Àìsáyà 13:1-22
13 Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Bábílónì,+ tí Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nínú ìran:
2 “Ẹ gbé àmì kan*+ sókè lórí òkè tó jẹ́ kìkì àpáta.
Ẹ ké pè wọ́n, ẹ ju ọwọ́,Kí wọ́n lè wá sí ẹnu ọ̀nà àwọn èèyàn pàtàkì.
3 Mo ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yàn.*+
Mo ti ké sí àwọn jagunjagun mi pé kí wọ́n fi ìbínú mi hàn,Àwọn èèyàn mi tó ń yangàn, tí wọ́n sì ń yọ̀.
4 Fetí sílẹ̀! Ọ̀pọ̀ èèyàn wà lórí òkè;Ìró wọn dà bí ìró ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn!
Fetí sílẹ̀! Ariwo àwọn ìjọba,Ti àwọn orílẹ̀-èdè tó kóra jọ!+
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ń pe àwọn ọmọ ogun jọ.+
5 Wọ́n ń bọ̀ láti ilẹ̀ tó jìnnà,+Láti ìkángun ọ̀run,Jèhófà àti àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,Láti pa gbogbo ayé run.+
6 Ẹ pohùn réré ẹkún, torí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé!
Ó máa jẹ́ ọjọ́ ìparun látọ̀dọ̀ Olódùmarè.+
7 Ìdí nìyẹn tí gbogbo ọwọ́ fi máa rọ,Tí ìbẹ̀rù sì máa mú kí ọkàn gbogbo èèyàn domi.+
8 Jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn náà.+
Iṣan wọn sún kì, wọ́n sì ń jẹ̀rora,Bí obìnrin tó ń rọbí.
Wọ́n ń wo ara wọn tìbẹ̀rù-tìbẹ̀rù,Ìrora sì hàn lójú wọn.
9 Wò ó! Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀,Ọjọ́ tó lágbára pẹ̀lú ìbínú tó le àti ìbínú tó ń jó fòfò,Láti sọ ilẹ̀ náà di ohun àríbẹ̀rù,+Kó sì pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà run kúrò lórí rẹ̀.
10 Torí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti àwọn àgbájọ ìràwọ̀ wọn*+Kò ní tan ìmọ́lẹ̀ wọn jáde;Oòrùn máa ṣókùnkùn tó bá ràn,Òṣùpá ò sì ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.
11 Màá pe àwọn tó ń gbé ayé lẹ́jọ́ torí ìwà burúkú wọn,+Màá sì pe àwọn ẹni burúkú lẹ́jọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Màá fòpin sí ìyangàn àwọn agbéraga,Màá sì rẹ ìgbéraga àwọn oníwà ìkà wálẹ̀.+
12 Màá mú kí ẹni kíkú ṣọ̀wọ́n ju wúrà tí wọ́n yọ́ mọ́,+Màá sì mú kí àwọn èèyàn ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ófírì.+
13 Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí ọ̀run gbọ̀n rìrì,Ayé sì máa mì jìgìjìgì kúrò ní àyè rẹ̀+Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun bá bínú gidigidi ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀ tó ń jó bí iná.
14 Bí egbin tí wọ́n ń dọdẹ àti bí agbo ẹran tí kò sí ẹnikẹ́ni tó máa kó wọn jọ,Kálukú máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀;Kálukú sì máa sá lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.+
15 Wọ́n máa gún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí ní àgúnyọ,Wọ́n sì máa fi idà pa ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú.+
16 Wọ́n máa já àwọn ọmọ wọn sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,+Wọ́n máa kó ẹrù ilé wọn,Wọ́n sì máa fipá bá àwọn ìyàwó wọn lò pọ̀.
17 Màá gbé àwọn ará Mídíà dìde sí wọn,+Àwọn tí kò ka fàdákà sí nǹkan kan,Tí wúrà ò sì já mọ́ nǹkan kan lójú wọn.
18 Ọfà wọn máa run àwọn ọ̀dọ́kùnrin túútúú;+Wọn ò ní káàánú èso ikùn,Wọn ò sì ní ṣàánú àwọn ọmọdé.
19 Bábílónì tó lógo* jù nínú àwọn ìjọba,+Ẹwà àti ògo àwọn ará Kálídíà,+Máa dà bíi Sódómù àti Gòmórà nígbà tí Ọlọ́run bì wọ́n ṣubú.+
20 Ẹnikẹ́ni ò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ láé,Kò sì sẹ́ni tó máa gbé ibẹ̀ láti ìran dé ìran.+
Ará Arébíà kankan ò ní pàgọ́ síbẹ̀,Olùṣọ́ àgùntàn kankan ò sì ní jẹ́ kí agbo ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
21 Àwọn ẹranko inú aṣálẹ̀ máa dùbúlẹ̀ síbẹ̀;Àwọn ẹyẹ òwìwí máa kún ilé wọn.
Àwọn ògòǹgò á máa gbé ibẹ̀,+Àwọn ewúrẹ́ igbó* á máa tọ kiri níbẹ̀.
22 Àwọn ẹranko tó ń hu á máa ké nínú àwọn ilé gogoro rẹ̀Àti àwọn ajáko* nínú àwọn ààfin rẹ̀ tó lọ́lá.
Àkókò rẹ̀ ti sún mọ́lé, a ò sì ní fi kún àwọn ọjọ́ rẹ̀.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “òpó kan láti fi ṣe àmì.”
^ Ní Héb., “tí mo sọ di mímọ́.”
^ Ní Héb., “àti àwọn Késílì wọn,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Óríónì àtàwọn àgbájọ ìràwọ̀ tó yí i ká ló ń tọ́ka sí.
^ Tàbí “lọ́ṣọ̀ọ́.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́.”
^ Tàbí “akátá.”