì, ó sì máa kún rẹ́rẹ́,Torí pé a máa darí ọrọ̀ òkun sọ́dọ̀ rẹ;Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè máa wá sọ́dọ̀ rẹ.+
6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ràkúnmí máa bo ilẹ̀ rẹ,*Àwọn akọ ọmọ ràkúnmí Mídíánì àti Eéfà.+
Gbogbo àwọn tó wá láti Ṣébà, wọ́n máa wá;Wọ́n máa gbé wúrà àti oje igi tùràrí.
Wọ́n máa kéde ìyìn Jèhófà.+
7 A máa kó gbogbo agbo ẹran Kídárì+ jọ sọ́dọ̀ rẹ.
Àwọn àgbò Nébáótì+ máa sìn ọ́.
Wọ́n máa wá sórí pẹpẹ mi pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà,+Màá sì ṣe ilé ológo mi* lọ́ṣọ̀ọ́.+
8 Àwọn wo nìyí tí wọ́n ń fò kọjá bí ìkùukùu,Bí àwọn àdàbà tó ń fò lọ sí ilé* wọn?
9 Torí àwọn erékùṣù máa gbẹ́kẹ̀ lé mi,+Àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì ló ṣíwájú,*Láti kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn,+Pẹ̀lú fàdákà wọn àti wúrà wọn,Síbi orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ àti sọ́dọ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,Torí ó máa ṣe ọ́ lógo.*+
10 Àwọn àjèjì máa mọ àwọn ògiri rẹ,Àwọn ọba wọn sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún ọ,+Torí ìbínú ni mo fi kọ lù ọ́,Àmọ́ màá fi ojúure* mi ṣàánú rẹ.+
11 Àwọn ẹnubodè rẹ máa wà ní ṣíṣí nígbà gbogbo;+Wọn ò ní tì wọ́n ní ọ̀sán tàbí ní òru,Láti mú ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá sọ́dọ̀ rẹ,Àwọn ọba wọn sì máa ṣáájú.+
12 Torí orílẹ̀-èdè àti ìjọba èyíkéyìí tí kò bá sìn ọ́ máa ṣègbé,Àwọn orílẹ̀-èdè sì máa pa run pátápátá.+
13 Ọ̀dọ̀ rẹ ni ògo Lẹ́bánónì máa wá,+Igi júnípà, igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì lẹ́ẹ̀kan náà,+Láti ṣe ibi mímọ́ mi lọ́ṣọ̀ọ́;Màá ṣe ibi tí ẹsẹ̀ mi wà lógo.+
14 Àwọn ọmọ àwọn tó fìyà jẹ ọ́ máa wá, wọ́n á sì tẹrí ba níwájú rẹ;Gbogbo àwọn tó ń hùwà àfojúdi sí ọ gbọ́dọ̀ tẹrí ba níbi ẹsẹ̀ rẹ,Wọ́n sì máa pè ọ́ ní ìlú Jèhófà,Síónì Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+
15 Dípò kí wọ́n pa ọ́ tì, kí wọ́n sì kórìíra rẹ, láìsí ẹni tó ń gbà ọ́ kọjá,+Màá mú kí o di ohun àmúyangàn títí láé,Orísun ayọ̀ láti ìran dé ìran.+
16 O sì máa mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,+O máa mu ọmú àwọn ọba;+Wàá sì mọ̀ dájú pé èmi Jèhófà ni Olùgbàlà rẹ,Alágbára Jékọ́bù sì ni Olùtúnrà rẹ.+
17 Dípò bàbà, màá mú wúrà wá,Dípò irin, màá mú fàdákà wáDípò igi, bàbàÀti dípò òkúta, irin;Màá fi àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ,Màá sì fi òdodo ṣe àwọn tó ń yan iṣẹ́ fún ọ.+
18 A ò ní gbúròó ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ,A ò sì ní gbúròó ìparun àti ìwópalẹ̀ nínú àwọn ààlà rẹ.+
O máa pe àwọn ògiri rẹ ní Ìgbàlà,+ o sì máa pe àwọn ẹnubodè rẹ ní Ìyìn.
19 Oòrùn ò ní jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ mọ́ ní ọ̀sán,Ìmọ́lẹ̀ òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀ fún ọ,Torí Jèhófà máa di ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,+Ọlọ́run rẹ sì máa di ẹwà rẹ.+
20 Oòrùn rẹ ò ní wọ̀ mọ́,Òṣùpá rẹ ò sì ní wọ̀ọ̀kùn,Torí pé Jèhófà máa di ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,+Àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ sì máa dópin.+
21 Gbogbo èèyàn rẹ máa jẹ́ olódodo;Ilẹ̀ náà máa di tiwọn títí láé.
Àwọn ni èéhù ohun tí mo gbìn,Iṣẹ́ ọwọ́ mi,+ ká lè ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́.+
22 Ẹni tó kéré máa di ẹgbẹ̀rún,Ẹni kékeré sì máa di orílẹ̀-èdè alágbára.
Èmi fúnra mi, Jèhófà, máa mú kó yára kánkán ní àkókò rẹ̀.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ìmọ́lẹ̀ àárọ̀ rẹ.”
^ Ní Héb., “bò ọ́.”
^ Tàbí “ilé ẹwà mi.”
^ Tàbí “àlàfo ilé ẹyẹ.”
^ Tàbí “ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́.”
^ Tàbí “ló wà bíi ti àkọ́kọ́.”
^ Tàbí “ìtẹ́wọ́gbà.”