Àìsáyà 47:1-15

  • Ìṣubú Bábílónì (1-15)

    • Àṣírí àwọn awòràwọ̀ tú (13-15)

47  Sọ̀ kalẹ̀ wá jókòó sínú iyẹ̀pẹ̀,Ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Bábílónì.+ Jókòó sílẹ̀ níbi tí kò sí ìtẹ́,+Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà,Torí àwọn èèyàn ò tún ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ àti àkẹ́jù mọ́.   Mú ọlọ, kí o sì lọ ìyẹ̀fun. Yọ ìbòjú rẹ. Bọ́ aṣọ rẹ, ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ. Sọdá àwọn odò.   A máa tú ọ sí ìhòòhò. Ìtìjú rẹ máa hàn síta. Màá gbẹ̀san, + èèyàn kankan ò sì ní dá mi dúró.*   “Ẹni tó ń tún wa rà,Ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”   Jókòó síbẹ̀, dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì lọ sínú òkùnkùn,Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà;+Wọn ò ní pè ọ́ ní Ìyálóde* Àwọn Ìjọba mọ́.+   Inú bí mi sí àwọn èèyàn mi.+ Mo sọ ogún mi di aláìmọ́,+Mo sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+ Àmọ́ o ò ṣàánú wọn rárá.+ Kódà, o gbé àjàgà tó wúwo lé àgbàlagbà.+   O sọ pé: “Títí láé ni màá jẹ́ Ìyálóde.”*+ O ò fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn;O ò ro ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí.   Wá gbọ́ èyí, ìwọ ẹni tó fẹ́ràn fàájì,+Tó jókòó láìséwu, tó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé: “Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.+ Mi ò ní di opó. Mi ò ní ṣòfò ọmọ láé.”+   Àmọ́ nǹkan méjèèjì yìí máa dé bá ọ lójijì, lọ́jọ́ kan ṣoṣo:+ Wàá ṣòfò ọmọ, wàá sì di opó. Wọ́n máa dé bá ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,+Torí* ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ àti gbogbo èèdì rẹ tó lágbára.+ 10  O gbẹ́kẹ̀ lé ìwà burúkú rẹ. O sọ pé: “Kò sẹ́ni tó ń rí mi.” Ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ ló kó ọ ṣìnà,O sì ń sọ lọ́kàn rẹ pé: “Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.” 11  Àmọ́ àjálù máa dé bá ọ,Ìkankan nínú àwọn oògùn rẹ ò sì ní dá a dúró.* O máa ko àgbákò; o ò ní lè yẹ̀ ẹ́. Ìparun òjijì máa dé bá ọ, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ sí ọ rí.+ 12  Máa fi èèdì di àwọn èèyàn lọ, kí o sì máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ,+Èyí tí o ti ń ṣe kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ. Bóyá wàá lè jàǹfààní;Bóyá wàá lè mú kí ẹ̀rù ba àwọn èèyàn. 13  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ ti tán ọ lókun. Kí wọ́n dìde báyìí, kí wọ́n sì gbà ọ́ là,Àwọn tó ń jọ́sìn ọ̀run,* tí wọ́n ń wo ìràwọ̀,+Àwọn tó ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun,Nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ. 14  Wò ó! Wọ́n dà bí àgékù pòròpórò. Iná máa jó wọn run. Wọn ò lè gba ara* wọn lọ́wọ́ agbára ọwọ́ iná. Àwọn èédú yìí kì í ṣe èyí tí a lè fi yáná,Iná yìí kì í sì í ṣe èyí tí a lè jókòó síwájú rẹ̀. 15  Bẹ́ẹ̀ ni àwọn atujú rẹ máa rí sí ọ,Àwọn tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ. Wọ́n máa rìn gbéregbère, kálukú ní ọ̀nà tirẹ̀.* Kò ní sí ẹni tó máa gbà ọ́ là.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “mi ò sì ní ṣàánú ẹnikẹ́ni.”
Tàbí “Ọbabìnrin.”
Tàbí “Ọbabìnrin.”
Tàbí kó jẹ́, “Láìka.”
Tàbí “O ò sì ní lè sa oògùn sí i.”
Tàbí kó jẹ́, “Àwọn tó ń pín ọ̀run; Àwọn awòràwọ̀.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “kálukú lọ sí agbègbè rẹ̀.”