Àìsáyà 46:1-13
46 Bélì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀,+ Nébò tẹ̀ ba síwájú.
Wọ́n kó àwọn òrìṣà wọn sẹ́yìn àwọn ẹranko, sẹ́yìn àwọn ẹran akẹ́rù,+Bí ẹrù tó ń ni àwọn ẹranko tó ti rẹ̀ lára.
2 Wọ́n jọ tẹ̀ ba, wọ́n sì jọ bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;Wọn ò lè gba àwọn ẹrù* náà sílẹ̀,Àwọn fúnra wọn* sì lọ sí ìgbèkùn.
3 “Fetí sí mi, ìwọ ilé Jékọ́bù àti gbogbo ẹ̀yin tó ṣẹ́ kù ní ilé Ísírẹ́lì,+Ẹ̀yin tí mò ń tì lẹ́yìn látìgbà tí a ti bí yín, tí mo sì gbé látinú oyún.+
4 Títí o fi máa dàgbà, mi ò ní yí pa dà;+Títí irun rẹ fi máa funfun, mi ò ní yéé gbé ọ.
Bí mo ti ń ṣe, màá gbé ọ, màá rù ọ́, màá sì gbà ọ́ sílẹ̀.+
5 Ta lẹ lè fi mí wé, tí ẹ lè mú bá mi dọ́gba tàbí tí ẹ lè fi díwọ̀n mi,+Tí a máa wá rí bákan náà?+
6 Àwọn kan wà tó ń kó wúrà jáde yàlàyòlò látinú àpò wọn;Wọ́n ń wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n.
Wọ́n gba oníṣẹ́ irin síṣẹ́, ó sì fi ṣe ọlọ́run.+
Wọ́n wá wólẹ̀, àní, wọ́n jọ́sìn rẹ̀.*+
7 Wọ́n gbé e sí èjìká wọn,+Wọ́n gbé e, wọ́n sì fi sí àyè rẹ̀, ṣe ló kàn dúró síbẹ̀.
Kì í kúrò ní àyè rẹ̀.+
Wọ́n ké sí i, àmọ́ kò dáhùn;Kò lè gba ẹnikẹ́ni nínú wàhálà.+
8 Ẹ rántí èyí, kí ẹ sì mọ́kàn le.
Ẹ fi sọ́kàn, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀.
9 Ẹ rántí àwọn nǹkan àtijọ́* tó ti wà tipẹ́,Pé èmi ni Ọlọ́run,* kò sí ẹlòmíì,Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹni tó dà bí èmi.+
10 Láti ìbẹ̀rẹ̀, mò ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀,Tipẹ́tipẹ́ ni mo sì ti ń sọ àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀.+
Mo sọ pé, ‘Ìpinnu mi* máa dúró,+Màá sì ṣe ohunkóhun tó bá wù mí.’+
11 Màá pe ẹyẹ aṣọdẹ wá láti ibi tí oòrùn ti ń yọ,*+Ọkùnrin tó máa ṣe ohun tí mo pinnu*+ máa wá láti ilẹ̀ tó jìn.
Mo ti sọ̀rọ̀, màá sì mú kó ṣẹ.
Mo ti ní in lọ́kàn, màá sì ṣe é.+
12 Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọlọ́kàn líle,*Ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré sí òdodo.
13 Mo ti mú òdodo mi sún mọ́ tòsí;Kò jìnnà réré,Ìgbàlà mi ò sì ní falẹ̀.+
Màá mú kí wọ́n rí ìgbàlà ní Síónì, ẹwà mi sì máa wà ní Ísírẹ́lì.”+

