Sámúẹ́lì Kìíní 23:1-29

  • Dáfídì gba ìlú Kéílà sílẹ̀ (1-12)

  • Sọ́ọ̀lù lépa Dáfídì (13-15)

  • Jónátánì fún Dáfídì lókun (16-18)

  • Díẹ̀ ló kù kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù tẹ Dáfídì (19-29)

23  Nígbà tó yá, wọ́n sọ fún Dáfídì pé: “Àwọn Filísínì ń bá Kéílà+ jà, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rù ní àwọn ibi ìpakà.”  Torí náà, Dáfídì wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà pé:+ “Ṣé kí n lọ mú àwọn Filísínì yìí balẹ̀?” Jèhófà sọ fún Dáfídì pé: “Lọ mú àwọn Filísínì náà balẹ̀, kí o sì gba Kéílà sílẹ̀.”  Àmọ́ àwọn ọkùnrin Dáfídì sọ fún un pé: “Wò ó! Bí a ṣe wà níbí ní Júdà,+ ẹ̀rù ṣì ń bà wá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé ká lọ sí Kéílà láti dojú kọ ìlà ogun àwọn Filísínì!”+  Torí náà, Dáfídì wádìí lẹ́ẹ̀kan sí i lọ́dọ̀ Jèhófà.+ Jèhófà sì dá a lóhùn pé: “Dìde; lọ sí Kéílà torí màá fi àwọn Filísínì náà lé ọ lọ́wọ́.”+  Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ bá lọ sí Kéílà, ó sì bá àwọn Filísínì jà; ó kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ, ó pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ, Dáfídì sì gba àwọn tó ń gbé ní Kéílà+ sílẹ̀.  Nígbà tí Ábíátárì+ ọmọ Áhímélékì sá lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Kéílà, éfódì kan wà lọ́wọ́ rẹ̀.  Wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dáfídì ti wá sí Kéílà.” Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́,*+ nítorí ó ti há ara rẹ̀ mọ́ bó ṣe wá sínú ìlú tó ní àwọn ilẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.”  Nítorí náà, Sọ́ọ̀lù pe gbogbo àwọn èèyàn náà sí ogun, láti lọ sí Kéílà, kí wọ́n sì dó ti Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀.  Nígbà tí Dáfídì gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù ń gbìmọ̀ ibi sí òun, ó sọ fún àlùfáà Ábíátárì pé: “Mú éfódì wá.”+ 10  Dáfídì wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù fẹ́ wá sí Kéílà láti pa ìlú náà run nítorí mi.+ 11  Ṣé àwọn olórí* Kéílà máa fi mí lé e lọ́wọ́? Ṣé Sọ́ọ̀lù máa wá lóòótọ́ bí ìránṣẹ́ rẹ ṣe gbọ́? Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, jọ̀wọ́ sọ fún ìránṣẹ́ rẹ.” Ni Jèhófà bá fèsì pé: “Ó máa wá.” 12  Dáfídì béèrè pé: “Ṣé àwọn olórí Kéílà máa fi èmi àti àwọn ọkùnrin mi lé Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́?” Jèhófà dáhùn pé: “Wọ́n á fi yín lé e lọ́wọ́.” 13  Ní kíá, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ dìde, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ni wọ́n,+ wọ́n kúrò ní Kéílà, wọ́n sì ń lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá lè lọ. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà, kò wá a lọ mọ́. 14  Dáfídì ń gbé ní aginjù ní àwọn ibi tó ṣòroó dé, ní agbègbè olókè tó wà ní aginjù Sífù.+ Gbogbo ìgbà ni Sọ́ọ̀lù ń wá a kiri,+ àmọ́ Jèhófà kò fi lé e lọ́wọ́. 15  Dáfídì mọ̀ pé* Sọ́ọ̀lù ti jáde lọ láti gba ẹ̀mí* òun nígbà tí Dáfídì ṣì wà ní aginjù Sífù ní Hóréṣì. 16  Ni Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù bá lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, ó sì ràn án lọ́wọ́ kí ó lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà.+ 17  Ó sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, torí pé Sọ́ọ̀lù bàbá mi kò ní rí ọ mú; ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì,+ èmi ni màá di igbá kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.”+ 18  Àwọn méjèèjì wá dá májẹ̀mú+ níwájú Jèhófà, Dáfídì dúró sí Hóréṣì, Jónátánì sì gba ilé rẹ̀ lọ. 19  Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin Sífù lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n sọ pé: “Ṣebí tòsí wa ni Dáfídì fara pa mọ́ sí,+ ní àwọn ibi tó ṣòroó dé ní Hóréṣì,+ lórí òkè Hákílà,+ tó wà ní gúúsù* Jéṣímónì.*+ 20  Ìgbàkígbà tó bá wù ọ́* láti wá, ìwọ ọba, o lè wá, a ó sì fà á lé ọba lọ́wọ́.”+ 21  Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Kí Jèhófà bù kún yín, nítorí ẹ ti ṣàánú mi. 22  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ lọ bá mi wá ọ̀gangan ibi tó wà, kí ẹ wádìí lọ́wọ́ ẹni tó bá rí i níbẹ̀, nítorí mo ti gbọ́ pé alárèékérekè ni. 23  Ẹ fara balẹ̀ wá gbogbo ibi tó máa ń fara pa mọ́ sí, kí ẹ sì mú ẹ̀rí bọ̀ wá fún mi. Nígbà náà, màá bá yín lọ, tó bá sì wà ní ilẹ̀ náà, màá wá a jáde láàárín gbogbo ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Júdà.” 24  Nítorí náà, wọ́n ṣáájú Sọ́ọ̀lù lọ sí Sífù,+ nígbà tí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ṣì wà ní aginjù Máónì+ ní Árábà+ ní apá gúúsù Jéṣímónì. 25  Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wá a wá.+ Nígbà tí wọ́n sọ fún Dáfídì, ní kíá, ó lọ sí ibi àpáta,+ ó sì dúró sí aginjù Máónì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbọ́, ó lépa Dáfídì wọ inú aginjù Máónì. 26  Bí Sọ́ọ̀lù ṣe dé ẹ̀gbẹ́ kan òkè náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì òkè náà. Dáfídì ṣe kánkán+ kí ọwọ́ Sọ́ọ̀lù má bàa tẹ̀ ẹ́, àmọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ túbọ̀ ń sún mọ́ Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ láti gbá wọn mú.+ 27  Ṣùgbọ́n òjíṣẹ́ kan wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Tètè máa bọ̀, nítorí àwọn Filísínì ti wá kó ẹrù ní ilẹ̀ wa!” 28  Ni Sọ́ọ̀lù ò bá lépa Dáfídì mọ́,+ ó sì lọ gbéjà ko àwọn Filísínì. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pe ibẹ̀ ní Àpáta Ìpínyà. 29  Lẹ́yìn náà, Dáfídì kúrò níbẹ̀, ó sì dúró sí àwọn ibi tó ṣòroó dé ní Ẹ́ń-gédì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “tà á sọ́wọ́ mi.”
Tàbí kó jẹ́, “àwọn onílẹ̀.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀rù ń ba Dáfídì torí pé.”
Tàbí “ọkàn.”
Ní Héb., “ó sì fún ọwọ́ rẹ̀ lókun nínú.”
Ní Héb., “ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún.”
Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀; aginjù.”
Tàbí “wu ọkàn rẹ.”
Tàbí “agbo ilé.”