Àìsáyà 48:1-22

  • Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì wí, ó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ (1-11)

  • Jèhófà máa kọ lu Bábílónì (12-16a)

  • Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ṣàǹfààní (16b-19)

  • “Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!” (20-22)

48  Gbọ́ èyí, ìwọ ilé Jékọ́bù,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Ísírẹ́lì pe ara yín +Àti ẹ̀yin tí ẹ jáde látinú omi* Júdà,Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi orúkọ Jèhófà búra,+Tí ẹ sì ń ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì,Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo.+   Torí wọ́n ń fi ìlú mímọ́+ pe ara wọn,Wọ́n sì ń wá ìtìlẹyìn Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+Tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.   “Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti sọ àwọn ohun àtijọ́* fún ọ. Wọ́n ti ẹnu mi jáde,Mo sì jẹ́ kó di mímọ̀.+ Mo gbé ìgbésẹ̀ lójijì, wọ́n sì ṣẹlẹ̀.+   Torí mo mọ bí o ṣe lágídí tó,Pé irin ni iṣan ọrùn rẹ àti pé bàbà ni iwájú orí rẹ,+   Mo sọ fún ọ tipẹ́tipẹ́. Kó tó ṣẹlẹ̀, mo mú kí o gbọ́ ọ,Kí o má bàa sọ pé, ‘Òrìṣà mi ló ṣe èyí,Ère gbígbẹ́ mi àti ère onírin* mi ló pa á láṣẹ.’   Ẹ ti gbọ́, ẹ sì ti rí gbogbo èyí. Ṣé ẹ ò ní kéde rẹ̀ ni?+ Láti ìsinsìnyí lọ, màá kéde àwọn ohun tuntun fún ọ,+Àwọn àṣírí tí mo pa mọ́, tí o kò mọ̀.   A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá wọn ni, kì í ṣe látìgbà àtijọ́,Àwọn ohun tí o ò gbọ́ rí kó tó di òní,Kí o má bàa sọ pé, ‘Wò ó! Mo ti mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.’   Rárá, o ò tíì gbọ́,+ o ò tíì mọ̀ ọ́n,Etí rẹ ò sì là nígbà àtijọ́. Nítorí mo mọ̀ pé ọ̀dàlẹ̀ paraku ni ọ́,+A sì ti pè ọ́ ní ẹlẹ́ṣẹ̀ látìgbà tí wọ́n ti bí ọ.+   Àmọ́ nítorí orúkọ mi, mi ò ní bínú mọ́;+Nítorí ìyìn mi, màá kó ara mi níjàánu lórí ọ̀rọ̀ rẹ,Mi ò sì ní pa ọ́ run.+ 10  Wò ó! Mo ti yọ́ ọ mọ́, àmọ́ kì í ṣe bíi ti fàdákà.+ Mo ti dán ọ wò* nínú iná ìléru ti ìyà, tí a fi ń yọ́ nǹkan.+ 11  Nítorí tèmi, àní nítorí tèmi, màá gbé ìgbésẹ̀,+Ṣé màá wá jẹ́ kí wọ́n kẹ́gàn mi ni?+ Èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì.* 12  Fetí sí mi, ìwọ Jékọ́bù àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti pè,Ẹnì kan náà ni mí.+ Èmi ni ẹni àkọ́kọ́; èmi náà ni ẹni ìkẹyìn.+ 13  Ọwọ́ mi ni mo fi fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,+Ọwọ́ ọ̀tún mi ni mo sì fi na ọ̀run.+ Tí mo bá pè wọ́n, wọ́n jọ máa dìde. 14  Gbogbo yín, ẹ kóra jọ, kí ẹ sì fetí sílẹ̀. Ta ni nínú wọn ló kéde àwọn nǹkan yìí? Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ Ó máa ṣe ohun tó dùn mọ́ ọn nínú sí Bábílónì,+Apá rẹ̀ sì máa kọ lu àwọn ará Kálídíà.+ 15  Èmi fúnra mi ti sọ̀rọ̀, mo sì ti pè é.+ Mo ti mú un wá, ọ̀nà rẹ̀ sì máa yọrí sí rere.+ 16  Ẹ sún mọ́ mi, kí ẹ sì gbọ́ èyí. Láti ìbẹ̀rẹ̀, mi ò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀.+ Látìgbà tó ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti wà níbẹ̀.” Ní báyìí, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti rán mi àti* ẹ̀mí rẹ̀. 17  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+ “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní,*+Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+ 18  Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni!+ Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò,+Òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.+ 19  Àwọn ọmọ* rẹ ì bá pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ ì bá sì pọ̀ bí iyanrìn.+ A ò ní pa orúkọ wọn rẹ́ tàbí ká pa á run kúrò níwájú mi láé.” 20  Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!+Ẹ sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà! Ẹ fi igbe ayọ̀ polongo rẹ̀! Ẹ kéde rẹ̀!+ Ẹ jẹ́ kó di mímọ̀ dé àwọn ìkángun ayé.+ Ẹ sọ pé: “Jèhófà ti tún Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ rà.+ 21  Òùngbẹ ò gbẹ wọ́n nígbà tó mú wọn gba àwọn ibi tó ti pa run.+ Ó mú kí omi ṣàn jáde látinú àpáta fún wọn;Ó la àpáta, ó sì mú kí omi rọ́ jáde.”+ 22  Jèhófà sọ pé, “Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “ṣẹ̀ wá láti.”
Ní Héb., “àkọ́kọ́.”
Tàbí “ère dídà.”
Tàbí “yẹ̀ ọ́ wò.” Tàbí kó jẹ́, “yàn ọ́.”
Tàbí “Èmi kì í bá ẹnì kankan pín ògo mi.”
Tàbí “pẹ̀lú.”
Tàbí “fún àǹfààní ara rẹ.”
Ní Héb., “èso.”