Sámúẹ́lì Kìíní 17:1-58

  • Dáfídì ṣẹ́gun Gòláyátì (1-58)

    • Gòláyátì pẹ̀gàn Ísírẹ́lì (8-10)

    • Dáfídì pinnu láti lọ jà (32-37)

    • Dáfídì jà ní orúkọ Jèhófà (45-47)

17  Àwọn Filísínì+ kó àwọn ọmọ ogun* wọn jọ láti jagun. Wọ́n kóra jọ sí Sókọ̀+ ti ilẹ̀ Júdà, wọ́n sì dó sí àárín Sókọ̀ àti Ásékà,+ ní Efesi-dámímù.+  Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì kóra jọ, wọ́n pàgọ́ sí Àfonifojì* Élà,+ wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti pàdé àwọn Filísínì.  Àwọn Filísínì wà lórí òkè ní ẹ̀gbẹ́ kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì wà lórí òkè ní ẹ̀gbẹ́ kejì, àfonífojì sì wà láàárín wọn.  Ni akọgun kan bá jáde láti ibùdó àwọn Filísínì, Gòláyátì ni orúkọ rẹ̀,+ ará Gátì ni,+ gíga rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.*  Ó dé akoto* bàbà sórí, ó sì wọ ẹ̀wù irin tí àwọn ìpẹ́ rẹ̀ gbẹ́nu léra. Ìwọ̀n ẹ̀wù irin bàbà+ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ṣékélì.*  Kóbìtà* bàbà wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì gbé ẹ̀ṣín*+ bàbà kọ́ èjìká rẹ̀.  Igi ọ̀kọ̀ rẹ̀ dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ,*+ ìwọ̀n irin tí wọ́n fi ṣe aṣóró ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì;* ẹni tó ń bá a gbé apata sì ń lọ níwájú rẹ̀.  Ó wá dúró, ó nahùn jáde sí ìlà ogun Ísírẹ́lì,+ ó sì sọ fún wọn pé: “Kí nìdí tí ẹ fi jáde wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun? Ṣebí èmi ni alágbára Filísínì, ẹ̀yin sì ni ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù. Torí náà, ẹ yan ọkùnrin kan lára yín kó wá bá mi.  Tó bá lè bá mi jà, tó sì mú mi balẹ̀, a ó di ìránṣẹ́ yín. Àmọ́ tí mo bá borí rẹ̀, tí mo sì mú un balẹ̀, ẹ ó di ìránṣẹ́ wa, ẹ ó sì máa sìn wá.” 10  Filísínì náà wá sọ pé: “Mo pẹ̀gàn ìlà ogun Ísírẹ́lì*+ lónìí yìí. Ẹ rán ọkùnrin kan sí mi, kí a jọ figẹ̀ wọngẹ̀!” 11  Ìgbà tí Sọ́ọ̀lù àti gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Filísínì náà sọ, àyà wọn já, ẹ̀rù sì bà wọ́n gan-an. 12  Dáfídì jẹ́ ọmọ Jésè ará Éfúrátà+ láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Júdà. Jésè+ ní ọmọkùnrin mẹ́jọ,+ ó sì ti darúgbó gan-an ní ayé ìgbà Sọ́ọ̀lù. 13  Àwọn mẹ́ta tó dàgbà jù lára àwọn ọmọkùnrin Jésè ti tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù lọ sí ogun.+ Orúkọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó lọ sójú ogun ni Élíábù+ àkọ́bí, Ábínádábù+ ìkejì àti Ṣámà ìkẹta.+ 14  Dáfídì ló kéré jù,+ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó dàgbà jù sì tẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù. 15  Nígbà tí Dáfídì wà lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó máa ń lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti lọ tọ́jú àwọn àgùntàn+ bàbá rẹ̀, á sì pa dà. 16  Lákòókò yìí, ó ti pé ogójì (40) ọjọ́ tí Filísínì náà ti ń jáde wá tí á sì dúró láràárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́-ìrọ̀lẹ́. 17  Ìgbà náà ni Jésè sọ fún Dáfídì ọmọ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, gba àyangbẹ ọkà òṣùwọ̀n eéfà* yìí àti búrẹ́dì mẹ́wàá yìí, kí o tètè gbé e lọ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ ní ibùdó. 18  Gba wàrà* mẹ́wàá yìí lọ fún olórí ẹgbẹ̀rún; bákan náà, kí o wo àlàáfíà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ, kí o sì gba àmì ìdánilójú bọ̀ látọ̀dọ̀ wọn.” 19  Wọ́n wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yòókù ní Àfonífojì* Élà,+ wọ́n ń bá àwọn Filísínì jà.+ 20  Nítorí náà, Dáfídì dìde ní àárọ̀ kùtù, ó sì fi ẹnì kan ti àwọn àgùntàn; ó di ẹrù náà, ó sì lọ bí Jésè ti pàṣẹ fún un. Nígbà tí ó dé etí ibùdó, àwọn ọmọ ogun ń jáde lọ sí ìlà ogun, wọ́n sì ń kígbe ogun. 21  Ísírẹ́lì àti àwọn Filísínì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjà, ìlà ogun kan sì dojú kọ ìlà ogun kejì. 22  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Dáfídì gbé ẹrù rẹ̀ ti ẹni tó ń bójú tó ẹrù, ó sì sáré lọ sí ìlà ogun. Nígbà tó dé ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àlàáfíà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀.+ 23  Bó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, akọgun tó ń jẹ́ Gòláyátì+ dé, Filísínì tó wá láti Gátì. Ó jáde wá láti ìlà ogun àwọn Filísínì, ó tún sọ ọ̀rọ̀ tó máa ń sọ,+ Dáfídì sì gbọ́ ohun tó sọ. 24  Nígbà tí gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì rí ọkùnrin náà, wọ́n sá sẹ́yìn, jìnnìjìnnì sì bá wọn.+ 25  Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ń sọ pé: “Ṣé ẹ rí ọkùnrin tó ń jáde bọ̀ yìí? Ńṣe ló wá pẹ̀gàn Ísírẹ́lì.*+ Ọrọ̀ tó pọ̀ ni ọba máa fún ọkùnrin tó bá mú un balẹ̀, á tún fún un ní ọmọbìnrin rẹ̀,+ ilé bàbá rẹ̀ kò sì ní san nǹkan kan mọ́ ní Ísírẹ́lì.” 26  Dáfídì béèrè lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tó dúró nítòsí rẹ̀ pé: “Kí ni wọ́n máa ṣe fún ọkùnrin tó bá mú Filísínì tó wà níbẹ̀ yẹn balẹ̀, tó sì mú ẹ̀gàn kúrò lórí Ísírẹ́lì? Ta tiẹ̀ ni Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí tí á fi máa pẹ̀gàn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè?”+ 27  Ni àwọn èèyàn náà bá sọ ohun tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ fún un pé: “Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ọkùnrin tó bá mú un balẹ̀ nìyí.” 28  Nígbà tí Élíábù+ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tó ń bá àwọn ọkùnrin náà sọ̀rọ̀, inú bí i gan-an sí Dáfídì, ó sọ pé: “Kí lo wá débí? Ta lo fi ìwọ̀nba àgùntàn yẹn tì ní aginjù?+ Mo mọ̀ dáadáa pé o máa ń kọjá àyè rẹ, mo sì mọ èrò burúkú tó wà lọ́kàn rẹ; torí kí o lè rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójú ogun lo ṣe wá.” 29  Ni Dáfídì bá fèsì pé: “Kí ni mo tún ṣe báyìí? Ṣebí mo kàn béèrè ọ̀rọ̀ ni!” 30  Torí náà, ó yíjú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ẹlòmíì, ó sì béèrè ohun tó béèrè tẹ́lẹ̀,+ àwọn èèyàn náà sì fún un lésì bíi ti tẹ́lẹ̀.+ 31  Ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ ta sí àwọn kan létí, wọ́n sì lọ sọ fún Sọ́ọ̀lù. Torí náà, ó ránṣẹ́ pè é. 32  Dáfídì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Kí ọkàn ẹnikẹ́ni má ṣe domi* nítorí ọkùnrin náà. Ìránṣẹ́ rẹ máa lọ bá Filísínì náà jà.”+ 33  Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “O ò lè lọ bá Filísínì yìí jà, torí ọmọdé ni ọ́,+ àmọ́ jagunjagun* ni òun láti ìgbà èwe rẹ̀.” 34  Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ń ṣọ́ agbo ẹran bàbá rẹ̀, kìnnìún+ kan wá, lẹ́yìn náà bíárì kan wá pẹ̀lú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbé àgùntàn lọ nínú agbo ẹran. 35  Mo gbá tẹ̀ lé e, mo mú un balẹ̀, mo sì gba àgùntàn náà sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀. Nígbà tó dìde sí mi, mo gbá a mú níbi irun ọrùn rẹ̀,* mo mú un balẹ̀, mo sì pa á. 36  Àti kìnnìún àti bíárì náà ni ìránṣẹ́ rẹ pa, Filísínì aláìdádọ̀dọ́* yìí á sì dà bí ọ̀kan lára wọn, nítorí ó ti pẹ̀gàn àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè.”*+ 37  Dáfídì wá fi kún un pé: “Jèhófà tó gbà mí lọ́wọ́* kìnnìún àti bíárì náà, ló máa gbà mí lọ́wọ́ Filísínì yìí.”+ Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ, kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” 38  Sọ́ọ̀lù wá gbé ẹ̀wù rẹ̀ wọ Dáfídì. Ó fi akoto* bàbà dé e lórí, lẹ́yìn náà ó gbé ẹ̀wù irin wọ̀ ọ́. 39  Dáfídì sì di idà rẹ̀ mọ́ ẹ̀wù rẹ̀, ó fẹ́ máa lọ, àmọ́ kò lè rìn, nítorí kò mọ́ ọn lára. Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Mi ò lè wọ nǹkan wọ̀nyí rìn, nítorí wọn ò mọ́ mi lára.” Torí náà, Dáfídì bọ́ wọn kúrò. 40  Ó mú ọ̀pá rẹ̀ dání, ó ṣa òkúta márùn-ún tó jọ̀lọ̀ nínú odò, ó kó wọn sínú àpò tí ó fi ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, kànnàkànnà+ rẹ̀ sì wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ó sì ń bọ̀ lọ́dọ̀ Filísínì náà. 41  Filísínì náà ń sún mọ́ Dáfídì, ẹni tó ń bá a gbé apata rẹ̀ sì wà níwájú rẹ̀. 42  Nígbà tí Filísínì náà rí Dáfídì lọ́ọ̀ọ́kán, ó wò ó tẹ̀gàntẹ̀gàn torí pé ọmọdé ni, ó pupa, ó sì rẹwà.+ 43  Ni Filísínì náà bá sọ fún Dáfídì pé: “Ṣé ajá+ lo fi mí pè ni, tí o fi ń mú ọ̀pá bọ̀ wá bá mi jà?” Filísínì náà bá fi Dáfídì gégùn-ún ní orúkọ àwọn ọlọ́run rẹ̀. 44  Filísínì náà sọ fún Dáfídì pé: “Ṣáà máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi, màá fi ẹran ara rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko inú igbó.” 45  Dáfídì fún Filísínì náà lésì pé: “Ìwọ ń mú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín*+ bọ̀ wá bá mi jà, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ wá bá ọ ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun,+ Ọlọ́run ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí o pẹ̀gàn.*+ 46  Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́,+ màá mú ọ balẹ̀, màá sì gé orí rẹ kúrò. Lónìí yìí kan náà, màá fi òkú àwọn tó wà ní ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹran inú igbó; gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà ní Ísírẹ́lì.+ 47  Gbogbo àwọn tó pé jọ síbí* yóò mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là,+ torí ogun náà jẹ́ ti Jèhófà,+ á sì fi gbogbo yín lé wa lọ́wọ́.”+ 48  Ni Filísínì náà bá dìde, ó sì ń bọ̀ tààràtà láti pàdé Dáfídì, àmọ́ Dáfídì tètè sáré lọ sí ìlà ogun láti pàdé rẹ̀. 49  Dáfídì ki ọwọ́ bọ inú àpò rẹ̀, ó mú òkúta kan níbẹ̀, ó sì ta á. Ó ba iwájú orí Filísínì náà, òkúta náà wọ orí rẹ̀ lọ, ó sì ṣubú ní ìdojúbolẹ̀.+ 50  Bí Dáfídì ṣe fi kànnàkànnà àti òkúta kan ṣẹ́gun Filísínì náà nìyẹn; ó mú Filísínì náà balẹ̀, ó sì pa á, bó tilẹ̀ jẹ́ pe kò sí idà lọ́wọ́ Dáfídì.+ 51  Dáfídì sáré lọ, ó sì dúró ti Filísínì náà. Ó gbá idà Filísínì+ náà mú, ó fà á yọ nínú àkọ̀ rẹ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀ kúrò kó lè rí i dájú pé ó ti kú. Nígbà tí àwọn Filísínì rí i pé alágbára wọn ti kú, wọ́n fẹsẹ̀ fẹ.+ 52  Ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà bá dìde, wọ́n kígbe, wọ́n sì lépa àwọn Filísínì láti àfonífojì+ títí lọ dé àwọn ẹnubodè Ẹ́kírónì,+ àwọn Filísínì tó kú sì wà nílẹ̀ lójú ọ̀nà láti Ṣááráímù,+ títí dé Gátì àti Ẹ́kírónì. 53  Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà lẹ́yìn àwọn Filísínì tí wọ́n lé lọ kíkankíkan, wọ́n kó ẹrù tó wà ní ibùdó wọn. 54  Dáfídì gbé orí Filísínì náà wá sí Jerúsálẹ́mù, àmọ́ ó kó àwọn ohun ìjà Filísínì náà sínú àgọ́ tirẹ̀.+ 55  Gbàrà tí Sọ́ọ̀lù rí Dáfídì tó ń jáde lọ pàdé Filísínì náà, ó bi Ábínérì+ olórí ọmọ ogun pé: “Ábínérì, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?”+ Ábínérì fèsì pé: “Bí o* ti wà láàyè, ìwọ ọba, mi ò mọ̀!” 56  Ọba wá sọ pé: “Lọ wádìí ọmọ ẹni tí ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́.” 57  Torí náà, gbàrà tí Dáfídì pa dà láti ibi tó ti lọ pa Filísínì náà, Ábínérì mú un wá síwájú Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú orí Filísínì+ náà ní ọwọ́ rẹ̀. 58  Sọ́ọ̀lù wá sọ fún un pé: “Ọmọ ta ni ọ́, ìwọ ọmọdékùnrin yìí?” Dáfídì fèsì pé: “Ọmọ Jésè  + ìránṣẹ́ rẹ ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àwọn ibùdó.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Gíga rẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi mítà 2.9 (ẹsẹ̀ bàtà 9 ínǹṣì 5.75.) Wo Àfikún B14.
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Nǹkan bíi kìlógíráàmù 57. Wo Àfikún B14.
Ìyẹn, ohun tí àwọn ọmọ ogun fi ń bo ojúgun.
Tàbí “ọ̀kọ̀ kékeré.”
Tàbí “olófì.”
Nǹkan bíi kìlógíráàmù 6.84. Wo Àfikún B14.
Tàbí “Mo pe ìlà ogun Ísírẹ́lì níjà.”
Nǹkan bíi Lítà 22. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “mílíìkì.”
Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “pe Ísírẹ́lì níjà.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “rẹ̀wẹ̀sì.”
Tàbí “ọkùnrin ogun.”
Tàbí “ní páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́.” Ní Héb., “ní irùngbọ̀n.”
Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “pe àwọn ìlà ogun Ọlọ́run alààyè níjà.”
Ní Héb., “lọ́wọ́ èékánná.”
Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.
Tàbí “pè níjà.”
Tàbí “ọ̀kọ̀ kékeré.”
Ní Héb., “Gbogbo ìjọ yìí.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”