Àìsáyà 5:1-30

  • Orin nípa ọgbà àjàrà Jèhófà (1-7)

  • Ó mà ṣe fún ọgbà àjàrà Jèhófà o (8-24)

  • Ọlọ́run bínú sí àwọn èèyàn rẹ̀ (25-30)

5  Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn,Orin tó dá lórí ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́ àti ọgbà àjàrà rẹ̀.+ Ẹni tí mo fẹ́ràn ní ọgbà àjàrà kan síbi òkè tó lọ́ràá.   Ó gbẹ́ ibẹ̀, ó sì kó àwọn òkúta ibẹ̀ kúrò. Ó gbin àjàrà pupa tó dáa sínú rẹ̀,Ó kọ́ ilé gogoro sí àárín rẹ̀,Ó sì gbẹ́ ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì sínú rẹ̀.+ Ó wá ń retí pé kí àjàrà náà so,Àmọ́ èso àjàrà igbó nìkan ló mú jáde. +   “Ní báyìí, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerúsálẹ́mù àti ẹ̀yin èèyàn Júdà,Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣèdájọ́ láàárín èmi àti ọgbà àjàrà mi.+   Kí ló tún yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà miTí mi ò tíì ṣe?+ Nígbà tí mo retí pé kó so èso àjàrà,Kí ló dé tó jẹ́ àjàrà igbó nìkan ló ń mú jáde?   Ó yá, ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín,Ohun tí màá ṣe sí ọgbà àjàrà mi: Màá mú ọgbà tó yí i ká kúrò,Màá sì dáná sun ún.+ Màá fọ́ ògiri olókùúta rẹ̀,Wọ́n sì máa tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀.   Màá sọ ọ́ di ahoro;+Wọn ò ní rẹ́wọ́ rẹ̀, wọn ò sì ní ro ó. Igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò ló máa kún ibẹ̀,+Màá sì pàṣẹ fún àwọsánmà* pé kó má rọ òjò kankan sórí rẹ̀.+   Torí pé ilé Ísírẹ́lì ni ọgbà àjàrà Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun;+Àwọn èèyàn Júdà sì ni oko* tó fẹ́ràn. Ó ń retí ìdájọ́ òdodo,+Àmọ́ wò ó! ìrẹ́jẹ ló wà;Ó ń retí òdodo,Àmọ́ wò ó! igbe ìdààmú ló wà.”+   Àwọn tó ń ní ilé kún ilé gbé +Àti àwọn tí wọ́n ń ní ilẹ̀ kún ilẹ̀,+Títí kò fi sí àyè mọ́,Tó sì wá ku ẹ̀yin nìkan lórí ilẹ̀ náà!   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti búra ní etí mi,Pé ọ̀pọ̀ ilé, bí wọ́n tiẹ̀ tóbi, tí wọ́n sì rẹwà,Wọ́n máa di ohun àríbẹ̀rù,Láìsí olùgbé kankan.+ 10  Torí pé òṣùwọ̀n báàtì* kan ṣoṣo ni éékà ilẹ̀ mẹ́wàá* tí wọ́n gbin àjàrà sí máa mú jáde,Eéfà* kan ṣoṣo sì ni irúgbìn tó jẹ́ òṣùwọ̀n hómérì* kan máa mú jáde.+ 11  Àwọn tó ń dìde mu ọtí láàárọ̀ kùtù gbé,+Tí wọ́n ń dúró síbẹ̀ dìgbà tílẹ̀ ṣú títí ọtí fi ń pa wọ́n! 12  Wọ́n ní háàpù àti ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín,Ìlù tanboríìnì, fèrè àti wáìnì sì wà níbi àsè wọn;Àmọ́ wọn ò ronú nípa iṣẹ́ Jèhófà,Wọn ò sì rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. 13  Torí náà, àwọn èèyàn mi máa lọ sí ìgbèkùn,Torí wọn ò ní ìmọ̀;+Ebi máa pa àwọn èèyàn wọn tó lọ́lá,+Òùngbẹ sì máa gbẹ gbogbo èèyàn wọn gidigidi. 14  Torí náà, Isà Òkú* ti fẹ ara* rẹ̀ sí i,Ó sì ti la ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu láìní ààlà;+Ó dájú pé iyì rẹ̀,* ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ń pariwo àtàwọn èèyàn rẹ̀ tó ń ṣe àríyá aláriwoMáa sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú rẹ̀. 15  Èèyàn sì máa tẹrí ba,A máa rẹ èèyàn sílẹ̀,A sì máa rẹ ojú àwọn agbéraga wálẹ̀. 16  Ìdájọ́* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa gbé e ga,Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni Mímọ́,+ máa fi òdodo+ sọ ara rẹ̀ di mímọ́. 17  Àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn sì máa jẹko bíi pé ibi ìjẹko wọn ni;Àwọn àjèjì máa jẹun níbi tó ti dahoro táwọn ẹran tí wọ́n bọ́ dáadáa ti jẹun. 18  Àwọn tó ń fi okùn ẹ̀tàn fa ẹ̀bi wọn lọ gbé,Tí wọ́n sì ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹṣin fa ẹ̀ṣẹ̀ wọn; 19  Àwọn tó ń sọ pé: “Kó jẹ́ kí iṣẹ́ Rẹ̀ yára kánkán;Kó tètè dé, ká lè rí i. Kí ohun tí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ní lọ́kàn* ṣẹ,Ká lè mọ̀ ọ́n!”+ 20  Àwọn tó ń sọ pé ohun tó dára burú àti pé ohun tó burú dára gbé,+Àwọn tó ń fi òkùnkùn dípò ìmọ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń fi ìmọ́lẹ̀ dípò òkùnkùn,Àwọn tó ń fi ìkorò dípò adùn àti adùn dípò ìkorò! 21  Àwọn tó gbọ́n lójú ara wọn gbé,Tí wọ́n jẹ́ olóye lójú ara wọn!+ 22  Àwọn akọni nídìí ọtí mímu gbéÀti àwọn tó mọ àdàlù ọtí ṣe dáadáa,+ 23  Àwọn tó dá ẹni burúkú láre torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+Tí wọn ò sì jẹ́ kí olódodo rí ìdájọ́ òdodo gbà!+ 24  Torí náà, bí ahọ́n iná ṣe máa ń jó àgékù pòròpórò run,Tí koríko gbígbẹ sì máa ń rún sínú ọwọ́ iná,Gbòǹgbò wọn gangan máa jẹra,Ìtànná wọn sì máa fọ́n ká bí eruku,Torí pé wọ́n kọ òfin* Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Wọn ò sì ka ọ̀rọ̀ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sí.+ 25  Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi bínú gidigidi sí àwọn èèyàn rẹ̀,Ó sì máa na ọwọ́ rẹ̀ lòdì sí wọn, ó máa lù wọ́n.+ Àwọn òkè máa mì tìtì,Òkú wọn sì máa dà bí ààtàn lójú ọ̀nà.+ Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí pa dà,Àmọ́ ó ṣì na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lù wọ́n. 26  Ó ti gbé àmì sókè* sí orílẹ̀-èdè tó wà lọ́nà jíjìn;+Ó ti súfèé sí wọn pé kí wọ́n wá láti àwọn ìkángun ayé;+Sì wò ó! wọ́n ń yára bọ̀.+ 27  Kò rẹ ẹnì kankan nínú wọn, wọn ò sì kọsẹ̀. Ìkankan nínú wọn ò tòògbé, wọn ò sì sùn. Àmùrè tó wà ní ìbàdí wọn ò tú,Okùn bàtà wọn ò sì já. 28  Gbogbo ọfà wọn mú,Wọ́n sì ti fa gbogbo ọrun wọn.* Pátákò àwọn ẹṣin wọn dà bí akọ òkúta, Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dà bí ìjì.+ 29  Wọ́n ń ké ramúramù bíi kìnnìún;Wọ́n ń ké ramúramù bí àwọn ọmọ kìnnìún.*+ Wọ́n máa kùn, wọ́n sì máa mú ẹran,Wọ́n á gbé e lọ, kò sì ní sẹ́ni tó máa gbà á lọ́wọ́ wọn. 30  Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa kùn lórí rẹ̀,Bí òkun ṣe ń ru.+ Òkùnkùn tó ń kó ìdààmú báni ni ẹnikẹ́ni tó bá tẹjú mọ́ ilẹ̀ náà máa rí;Ìmọ́lẹ̀ pàápàá ti ṣókùnkùn nítorí ìkùukùu.*+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “ohun ọ̀gbìn.”
Ìyẹn, ilẹ̀ tí 20 màlúù tí wọ́n so pọ̀ ní méjì-méjì lè túlẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kan.
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “àwọn èèyàn rẹ̀ pàtàkì.”
Tàbí “Ìdájọ́ òdodo.”
Tàbí “ìpinnu (ìmọ̀ràn) Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”
Tàbí “ìtọ́ni.”
Tàbí “gbé òpó sókè láti ṣe àmì.”
Tàbí “Wọ́n sì ti fẹ́ tafà.”
Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”
Tàbí “àwọsánmà.”