Àìsáyà 6:1-13

  • Ìran nípa Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ (1-4)

    • “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà” (3)

  • A wẹ ètè Àìsáyà mọ́ (5-7)

  • Àìsáyà gba iṣẹ́ (8-10)

    • “Èmi nìyí! Rán mi!” (8)

  • “Títí dìgbà wo, Jèhófà?” (11-13)

6  Ní ọdún tí Ọba Ùsáyà kú,+ mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ gíga, tó sì ta yọ,+ etí aṣọ rẹ̀ kún inú tẹ́ńpìlì.  Àwọn séráfù dúró lókè rẹ̀; ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan* fi méjì bo ojú, ó fi méjì bo ẹsẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń fi méjì fò kiri.   Ọ̀kan sì ń sọ fún èkejì pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun.+ Ògo rẹ̀ kún gbogbo ayé.”  Igbe náà* mú kí ojú ibi tí ilẹ̀kùn ti ń yí mì tìtì, èéfín sì kún ilé náà.+   Mo wá sọ pé: “Mo gbé! Mo ti kú tán,*Torí ọkùnrin tí ètè rẹ̀ kò mọ́ ni mí,Àárín àwọn èèyàn tí ètè wọn ò mọ́ ni mo sì ń gbé;+Torí ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fúnra rẹ̀!”  Ni ọ̀kan lára àwọn séráfù náà bá fò wá sọ́dọ̀ mi, ẹyin iná tó pọ́n yòò+ tó fi ẹ̀mú mú látorí pẹpẹ + sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.  Ó fi kan ẹnu mi, ó sì sọ pé: “Wò ó! Ó ti kan ètè rẹ. Ẹ̀bi rẹ ti kúrò,A sì ti ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”  Mo wá gbọ́ ohùn Jèhófà tó sọ pé: “Ta ni kí n rán, ta ló sì máa lọ fún wa?”+ Mo sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi!”+   Ó fèsì pé: “Lọ, kí o sì sọ fún àwọn èèyàn yìí pé: ‘Ẹ máa gbọ́ léraléra,Àmọ́ kò ní yé yín;Ẹ máa rí léraléra,Àmọ́ ẹ ò ní mọ nǹkan kan.’+ 10  Mú kí ọkàn àwọn èèyàn yìí yigbì,+Mú kí etí wọn di,+Kí o sì lẹ ojú wọn pọ̀,Kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran,Kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́rọ̀,Kí ọkàn wọn má bàa lóye,Kí wọ́n má bàa yí pa dà, kí wọ́n sì rí ìwòsàn.” 11  Ni mo bá sọ pé: “Títí dìgbà wo, Jèhófà?” Ó dáhùn pé: “Títí àwọn ìlú náà fi máa fọ́ túútúú, tí kò sì ní sẹ́ni tó ń gbé ibẹ̀,Tí kò ní sẹ́nì kankan nínú àwọn ilé,Títí ilẹ̀ náà fi máa pa run, tó sì máa di ahoro;+ 12  Títí Jèhófà fi máa mú àwọn èèyàn jìnnà,+Tí gbogbo ilẹ̀ náà á sì di ahoro. 13  “Àmọ́ ìdá mẹ́wàá ṣì máa wà níbẹ̀, wọ́n á sì tún dáná sun ún, bí igi ńlá àti igi ràgàjì,* tí kùkùté rẹ̀ máa ń ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí wọ́n bá gé e; irúgbìn* mímọ́ ló máa jẹ́ kùkùté rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Ó.”
Ní Héb., “Ohùn ẹni tó ń sọ̀rọ̀.”
Ní Héb., “A ti pa mí lẹ́nu mọ́.”
Tàbí “igi óákù.”
Tàbí “ọmọ.”