Àìsáyà 3:1-26

  • Àwọn olórí Júdà kó àwọn èèyàn ṣìnà (1-15)

  • A dá àwọn ọmọbìnrin Síónì oníṣekúṣe lẹ́jọ́ (16-26)

3  Wò ó! Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Ó ń mú gbogbo ìtìlẹ́yìn àtàwọn ohun tí wọ́n nílò ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà kúrò,Gbogbo ìtìlẹ́yìn oúnjẹ àti omi,+   Akíkanjú ọkùnrin àti jagunjagun,Adájọ́ àti wòlíì,+ woṣẹ́woṣẹ́ àtàwọn àgbààgbà,   Olórí àádọ́ta (50),+ èèyàn pàtàkì àti agbani-nímọ̀ràn,Onídán tó gbówọ́ àti atujú tó gbóná.+   Àwọn ọmọdékùnrin ni màá fi ṣe olórí wọn,Àwọn aláìnípinnu* ló sì máa ṣàkóso wọn.   Àwọn èèyàn náà máa fìyà jẹ ara wọn,Kálukú máa fìyà jẹ ọmọnìkejì rẹ̀.+ Ọmọdékùnrin máa lu àgbà ọkùnrin,Ẹni tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ kà sí sì máa fojú di ẹni táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún.+   Kálukú máa mú arákùnrin rẹ̀ nínú ilé bàbá rẹ̀, á sì sọ pé: “O ní aṣọ àwọ̀lékè, wá ṣe olórí wa. Jẹ́ kí àwókù ibi tí a ṣẹ́gun yìí wà níkàáwọ́ rẹ.”   Àmọ́ ó máa kọ̀ jálẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé: “Mi ò ní wẹ ọgbẹ́ rẹ;*Mi ò ní oúnjẹ tàbí aṣọ nínú ilé mi. Ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn èèyàn náà.”   Torí Jerúsálẹ́mù ti kọsẹ̀,Júdà sì ti ṣubú,Torí wọ́n ta ko Jèhófà nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn;Wọ́n ya aláìgbọràn níwájú ògo rẹ̀.*+   Ìrísí ojú wọn ta kò wọ́n,Wọ́n sì ń kéde ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sódómù;+Wọn ò fi bò rárá. Wọ́n* gbé, torí wọ́n ń mú àjálù wá sórí ara wọn! 10  Sọ fún àwọn olódodo pé nǹkan máa lọ dáadáa fún wọn;Wọ́n máa jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.*+ 11  Ẹni burúkú gbé! Àjálù máa dé bá a,Torí ohun tó fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe ni wọ́n máa ṣe fún un! 12  Ní ti àwọn èèyàn mi, àwọn tó ń kó wọn ṣiṣẹ́ ń fìyà jẹ wọ́n,Àwọn obìnrin sì ń jọba lé wọn lórí. Ẹ̀yin èèyàn mi, àwọn olórí yín ń mú kí ẹ rìn gbéregbère,Wọ́n sì ń da ọ̀nà rú mọ́ yín lójú.+ 13  Jèhófà dúró sí àyè rẹ̀ láti fẹ̀sùn kàn wọ́n;Ó dìde dúró láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn. 14  Jèhófà máa dá àwọn àgbààgbà àtàwọn olórí àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́jọ́. “Ẹ ti dáná sun ọgbà àjàrà. Ohun tí ẹ jí lọ́dọ̀ aláìní sì wà nínú àwọn ilé yín.+ 15  Kí ló kì yín láyà tí ẹ fi ń tẹ àwọn èèyàn mi rẹ́, Tí ẹ sì ń fi ojú àwọn aláìní gbolẹ̀?”+ ni Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 16  Jèhófà sọ pé: “Torí pé àwọn ọmọbìnrin Síónì ń gbéra ga,Tí wọ́n ń gbé orí wọn sókè* bí wọ́n ṣe ń rìn,Tí wọ́n ń sejú, tí wọ́n sì ń ṣakọ lọ,Wọ́n ń mú kí ẹ̀gbà ẹsẹ̀ wọn máa dún woroworo, 17  Jèhófà tún máa fi èépá kọ lu àwọn ọmọbìnrin Síónì ní orí,Jèhófà sì máa mú kí iwájú orí wọn pá.+ 18  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà ò ní mú kí àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn rẹwà mọ́,Àwọn aṣọ ìwérí àtàwọn ohun ọ̀ṣọ́ tó rí bí òṣùpá,+ 19  Àwọn yẹtí,* àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú, 20  Àwọn ìwérí, àwọn ẹ̀gbà ẹsẹ̀ àtàwọn ọ̀já ìgbàyà,*Àwọn ìgò lọ́fínńdà* àtàwọn oògùn,* 21  Àwọn òrùka ọwọ́ àti òrùka imú, 22  Àwọn aṣọ oyè, àwọn aṣọ àwọ̀lékè, àwọn aṣọ ìlékè àtàwọn àpò, 23  Àwọn dígí ọwọ́+ àtàwọn aṣọ ọ̀gbọ̀,*Àwọn láwàní àtàwọn ìbòjú. 24  Dípò òróró básámù,+ òórùn ohun tó jẹrà ló máa wà;Dípò àmùrè, okùn;Dípò irun tó rẹwà, orí pípá;+Dípò aṣọ olówó ńlá, aṣọ ọ̀fọ̀;*+Àpá tí wọ́n fi sàmì dípò ẹwà. 25  Wọ́n máa fi idà pa àwọn ọkùnrin rẹ,Àwọn akíkanjú ọkùnrin rẹ sì máa kú sójú ogun.+ 26  Àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀ máa ṣọ̀fọ̀, wọ́n á sì kẹ́dùn,+Ó sì máa jókòó sí ilẹ̀, ó máa di ahoro.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Àwọn tí èrò wọn ò dúró sójú kan.”
Tàbí “Mi ò ní wò ọ́ sàn.”
Ní Héb., “ní ojú ògo rẹ̀.”
Tàbí “Ọkàn wọn.”
Ní Héb., “Wọ́n máa jẹ èso iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”
Ní Héb., “Tí wọ́n ń na ọrùn (ọ̀fun) síwájú.”
Tàbí “ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ń so mọ́ ẹ̀gbà ọrùn.”
Tàbí “ìborùn.”
Ní Héb., “Àwọn ilé ọkàn.”
Tàbí “àwọn karawun tó ń dún tí wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́.”
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”