Àìsáyà 59:1-21

  • Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì mú kí wọ́n jìnnà sí Ọlọ́run (1-8)

  • Wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ (9-15a)

  • Jèhófà dá sí i torí àwọn tó ronú pìwà dà (15b-21)

59  Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù láti gbani là,+Bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò di* tí kò fi lè gbọ́.+  2  Rárá, àwọn àṣìṣe yín ti pín ẹ̀yin àti Ọlọ́run yín níyà.+ Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ti mú kó fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún yín,Ó sì kọ̀ láti gbọ́ yín.+  3  Torí ẹ̀jẹ̀ ti sọ àtẹ́lẹwọ́ yín di eléèérí,+Ẹ̀ṣẹ̀ sì ti sọ ìka yín di eléèérí. Ètè yín ń parọ́,+ ahọ́n yín sì ń sọ àìṣòdodo kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.  4  Kò sí ẹni tó ń wá òdodo,+Kò sí ẹni tó ń fi òótọ́ inú lọ sí ilé ẹjọ́. Ohun tí kò sí rárá* ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé,+ wọ́n sì ń sọ ohun tí kò ní láárí. Wọ́n lóyún wàhálà, wọ́n sì bí ohun tó ń pani lára.+  5  Wọ́n pa ẹyin ejò olóró,Wọ́n sì hun òwú aláǹtakùn.+ Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹyin wọn máa kú,Ẹyin tí wọ́n sì tẹ̀ fọ́ mú ejò paramọ́lẹ̀ jáde.  6  Òwú aláǹtakùn wọn ò ní dà bí aṣọ,Wọn ò sì ní fi ohun tí wọ́n ṣe bo ara wọn.+ Iṣẹ́ wọn léwu,Ìwà ipá ló sì kún ọwọ́ wọn.+  7  Ẹsẹ̀ wọn ń sáré láti hùwà burúkú,Wọ́n sì ń yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.+ Ohun burúkú ni wọ́n ń rò;Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn.+  8  Wọn ò mọ ọ̀nà àlàáfíà,Kò sí ìdájọ́ òdodo ní àwọn ipa ọ̀nà wọn.+ Wọ́n mú kí àwọn ọ̀nà wọn wọ́;Ìkankan nínú àwọn tó ń rìn níbẹ̀ kò ní mọ àlàáfíà.+  9  Ìdí nìyẹn tí ìdájọ́ òdodo fi jìnnà sí wa,Tí òdodo kò sì lé wa bá. À ń retí ìmọ́lẹ̀ ṣáá, àmọ́ wò ó! òkùnkùn ló ṣú;À ń retí ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò, àmọ́ a ò yéé rìn nínú ìṣúdùdù.+ 10  À ń táràrà níbi ògiri bí afọ́jú;À ń táràrà bí àwọn tí kò ní ojú.+ A kọsẹ̀ ní ọ̀sán gangan bíi pé a wà nínú òkùnkùn alẹ́;Ṣe la dà bí òkú láàárín àwọn alágbára. 11  Gbogbo wa ń kùn ṣáá bíi bíárì,A sì ń ṣọ̀fọ̀, à ń ké kúùkúù bí àdàbà. À ń retí ìdájọ́ òdodo, àmọ́ kò sí;À ń retí ìgbàlà, àmọ́ ó jìnnà gan-an sí wa. 12  Torí ọ̀tẹ̀ wa pọ̀ níwájú rẹ;+Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ń ta kò wá níkọ̀ọ̀kan.+ Torí àwọn ọ̀tẹ̀ wa wà pẹ̀lú wa;A mọ àwọn àṣìṣe wa dáadáa.+ 13  A ti ṣẹ̀, a sì ti sẹ́ Jèhófà;A ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run wa,A ti sọ̀rọ̀ nípa ìnilára àti ọ̀tẹ̀;+A ti lóyún irọ́, a sì ti sọ̀rọ̀ èké kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ látinú ọkàn.+ 14  Wọ́n ti rọ́ ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,+Òdodo sì dúró sí ọ̀nà jíjìn;+Nítorí pé òtítọ́* ti kọsẹ̀ ní ojúde ìlú,Ohun tó tọ́ kò sì rí ọ̀nà wọlé. 15  Òtítọ́* ti pòórá,+Ẹnikẹ́ni tó bá sì yí pa dà kúrò nínú ohun tó burú ni wọ́n ń kó lẹ́rù. Jèhófà rí i, inú rẹ̀ ò sì dùn*Torí kò sí ìdájọ́ òdodo.+ 16  Ó rí i pé kò sí èèyàn kankan,Ó sì yà á lẹ́nu pé ẹnì kankan ò bá wọn bẹ̀bẹ̀,Torí náà, apá rẹ̀ mú ìgbàlà wá,*Òdodo rẹ̀ sì tì í lẹ́yìn. 17  Ó wá gbé òdodo wọ̀ bí ẹ̀wù irin,Ó sì dé akoto ìgbàlà* sí orí rẹ̀.+ Ó wọ ẹ̀wù ẹ̀san bí aṣọ,+Ó sì fi ìtara bo ara rẹ̀ bí aṣọ àwọ̀lékè.* 18  Ó máa san wọ́n lẹ́san ohun tí wọ́n ṣe:+ Ó máa bínú sí àwọn elénìní rẹ̀, ó máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀.+ Ó sì máa san ohun tó yẹ àwọn erékùṣù fún wọn. 19  Wọ́n máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà láti ìwọ̀ oòrùnÀti ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn,Torí ó máa wọlé wá bí odò tó ń yára ṣàn,Tí ẹ̀mí Jèhófà ń gbé lọ. 20  “Olùtúnrà+ máa wá sí Síónì,+Sọ́dọ̀ àwọn ti Jékọ́bù, àwọn tó yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,”+ ni Jèhófà wí. 21  “Ní tèmi, májẹ̀mú tí mo bá wọn dá nìyí,”+ ni Jèhófà wí. “Ẹ̀mí mi tó wà lára rẹ àti àwọn ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí ẹnu rẹ kò ní kúrò ní ẹnu rẹ, ní ẹnu àwọn ọmọ* rẹ tàbí ní ẹnu àwọn ọmọ ọmọ rẹ,”* ni Jèhófà wí, “láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

^ Ní Héb., “wúwo.”
^ Tàbí “Òfìfo.”
^ Tàbí “ìṣòtítọ́.”
^ Tàbí “Ìṣòtítọ́.”
^ Ní Héb., “ó sì burú ní ojú rẹ̀.”
^ Tàbí “mú kó ṣẹ́gun.”
^ Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”
^ Tàbí “ìṣẹ́gun.”
^ Ní Héb., “èso.”
^ Ní Héb., “èso àwọn èso rẹ.”