Àìsáyà 65:1-25

  • Jèhófà máa dá àwọn abọ̀rìṣà lẹ́jọ́ (1-16)

    • Ọlọ́run Oríire àti Àyànmọ́ (11)

    • “Àwọn ìránṣẹ́ mi máa jẹun” (13)

  • Ọ̀run tuntun àti ayé tuntun (17-25)

    • A máa kọ́ ilé; a máa gbin ọgbà àjàrà (21)

    • Kò sẹ́ni tó máa ṣiṣẹ́ àṣedànù (23)

65  “Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò béèrè mi wá mi;Mo ti jẹ́ kí àwọn tí kò wá mi rí mi.+ Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi pé, ‘Èmi nìyí, èmi nìyí!’+   Mo ti tẹ́ ọwọ́ mi sí àwọn alágídí láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,+Sí àwọn tó ń rìn ní ọ̀nà tí kò dáa,+Tí wọ́n ń tẹ̀ lé èrò tiwọn;+   Àwọn èèyàn tó ń fìgbà gbogbo ṣe ohun tó ń bí mi nínú níṣojú mi, +Tí wọ́n ń rúbọ nínú àwọn ọgbà,+ tí wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn bíríkì.   Wọ́n jókòó sáàárín àwọn sàréè,+Wọ́n sì sun àwọn ibi tó pa mọ́* mọ́jú,Wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,+Omi àwọn nǹkan tó ń ríni lára* sì wà nínú àwọn ohun èlò wọn.+   Wọ́n sọ pé, ‘Dúró sí àyè rẹ; má ṣe sún mọ́ mi,Torí mo mọ́ jù ọ́ lọ.’* Èéfín ni àwọn yìí nínú ihò imú mi, iná tó ń jó láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.   Wò ó! A ti kọ ọ́ níwájú mi;Mi ò kàn ní dúró,Àmọ́ màá san wọ́n lẹ́san,+Màá san wọ́n lẹ́san ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́*   Torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn pẹ̀lú,”+ ni Jèhófà wí. “Torí pé wọ́n ti mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn òkè,Wọ́n sì ti gàn mí lórí àwọn òkè,+Màá kọ́kọ́ díwọ̀n èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”*   Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Bí ìgbà tí wọ́n rí wáìnì tuntun nínú òṣùṣù èso àjàrà,Tí ẹnì kan wá sọ pé, ‘Má bà á jẹ́, torí ohun tó dáa* wà nínú rẹ̀,’ Bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe nítorí àwọn ìránṣẹ́ mi;Mi ò ní pa gbogbo wọn run.+   Màá mú ọmọ* kan jáde látinú Jékọ́bù,Màá sì mú ẹni tó máa jogún àwọn òkè mi jáde látinú Júdà;+Àwọn àyànfẹ́ mi máa gbà á,Àwọn ìránṣẹ́ mi á sì máa gbé níbẹ̀.+ 10  Ṣárónì+ máa di ibi tí àgùntàn á ti máa jẹko,Àfonífojì* Ákórì+ sì máa di ibi ìsinmi àwọn màlúùFún àwọn èèyàn mi tó ń wá mi. 11  Àmọ́ ẹ wà lára àwọn tó ń fi Jèhófà sílẹ̀,+Àwọn tó ń gbàgbé òkè mímọ́ mi,+Àwọn tó ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run OríireÀti àwọn tó ń bu àdàlù wáìnì kún inú ife fún ọlọ́run Àyànmọ́. 12  Torí náà, màá yàn yín fún idà,+Gbogbo yín sì máa tẹrí ba kí wọ́n lè pa yín,+Torí mo pè, àmọ́ ẹ ò dáhùn,Mo sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ ò fetí sílẹ̀;+Ẹ̀ ń ṣe ohun tó burú lójú mi ṣáá,Ẹ sì yan ohun tí inú mi ò dùn sí.”+ 13  Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa jẹun, àmọ́ ebi máa pa ẹ̀yin.+ Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa mu,+ àmọ́ òùngbẹ máa gbẹ ẹ̀yin. Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa yọ̀,+ àmọ́ ojú máa ti ẹ̀yin.+ 14  Wò ó! Àwọn ìránṣẹ́ mi máa kígbe ayọ̀ torí pé ayọ̀ kún inú ọkàn,Àmọ́ ẹ̀yin máa ké jáde torí ìrora ọkàn,Ẹ sì máa pohùn réré ẹkún torí ìbànújẹ́ ọkàn. 15  Ẹ máa fi orúkọ kan sílẹ̀ tí àwọn àyànfẹ́ mi máa fi gégùn-ún,Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì máa pa yín níkọ̀ọ̀kan,Àmọ́ ó máa fi orúkọ míì pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀;+ 16  Kí Ọlọ́run òtítọ́* lè bù kúnẸnikẹ́ni tó bá ń wá ìbùkún fún ara rẹ̀ ní ayé,Kí ẹnikẹ́ni tó bá sì ń búra ní ayéLè fi Ọlọ́run òtítọ́* búra.+ Torí àwọn wàhálà* àtijọ́ máa di ohun ìgbàgbé;Wọ́n máa pa mọ́ kúrò ní ojú mi.+ 17  Torí wò ó! Mò ń dá ọ̀run tuntun àti ayé tuntun;+Àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí,Wọn ò sì ní wá sí ọkàn.+ 18  Torí náà, ẹ yọ̀, kí inú yín sì máa dùn títí láé torí ohun tí mò ń dá. Torí wò ó! Mò ń dá Jerúsálẹ́mù láti mú ayọ̀ wáÀti àwọn èèyàn rẹ̀ láti jẹ́ orísun ìdùnnú.+ 19  Inú mi máa dùn nínú Jerúsálẹ́mù, màá sì yọ̀ torí àwọn èèyàn mi;+A ò ní gbọ́ igbe ẹkún tàbí igbe ìdààmú nínú rẹ̀ mọ́.”+ 20  “Kò ní sí ọmọ ọwọ́ kankan tó máa lo ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀ mọ́,Kò sì ní sí àgbàlagbà kankan tí kò ní lo ọjọ́ rẹ̀ dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Torí pé ọmọdé lásán la máa ka ẹnikẹ́ni tó bá kú ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún sí,A sì máa gégùn-ún fún ẹlẹ́ṣẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún.* 21  Wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n sì máa gbé inú wọn,+Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, wọ́n sì máa jẹ èso wọn.+ 22  Wọn ò ní kọ́lé fún ẹlòmíì gbé,Wọn ò sì ní gbìn fún ẹlòmíì jẹ. Torí pé ọjọ́ àwọn èèyàn mi máa dà bí ọjọ́ igi,+Àwọn àyànfẹ́ mi sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 23  Wọn ò ní ṣiṣẹ́ kára* lásán,*+Wọn ò sì ní bímọ fún wàhálà,Torí àwọn ni ọmọ* tí wọ́n jẹ́ àwọn tí Jèhófà bù kún+Àti àwọn àtọmọdọ́mọ wọn pẹ̀lú wọn.+ 24  Kódà kí wọ́n tó pè, màá dáhùn;Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, màá gbọ́. 25  Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn máa jẹun pa pọ̀,Kìnnìún máa jẹ pòròpórò bí akọ màlúù,+Erùpẹ̀ sì ni ejò á máa jẹ. Wọn ò ní ṣe ìpalára kankan, wọn ò sì ní fa ìparun kankan ní gbogbo òkè mímọ́ mi,”+ ni Jèhófà wí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “àwọn ahéré ìṣọ́.”
Tàbí “aláìmọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “Torí màá kó ìjẹ́mímọ́ mi ràn ọ́.”
Ní Héb., “sínú àyà wọn.”
Ní Héb., “sínú àyà wọn.”
Ní Héb., “ìbùkún.”
Ní Héb., “èso.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “olóòótọ́.” Ní Héb., “Àmín.”
Tàbí “olóòótọ́.” Ní Héb., “Àmín.”
Tàbí “ìṣòro.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹni ègún la sì máa ka ẹni tí kò bá lò tó ọgọ́rùn-ún ọdún sí.”
Tàbí “ṣe làálàá.”
Tàbí “ṣiṣẹ́ àṣedànù.”
Ní Héb., “èso.”