Sámúẹ́lì Kìíní 14:1-52

  • Àṣeyọrí tí Jónátánì ṣe ní Míkímáṣì (1-14)

  • Ọlọ́run lé àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì lọ (15-23)

  • Ẹ̀jẹ́ tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ láìronú jinlẹ̀ (24-46)

    • Àwọn èèyàn jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀ (32-34)

  • Àwọn ogun tí Sọ́ọ̀lù jà; ìdílé rẹ̀ (47-52)

14  Lọ́jọ́ kan, Jónátánì+ ọmọ Sọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bá a gbé àwọn ohun ìjà rẹ̀ pé: “Wá, jẹ́ ká sọdá sọ́dọ̀ àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó lódìkejì.” Àmọ́ kò sọ fún bàbá rẹ̀.  Sọ́ọ̀lù ń gbé ní ẹ̀yìn ìlú Gíbíà+ lábẹ́ igi pómégíránétì tó wà ní Mígírónì, àwọn tó sì wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọkùnrin.+  (Áhíjà ọmọ Áhítúbù,+ arákùnrin Íkábódì,+ ọmọ Fíníhásì,+ ọmọ Élì,+ àlùfáà Jèhófà ní Ṣílò+ tó ń wọ éfódì,+ sì wà pẹ̀lú wọn.) Àwọn èèyàn náà ò sì mọ̀ pé Jónátánì ti lọ.  Àpáta tó dà bí eyín wà lápá ọ̀tún àti lápá òsì ọ̀nà tí Jónátánì fẹ́ gbà kọjá lọ bá àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó, orúkọ àpáta kìíní ni Bósésì, ti ìkejì sì ni Sénè.  Èkíní jẹ́ òpó ní àríwá, ó dojú kọ Míkímáṣì, ìkejì sì wà ní gúúsù, ó dojú kọ Gébà.+  Nítorí náà, Jónátánì sọ fún ìránṣẹ́ tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Wá, jẹ́ ká sọdá lọ sọ́dọ̀ àwùjọ ọmọ ogun aláìdádọ̀dọ́*+ tó wà ní àdádó yìí. Bóyá Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́, nítorí kò sí ohun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti gbani là, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn tó pọ̀ tàbí àwọn díẹ̀.”+  Ni ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ bá sọ fún un pé: “Ṣe ohun tí ọkàn rẹ bá sọ pé kí o ṣe. Yíjú sí ibi tí o bá fẹ́, màá sì tẹ̀ lé ọ lọ sí ibikíbi tí ọkàn rẹ bá sọ.”  Jónátánì bá sọ pé: “A máa sọdá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin náà, a ó sì fi ara wa hàn wọ́n.  Tí wọ́n bá sọ fún wa pé, ‘Ẹ dúró títí a ó fi wá bá yín!’ a ó dúró sí ibi tí a wà, a ò sì ní lọ bá wọn. 10  Ṣùgbọ́n tí wọ́n bá sọ pé, ‘Ẹ wá bá wa jà!’ a ó lọ, nítorí Jèhófà yóò fi wọ́n lé wa lọ́wọ́. Èyí á sì jẹ́ àmì fún wa.”+ 11  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn méjèèjì fi ara wọn han àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó. Àwọn Filísínì sì sọ pé: “Àwọn Hébérù ti ń jáde bọ̀ látinú àwọn ihò tí wọ́n sá pa mọ́ sí.”+ 12  Torí náà, àwọn ọkùnrin ogun tó wà ní àdádó náà sọ fún Jónátánì àti ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé: “Ẹ wá bá wa, a ó sì kọ́ yín lọ́gbọ́n!”+ Ní kíá, Jónátánì sọ fún ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ pé: “Tẹ̀ lé mi, torí pé Jèhófà yóò fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́.”+ 13  Jónátánì wá fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ gòkè, ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sì tẹ̀ lé e; Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣá àwọn Filísínì balẹ̀, ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sì ń pa wọ́n bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. 14  Nígbà tí Jónátánì àti ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ kọ́kọ́ lọ jà, wọ́n pa nǹkan bí ogún (20) ọkùnrin láàárín nǹkan bí ìdajì éékà kan.* 15  Nígbà náà, jìnnìjìnnì bá àwọn tó wà ní ibùdó inú pápá àti gbogbo àwọn tó wà lára àwùjọ ọmọ ogun tó wà ní àdádó, ẹ̀rù sì ba agbo ọmọ ogun akónilẹ́rù.+ Ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mì tìtì, Ọlọ́run sì mú kí jìnnìjìnnì bá wọn. 16  Àwọn olùṣọ́ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà+ ti Bẹ́ńjámínì wá rí i pé rúkèrúdò náà ti ń dé ibi gbogbo.+ 17  Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ ka iye àwọn èèyàn, kí ẹ sì mọ ẹni tó ti kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà tí wọ́n kà wọ́n, wọ́n rí i pé Jónátánì àti ẹni tó ń gbé ìhámọ́ra rẹ̀ kò sí níbẹ̀. 18  Sọ́ọ̀lù wá sọ fún Áhíjà pé:+ “Gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sún mọ́ tòsí!” (Torí pé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkókò yẹn.*) 19  Bí Sọ́ọ̀lù ṣe ń bá àlùfáà náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, rúkèrúdò tó wà ní ibùdó àwọn Filísínì ń pọ̀ sí i. Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún àlùfáà náà pé: “Dáwọ́ ohun tí ò ń ṣe dúró.”* 20  Torí náà, Sọ́ọ̀lù àti gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ kóra jọ, wọ́n sì jáde lọ sí ojú ogun náà, ibẹ̀ ni wọ́n ti rí i tí àwọn Filísínì dojú idà kọ ara wọn, ìdàrúdàpọ̀ náà sì pọ̀ gan-an. 21  Bákan náà, àwọn Hébérù tí wọ́n ti gbè sẹ́yìn àwọn Filísínì tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti bá wọn wá sínú ibùdó wá ń pa dà sọ́dọ̀ Ísírẹ́lì lábẹ́ Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì. 22  Gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tí wọ́n fara pa mọ́+ sí agbègbè olókè Éfúrémù gbọ́ pé àwọn Filísínì ti fẹsẹ̀ fẹ, ni àwọn náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í lépa wọn lọ lójú ogun náà. 23  Torí náà, Jèhófà gba Ísírẹ́lì là lọ́jọ́ yẹn,+ ogun náà sì lọ títí dé Bẹti-áfénì.+ 24  Àmọ́, ó ti rẹ àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì tẹnutẹnu ní ọjọ́ yẹn, torí Sọ́ọ̀lù ti mú kí àwọn èèyàn náà búra pé: “Ègún ni fún ẹni tó bá jẹ oúnjẹ* kankan kó tó di ìrọ̀lẹ́ àti kó tó di ìgbà tí màá gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi!” Torí náà, kò sí ẹnì kankan nínú àwọn èèyàn náà tí ó fi oúnjẹ kan ẹnu.+ 25  Gbogbo àwọn èèyàn* náà dé inú igbó, oyin sì wà lórí ilẹ̀. 26  Nígbà tí àwọn èèyàn náà wọnú igbó náà, wọ́n rí oyin tó ń kán tótó, àmọ́ kò sí ẹni tó jẹ́ fi oyin náà kan ẹnu, torí pé wọ́n bẹ̀rù ìbúra náà. 27  Àmọ́ Jónátánì kò tíì gbọ́ pé bàbá rẹ̀ ti mú kí àwọn èèyàn náà búra,+ ni ó bá na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì ti orí rẹ̀ bọ afárá oyin náà. Nígbà tí ó fi kan ẹnu, ara rẹ̀ mókun.* 28  Ni ọ̀kan lára àwọn èèyàn náà bá sọ pé: “Bàbá rẹ mú kí àwọn èèyàn búra lọ́nà tó lágbára pé, ‘Ègún ni fún ẹni tó bá jẹ oúnjẹ lónìí!’+ Ìdí nìyẹn tó fi rẹ àwọn èèyàn náà tẹnutẹnu.” 29  Àmọ́ Jónátánì sọ pé: “Bàbá mi ti kó wàhálà ńlá* bá ilẹ̀ yìí. Ẹ wo bí ara mi ṣe mókun* nítorí oyin díẹ̀ tí mo fi kan ẹnu. 30  Ì bá dáa gan-an ká ní pé àwọn èèyàn náà ti jẹun bó ṣe wù wọ́n+ lónìí látinú ẹrù àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n rí kó! Àwọn Filísínì tí wọ́n ì bá pa ì bá sì pọ̀ gan-an ju èyí lọ.” 31  Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n ń pa àwọn Filísínì láti Míkímáṣì títí dé Áíjálónì,+ ó sì rẹ àwọn èèyàn náà gan-an. 32  Àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi wàdùwàdù kó ẹrù ogun, wọ́n mú àgùntàn àti màlúù àti ọmọ màlúù, wọ́n pa wọ́n lórí ilẹ̀, wọ́n sì ń jẹ ẹran náà tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.+ 33  Torí náà, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Wò ó! Àwọn èèyàn yìí ń dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà nítorí wọ́n ń jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”+ Ni ó bá sọ pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́. Ẹ yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ mi kíákíá.” 34  Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Ẹ lọ sáàárín àwọn èèyàn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, ‘Kí kálukú yín mú akọ màlúù rẹ̀ àti àgùntàn rẹ̀ wá, kí ó pa á níbí, lẹ́yìn náà kí ó jẹ ẹ́. Ẹ má jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀+ kí ẹ má bàa ṣẹ̀ sí Jèhófà.’” Nípa bẹ́ẹ̀, kálukú wọn mú akọ màlúù rẹ̀ wá ní òru ọjọ́ yẹn, wọ́n sì pa á níbẹ̀. 35  Sọ́ọ̀lù sì mọ pẹpẹ kan fún Jèhófà.+ Pẹpẹ yìí ló kọ́kọ́ mọ fún Jèhófà. 36  Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ gbéjà ko àwọn Filísínì ní òru, kí a sì kó nǹkan wọn títí ilẹ̀ á fi mọ́. A ò ní ṣẹ́ ẹyọ ẹnì kan kù nínú wọn.” Wọ́n fèsì pé: “Ṣe ohun tó bá dára ní ojú rẹ.” Nígbà náà, àlùfáà sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ níbí yìí.”+ 37  Sọ́ọ̀lù béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé: “Ṣé kí n lọ bá àwọn Filísínì?+ Ṣé wàá fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́?” Àmọ́ Ọlọ́run kò dá a lóhùn ní ọjọ́ yẹn. 38  Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ẹ máa bọ̀, gbogbo ẹ̀yin ìjòyè àwọn èèyàn, ẹ wádìí, kí a lè mọ ẹni tó dá ẹ̀ṣẹ̀ lónìí. 39  Nítorí bí Jèhófà, ẹni tí ó gba Ísírẹ́lì ti wà láàyè, kódà ì báà jẹ́ Jónátánì ọmọ mi ni, ó gbọ́dọ̀ kú.” Àmọ́ kò sí ìkankan lára àwọn èèyàn náà tó dá a lóhùn. 40  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún gbogbo Ísírẹ́lì pé: “Ẹ̀yin, ẹ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, èmi àti Jónátánì ọmọ mi á wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì.” Ni àwọn èèyàn náà bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ṣe ohun tó bá dára ní ojú rẹ.” 41  Sọ́ọ̀lù wá sọ fún Jèhófà pé: “Ọlọ́run Ísírẹ́lì, fi Túmímù+ dáhùn!” Ni Túmímù bá mú Jónátánì àti Sọ́ọ̀lù, àwọn èèyàn náà sì bọ́. 42  Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ẹ ṣẹ́ kèké+ kí a lè mọ ẹni tó jẹ́ láàárín èmi àti Jónátánì ọmọ mi.” Túmímù sì mú Jónátánì. 43  Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Jónátánì pé: “Sọ fún mi, kí lo ṣe?” Jónátánì wá sọ fún un pé: “Mo kàn fi oyin díẹ̀ tó wà lórí ọ̀pá mi kan ẹnu ni o.+ Èmi rèé! Mo ṣe tán láti kú!” 44  Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Kí Ọlọ́run fi ìyà jẹ mí gan-an tó ò bá ní kú, Jónátánì.”+ 45  Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn náà sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ṣé ó yẹ kí Jónátánì kú, ẹni tó mú ìṣẹ́gun* ńlá+ wá fún Ísírẹ́lì? Kò ṣeé gbọ́ sétí! Bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹyọ kan nínú irun orí rẹ̀ kò ní bọ́ sílẹ̀, nítorí Ọlọ́run lọ́wọ́ sí gbogbo ohun tó ṣe lónìí yìí.”+ Bí àwọn èèyàn náà ṣe gba Jónátánì sílẹ̀* nìyẹn, kò sì kú. 46  Torí náà, Sọ́ọ̀lù dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn Filísínì, àwọn Filísínì sì lọ sí agbègbè wọn. 47  Sọ́ọ̀lù fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá rẹ̀ jà níbi gbogbo, ó bá àwọn ọmọ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì+ jà, ó tún bá àwọn ọmọ Édómù+ àti àwọn ọba Sóbà+ pẹ̀lú àwọn Filísínì+ jà; ó sì ń ṣẹ́gun níbikíbi tó bá lọ. 48  Ó fi ìgboyà jà, ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì,+ ó sì gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn tó ń kó ohun ìní wọn lọ. 49  Àwọn ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù ni Jónátánì, Íṣífì àti Maliki-ṣúà.+ Ó ní ọmọbìnrin méjì; èyí ẹ̀gbọ́n ń jẹ́ Mérábù,+ àbúrò rẹ̀ sì ń jẹ́ Míkálì.+ 50  Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ni Áhínóámù ọmọ Áhímáásì. Orúkọ olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ni Ábínérì+ ọmọ Nérì tó jẹ́ arákùnrin bàbá Sọ́ọ̀lù. 51  Kíṣì+ ni bàbá Sọ́ọ̀lù, Nérì+ bàbá Ábínérì sì ni ọmọ Ábíélì. 52  Ogun tó le ni àwọn Filísínì dojú kọ nígbà ayé Sọ́ọ̀lù.+ Tí Sọ́ọ̀lù bá sì rí ọkùnrin èyíkéyìí tó lágbára tàbí tó láyà, á gbà á síṣẹ́ ogun.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aláìkọlà.”
Ìyẹn, ìdajì oko tí màlúù méjì tí wọ́n so pọ̀ lè túlẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ kan.
Ní Héb., “ní ọjọ́ yẹn.”
Ní Héb., “Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Ní Héb., “Gbogbo ilẹ̀.”
Ní Héb., “ojú rẹ̀ tàn yanran.”
Ní Héb., “bí ojú mi ṣe tàn yanran.”
Tàbí “ìtanùlẹ́gbẹ́.”
Tàbí “ìgbàlà.”
Ní Héb., “ra Jónátánì pa dà.”