Àìsáyà 14:1-32

  • Ísírẹ́lì máa gbé ní ilẹ̀ tirẹ̀ (1, 2)

  • Wọ́n fi ọba Bábílónì ṣe ẹlẹ́yà (3-23)

    • Ẹni tó ń tàn máa já bọ́ láti ọ̀run (12)

  • Ọwọ́ Jèhófà máa fọ́ ará Ásíríà túútúú (24-27)

  • Ọ̀rọ̀ ìkéde sí Filísíà (28-32)

14  Torí Jèhófà máa ṣàánú Jékọ́bù,+ ó sì máa tún Ísírẹ́lì yàn.+ Ó máa mú kí wọ́n gbé* ní ilẹ̀ wọn,+ àwọn àjèjì máa dara pọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì máa sọ ara wọn di ará ilé Jékọ́bù.+  Àwọn èèyàn máa mú wọn, wọ́n á mú wọn wá sí àyè wọn, ilé Ísírẹ́lì sì máa fi wọ́n ṣe ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin+ ní ilẹ̀ Jèhófà; wọ́n máa mú àwọn tó mú wọn lẹ́rú, wọ́n sì máa di olórí àwọn tó fipá kó wọn ṣiṣẹ́.  Ní ọjọ́ tí Jèhófà bá mú kí o bọ́ nínú ìrora rẹ, rúkèrúdò rẹ àti bí wọ́n ṣe ń fipá mú ọ sìnrú,+  o máa pa òwe* yìí sí ọba Bábílónì pé: “Ẹ wo bí òpin ṣe dé bá ẹni tó ń fipá kó àwọn míì ṣiṣẹ́! Ẹ wo bí ìfìyàjẹni ṣe wá sí òpin!+   Jèhófà ti kán ọ̀pá àwọn ẹni burúkú,Ọ̀pá àwọn tó ń ṣàkóso,+   Ẹni tó ń fìbínú kan àwọn èèyàn lẹ́ṣẹ̀ẹ́ láìdáwọ́ dúró,+Ẹni tó ń fi ìkannú tẹ àwọn orílẹ̀-èdè lórí ba, tó sì ń ṣe inúnibíni sí wọn láìṣíwọ́.+   Gbogbo ayé ti wá sinmi, ó bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn èèyàn ń kígbe ayọ̀.+   Àwọn igi júnípà pàápàá ń yọ̀ torí rẹ,Pẹ̀lú àwọn igi kédárì Lẹ́bánónì. Wọ́n sọ pé, ‘Látìgbà tí o ti ṣubú,Kò sí agégi kankan tó dìde sí wa.’   Isà Òkú* tó wà nísàlẹ̀ pàápàá ti ru sókè,Láti pàdé rẹ tí o bá dé. Nítorí rẹ, ó jí àwọn tí ikú ti pa,*Gbogbo àwọn aṣáájú ayé tó ń fìyà jẹni.* Ó ń mú kí gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè dìde lórí ìtẹ́ wọn. 10  Gbogbo wọn sọ fún ọ pé,‘Ṣé ìwọ náà ti di aláìlágbára bíi tiwa ni? Ṣé o ti dà bíi wa ni? 11  A ti mú ìyangàn rẹ lọ sínú Isà Òkú,*Ìró àwọn ohun ìkọrin rẹ olókùn tín-ín-rín.+ Àwọn ìdin tẹ́ rẹrẹ lábẹ́ rẹ bí ibùsùn,Kòkòrò mùkúlú sì ni ìbora rẹ.’ 12  Wo bí o ṣe já bọ́ láti ọ̀run,Ìwọ ẹni tó ń tàn, ọmọ òwúrọ̀! Wo bí a ṣe gé ọ já bọ́ lulẹ̀,Ìwọ tó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè!+ 13  O sọ lọ́kàn rẹ pé, ‘Màá gòkè lọ sí ọ̀run.+ Màá gbé ìtẹ́ mi ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,+Màá sì jókòó sórí òkè ìpàdé,Láwọn ibi tó jìnnà jù ní àríwá.+ 14  Màá gòkè lọ sórí àwọsánmà;*Màá mú ara mi jọ Ẹni Gíga Jù Lọ.’ 15  Kàkà bẹ́ẹ̀, a máa sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,*Sí àwọn ibi tó jìnnà jù nínú kòtò. 16  Àwọn tó rí ọ máa tẹjú mọ́ ọ;Wọ́n máa yẹ̀ ọ́ wò fínnífínní, wọ́n á sọ pé,‘Ṣé ọkùnrin tó ń mi ayé tìtì nìyí,Tó kó jìnnìjìnnì bá àwọn ìjọba,+ 17  Tó mú kí ilẹ̀ ayé tí à ń gbé dà bí aginjù,Tó sì gba àwọn ìlú rẹ̀,+Tí kò jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ̀ pa dà sílé?’+ 18  Gbogbo ọba àwọn orílẹ̀-èdè yòókù,Àní, gbogbo wọn dùbúlẹ̀ nínú ògo,Kálukú nínú ibojì* rẹ̀. 19  Àmọ́ a sọ ìwọ nù láìní sàréè,Bí èéhù* tí a kórìíra,Tí wọ́n fi àwọn tí a fi idà gún pa, bò bí aṣọ,Tó sọ̀ kalẹ̀ lọ bá àwọn òkúta inú kòtò,Bí òkú tí wọ́n fẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. 20  O ò ní lọ bá wọn nínú sàréè,Torí o run ilẹ̀ rẹ,O pa àwọn èèyàn tìrẹ. A ò ní dárúkọ ọmọ àwọn aṣebi mọ́ títí láé. 21  Ẹ ṣètò ibi ìpẹran fún àwọn ọmọ rẹ̀,Torí ẹ̀bi àwọn baba ńlá wọn,Kí wọ́n má bàa dìde, kí wọ́n sì gba ayé,Kí wọ́n wá fi àwọn ìlú wọn kún ilẹ̀ náà.” 22  “Màá dìde sí wọn,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. “Màá pa orúkọ àti àṣẹ́kù run, màá sì pa àtọmọdọ́mọ àti ìran tó ń bọ̀ run kúrò ní Bábílónì,”+ ni Jèhófà wí. 23  “Màá sọ ọ́ di ibùgbé àwọn òòrẹ̀ àti agbègbè tó ní irà, màá sì fi ìgbálẹ̀ ìparun gbá a,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 24  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti búra pé: “Bí mo ṣe gbèrò gẹ́lẹ́ ló máa rí,Ohun tí mo sì pinnu gẹ́lẹ́ ló máa ṣẹ. 25  Màá fọ́ ará Ásíríà náà túútúú ní ilẹ̀ mi,Màá sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi.+ Àjàgà rẹ̀ máa kúrò lọ́rùn wọn,Ẹrù rẹ̀ sì máa kúrò ní èjìká wọn.”+ 26  Ohun tí a ti pinnu láti ṣe* sí gbogbo ayé nìyí,Ọwọ́ tí a sì nà jáde sí* gbogbo orílẹ̀-èdè nìyí. 27  Torí pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti pinnu,Ta ló lè dà á rú?+ Ó ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde,Ta ló sì lè dá a pa dà?+ 28  Ní ọdún tí Ọba Áhásì kú,+ ìkéde yìí wáyé, pé: 29  “Kí ẹnì kankan nínú rẹ má yọ̀, ìwọ Filísíà,Torí pé ọ̀pá ẹni tó ń lù ọ́ ti kán. Torí ejò olóró+ máa jáde látinú gbòǹgbò ejò,+Ọmọ rẹ̀ sì máa jẹ́ ejò oníná tó ń fò.* 30  Tí àkọ́bí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ bá ń jẹun,Tí àwọn aláìní sì dùbúlẹ̀ láìséwu,Màá fi ìyàn pa gbòǹgbò rẹ,A sì máa pa ohun tó bá ṣẹ́ kù lára rẹ.+ 31  Pohùn réré ẹkún, ìwọ ẹnubodè! Ké jáde, ìwọ ìlú! Ọkàn gbogbo yín máa domi, ẹ̀yin Filísíà! Torí èéfín ń rú bọ̀ láti àríwá,Kò sì sẹ́ni tí kì í ṣe kánkán nínú ọ̀wọ́ ọmọ ogun rẹ̀.” 32  Báwo ni kí wọ́n ṣe dá àwọn ìránṣẹ́ orílẹ̀-èdè náà lóhùn? Pé Jèhófà ti fi ìpìlẹ̀ Síónì lélẹ̀+ Àti pé àwọn tó rẹlẹ̀ nínú àwọn èèyàn rẹ̀ máa fi ibẹ̀ ṣe ààbò.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “fún wọn ní ìsinmi.”
Tàbí “sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ti sọ di aláìlágbára.”
Ní Héb., “àwọn òbúkọ ayé.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ìkùukùu.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “ilé.”
Tàbí “ẹ̀ka.”
Ní Héb., “Ìmọ̀ràn tí a gbà.”
Tàbí “tó ṣe tán láti kọ lu.”
Tàbí “ejò olóró tó ń yára kánkán.”