Àìsáyà 43:1-28

  • Jèhófà pa dà kó àwọn èèyàn rẹ̀ jọ (1-7)

  • Kí àwọn ọlọ́run gbèjà ara wọn (8-13)

    • “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi” (10, 12)

  • Wọ́n máa tú wọn sílẹ̀ láti Bábílónì (14-21)

  • “Jẹ́ ká gbé ẹjọ́ wa wá” (22-28)

43  Ohun tí Jèhófà wá sọ nìyí,Ẹlẹ́dàá rẹ, ìwọ Jékọ́bù, Ẹni tó dá ọ, ìwọ Ísírẹ́lì:+ “Má bẹ̀rù, torí mo ti tún ọ rà.+ Mo ti fi orúkọ rẹ pè ọ́. Tèmi ni ọ́.   Tí o bá gba inú omi kọjá, màá wà pẹ̀lú rẹ,+Tí o bá sì gba inú odò kọjá, kò ní kún bò ọ́.+ Tí o bá rin inú iná kọjá, kò ní jó ọ,Ọwọ́ iná ò sì ní rà ọ́.   Torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, Olùgbàlà rẹ. Mo ti fi Íjíbítì ṣe ìràpadà fún ọ,Mo sì ti fi Etiópíà àti Sébà dípò rẹ.   Torí o ti wá ṣeyebíye ní ojú mi,+A dá ọ lọ́lá, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ.+ Torí náà, màá fi àwọn èèyàn rọ́pò rẹ,Màá sì fi àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí* rẹ.    Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+ Màá mú ọmọ* rẹ wá láti ìlà oòrùn,Màá sì kó ọ jọ láti ìwọ̀ oòrùn.+   Màá sọ fún àríwá pé, ‘Dá wọn sílẹ̀!’+ Màá sì sọ fún gúúsù pé, ‘Má ṣe dá wọn dúró. Mú àwọn ọmọkùnrin mi wá láti ọ̀nà jíjìn àti àwọn ọmọbìnrin mi láti àwọn ìkángun ayé,+   Gbogbo ẹni tí wọ́n ń fi orúkọ mi pè,+Tí mo sì dá fún ògo mi,Tí mo ṣẹ̀dá, tí mo sì ṣe.’+   Mú àwọn èèyàn tó fọ́jú jáde, bí wọ́n tiẹ̀ ní ojú,Àwọn tó jẹ́ adití, bí wọ́n tiẹ̀ ní etí.+   Kí gbogbo orílẹ̀-èdè pé jọ síbì kan,Kí àwọn èèyàn sì kóra jọ.+ Èwo nínú wọn ló lè sọ èyí? Àbí wọ́n lè mú ká gbọ́ àwọn ohun àkọ́kọ́?*+ Kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wá, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn jàre,Tàbí kí wọ́n gbọ́, kí wọ́n sì sọ pé, ‘Òótọ́ ni!’”+ 10  “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,”+ ni Jèhófà wí,“Àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn,+Kí ẹ lè mọ̀, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi,*Kó sì yé yín pé Ẹnì kan náà ni mí.+ Ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run tí a dá,Lẹ́yìn mi, kò sí ìkankan.+ 11  Èmi, àní èmi ni Jèhófà,+ kò sí olùgbàlà kankan yàtọ̀ sí mi.”+ 12  “Èmi ni Ẹni tó kéde, tó gbani là, tó sì mú kó di mímọ̀,Nígbà tí kò sí ọlọ́run àjèjì kankan láàárín yín.+ Torí náà, ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Jèhófà wí, “èmi sì ni Ọlọ́run.+ 13  Bákan náà, Ẹnì kan náà ni mí+ nígbà gbogbo;Kò sì sí ẹni tó lè já ohunkóhun gbà kúrò lọ́wọ́ mi.+ Tí mo bá ń ṣe nǹkan kan, ta ló lè dá mi dúró?”+ 14  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, Olùtúnrà yín,+ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì:+ “Nítorí yín, màá ránṣẹ́ sí Bábílónì, màá sì gé gbogbo ọ̀pá ìdábùú ẹnubodè lulẹ̀,+Àwọn ará Kálídíà sì máa ké jáde nínú ìdààmú, nínú àwọn ọkọ̀ òkun wọn.+ 15  Èmi ni Jèhófà, Ẹni Mímọ́ yín,+ Ẹlẹ́dàá Ísírẹ́lì+ àti Ọba yín.”+ 16  Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,Ẹni tó ń la ọ̀nà gba inú òkun,Tó sì ń la ọ̀nà gba inú omi tó ń ru gùdù,+ 17  Ẹni tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹṣin jáde,+Àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn jagunjagun tó lákíkanjú: “Wọ́n máa dùbúlẹ̀, wọn ò sì ní dìde.+ A máa fẹ́ wọn pa, a máa pa wọ́n bí òwú àtùpà tó ń jó.” 18  “Ẹ má ṣe rántí àwọn ohun àtijọ́,Ẹ má sì máa ronú nípa ohun tó ti kọjá. 19  Ẹ wò ó! Mò ń ṣe ohun tuntun;+Kódà, ní báyìí, ó ti ń rú yọ. Ṣé ẹ ò mọ̀ ọ́n ni? Màá la ọ̀nà kan gba inú aginjù,+Màá sì mú kí odò gba inú aṣálẹ̀.+ 20  Ẹran igbó máa bọlá fún mi,Àwọn ajáko* àti ògòǹgò,Torí mo pèsè omi ní aginjù,Odò ní aṣálẹ̀,+Fún àwọn èèyàn mi, àwọn àyànfẹ́ mi,+ kí wọ́n lè mu, 21  Àwọn èèyàn tí mo dá fún ara mi,Kí wọ́n lè kéde ìyìn mi.+ 22  Àmọ́ o ò ké pè mí, ìwọ Jékọ́bù,+Torí ọ̀rọ̀ mi ti sú ọ, ìwọ Ísírẹ́lì.+ 23  O ò mú àgùntàn wá fún mi láti fi rú àwọn odindi ẹbọ sísun rẹ,O ò sì fi àwọn ẹbọ rẹ yìn mí lógo. Mi ò fi dandan mú ọ pé kí o mú ẹ̀bùn wá fún mi,Mi ò sì fi oje igi tùràrí tí mo ní kí o mú wá dá ọ lágara.+ 24  O ò fi owó rẹ ra pòròpórò olóòórùn dídùn* fún mi,O ò sì fi ọ̀rá àwọn ẹbọ rẹ tẹ́ mi lọ́rùn.+ Dípò ìyẹn, ṣe lo fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ di ẹrù wọ̀ mí lọ́rùn,O sì fi àwọn àṣìṣe rẹ tán mi lókun.+ 25  Èmi, àní èmi ni Ẹni tó ń nu àwọn àṣìṣe* rẹ+ kúrò nítorí tèmi,+Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.+ 26  Rán mi létí; jẹ́ ká gbé ẹjọ́ wa wá;Ro ẹjọ́ rẹ, kí o lè fi hàn pé o jàre. 27  Baba ńlá rẹ àkọ́kọ́ ṣẹ̀,Àwọn agbẹnusọ* rẹ sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ 28  Torí náà, màá sọ àwọn ìjòyè ibi mímọ́ di aláìmọ́,Màá mú kí wọ́n pa Jékọ́bù run,Màá sì mú kí wọ́n sọ̀rọ̀ èébú sí Ísírẹ́lì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “èso.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ohun tó máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Tàbí “gbẹ́kẹ̀ lé mi.”
Tàbí “akátá.”
Esùsú tó ń ta sánsán.
Tàbí “ìwà ọ̀tẹ̀.”
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn olùkọ́ Òfin ló ń tọ́ka sí.