Àìsáyà 1:1-31
1 Ìran tí Àìsáyà*+ ọmọ Émọ́ọ̀sì rí nípa Júdà àti Jerúsálẹ́mù láyé ìgbà Ùsáyà,+ Jótámù,+ Áhásì+ àti Hẹsikáyà,+ àwọn ọba Júdà:+
2 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọ̀run, sì fetí sílẹ̀, ìwọ ayé,+Torí Jèhófà ti sọ pé:
“Mo ti tọ́ àwọn ọmọ,+ mo sì ti tọ́jú wọn dàgbà,
Àmọ́ wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+
3 Akọ màlúù mọ ẹni tó ra òun dunjú,Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ ẹran olówó rẹ̀;Àmọ́ Ísírẹ́lì ò mọ̀ mí,*+Àwọn èèyàn mi ò fi òye hùwà.”
4 O gbé! Ìwọ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,+Àwọn èèyàn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀ lọ́rùn,Ìran àwọn èèyàn burúkú, àwọn ọmọ oníwà ìbàjẹ́!
Wọ́n ti fi Jèhófà sílẹ̀;+Wọ́n ti hùwà àfojúdi sí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì;Wọ́n ti kẹ̀yìn sí i.
5 Ibo la tún lè lù lára yín nígbà tí ẹ kò jáwọ́ nínú ìwà ọ̀tẹ̀ yín?+
Gbogbo orí yín ló ń ṣàìsànÀrùn sì ti kọ lu gbogbo ọkàn yín.+
6 Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí, kò sí ibi tó gbádùn.
Ara yín bó, ó ní ọgbẹ́ àti ojú egbò,Ẹ ò tọ́jú wọn,* ẹ ò dì wọ́n, ẹ ò sì fi òróró pa wọ́n.+
7 Ilẹ̀ yín ti di ahoro.
Wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.
Àwọn àjèjì jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.+
Ó dà bí ilẹ̀ tó di ahoro tí àwọn àjèjì gbà.+
8 Ó wá ku ọmọbìnrin Síónì nìkan, bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,Bí ahéré nínú oko kùkúńbà,*Bí ìlú tí wọ́n gbógun tì.+
9 Tí kì í bá ṣe pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ nínú wa sí,À bá ti dà bíi Sódómù gẹ́lẹ́,À bá sì ti jọ Gòmórà.+
10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin apàṣẹwàá* Sódómù.+
Ẹ fetí sí òfin* Ọlọ́run wa, ẹ̀yin èèyàn Gòmórà.+
11 “Àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ ẹbọ yín ń ṣe mí?”+ ni Jèhófà wí.
“Àwọn ẹbọ sísun yín tí ẹ fi àgbò+ ṣe àti ọ̀rá àwọn ẹran tí ẹ bọ́ dáadáa + ti sú mi,Inú mi ò dùn sí ẹ̀jẹ̀+ àwọn akọ ọmọ màlúù,+ ọ̀dọ́ àgùntàn àti ewúrẹ́.+
12 Bí ẹ ṣe ń wá síwájú mi,+Tí ẹ̀ ń tẹ àgbàlá mi mọ́lẹ̀,Ta ló ní kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀?+
13 Ẹ má ṣe mú àwọn ọrẹ ọkà tí kò ní láárí wá mọ́.
Tùràrí yín ń rí mi lára.+
Àwọn òṣùpá tuntun,+ sábáàtì+ àti pípe àpéjọ,+Mi ò lè fara da bí ẹ ṣe ń pidán,+ tí ẹ sì tún ń ṣe àpéjọ ọlọ́wọ̀.
14 Mo* kórìíra àwọn òṣùpá tuntun yín àtàwọn àjọyọ̀ yín.
Wọ́n ti di ẹrù ìnira fún mi;Mi ò lè gbé e mọ́.
15 Tí ẹ bá sì tẹ́ ọwọ́ yín,Mò ń fojú mi pa mọ́ fún yín.+
Bí ẹ tiẹ̀ ń gbàdúrà púpọ̀,+Mi ò gbọ́ àdúrà yín;+Ẹ̀jẹ̀ kún ọwọ́ yín.+
16 Ẹ wẹ ara yín, ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́;+Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi;Ẹ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.+
17 Ẹ kọ́ bí ẹ ṣe máa ṣe rere, ẹ wá ìdájọ́ òdodo,+Ẹ tọ́ àwọn aninilára sọ́nà;Ẹ gbèjà àwọn ọmọ aláìníbaba,*Kí ẹ sì gba ẹjọ́ opó rò.”+
18 “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa,” ni Jèhófà wí.+
“Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò,Wọ́n máa di funfun bíi yìnyín;+Bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò,Wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.
19 Tó bá tinú yín wá, tí ẹ sì fetí sílẹ̀,Ẹ máa jẹ àwọn ohun rere ilẹ̀ náà.+
20 Àmọ́ tí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,Idà máa jẹ yín run,+Torí Jèhófà ti fi ẹnu rẹ̀ sọ ọ́.”
21 Ẹ wo bí ìlú olóòótọ́+ ṣe di aṣẹ́wó!+
Ìdájọ́ òdodo kún inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀;+Òdodo ń gbé inú rẹ̀ nígbà kan,+Àmọ́ ní báyìí, àwọn apààyàn ló wà níbẹ̀.+
22 Fàdákà rẹ ti di ìdàrọ́,+Wọ́n sì ti bu omi la ọtí bíà rẹ.*
23 Alágídí ni àwọn ìjòyè rẹ, àwọn àtàwọn olè jọ ń ṣiṣẹ́.+
Gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.+
Wọn kì í dá ẹjọ́ àwọn ọmọ aláìníbaba* bó ṣe tọ́,Ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.+
24 Torí náà, Olúwa tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,Alágbára Ísírẹ́lì, kéde pé:
“Ó tó gẹ́ẹ́! Mi ò ní fàyè gba àwọn elénìní mi mọ́,Màá sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.+
25 Màá yí ọwọ́ mi pa dà sí ọ,Màá yọ́ ìdàrọ́ rẹ dà nù bíi pé mo fi ọṣẹ fọ ìdọ̀tí,Màá sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.+
26 Màá dá àwọn adájọ́ rẹ pa dà sí bí wọ́n ṣe wà níbẹ̀rẹ̀,Àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ á sì rí bíi ti ìbẹ̀rẹ̀.+
Lẹ́yìn èyí, wọ́n máa pè ọ́ ní Ìlú Òdodo, Ìlú Olóòótọ́.+
27 Ìdájọ́ òdodo la máa fi tún Síónì rà pa dà,+Àwọn èèyàn rẹ̀ tó pa dà la sì máa fi òdodo rà pa dà.
28 Àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ máa fọ́ sí wẹ́wẹ́,+Òpin sì máa dé bá àwọn tó ń fi Jèhófà sílẹ̀.+
29 Torí àwọn igi ńlá tó wù yín máa tì wọ́n lójú,+Ojú sì máa tì yín torí àwọn ọgbà* tí ẹ yàn.+
30 Torí ẹ máa dà bí igi ńlá tí àwọn ewé rẹ̀ rọ+
Àti bí ọgbà tí kò lómi.
31 Ọkùnrin alágbára máa di èétú okùn,*Iṣẹ́ rẹ̀ sì máa ta pàrà;Iná máa jó àwọn méjèèjì pa pọ̀,Kò sì ní sẹ́ni tó máa pa iná náà.”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ó túmọ̀ sí “Ìgbàlà Jèhófà.”
^ Tàbí “mọ olúwa rẹ̀.”
^ Ní Héb., “tẹ̀ wọ́n.”
^ Tàbí “apálá.”
^ Tàbí “alákòóso.”
^ Tàbí “ìtọ́ni.”
^ Tàbí “Ọkàn mi.”
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Tàbí “bíà rẹ tí wọ́n fi wíìtì ṣe.”
^ Tàbí “aláìlóbìí.”
^ Ó jọ pé àwọn igi àti àwọn ọgbà tó jẹ mọ́ ìjọsìn òrìṣà ló ń sọ.
^ Ohun tó rí bí okùn tó sì lè tètè jóná.