Sámúẹ́lì Kìíní 20:1-42

  • Bí Jónátánì ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Dáfídì (1-42)

20  Nígbà náà, Dáfídì sá kúrò ní Náótì ní Rámà. Àmọ́, ó wá sọ́dọ̀ Jónátánì, ó ní: “Kí ni mo ṣe?+ Ọ̀ràn wo ni mo dá, ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo sì ṣẹ bàbá rẹ tí ó fi ń wá ẹ̀mí* mi?”  Ni Jónátánì bá sọ fún un pé: “Kò ṣeé gbọ́ sétí!+ O ò ní kú. Wò ó! Bàbá mi ò ní ṣe ohunkóhun, ì báà jẹ́ kékeré tàbí ńlá láìsọ fún mi. Báwo ni bàbá mi á ṣe fi irú ọ̀rọ̀ yìí pa mọ́ fún mi? Kò jẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀.”  Ṣùgbọ́n Dáfídì fi kún un pé: “Bàbá rẹ mọ̀ dájú pé mo ti rí ojú rere rẹ,+ á sì sọ pé, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Jónátánì mọ̀, tó bá mọ̀, inú rẹ̀ á bà jẹ́.’ Àmọ́, bí Jèhófà ti wà láàyè, tí ìwọ náà* sì wà láàyè, ìṣísẹ̀ kan péré ló wà láàárín èmi àti ikú!”+  Ni Jónátánì bá sọ fún Dáfídì pé: “Ohunkóhun tí o* bá sọ ni màá ṣe fún ọ.”  Dáfídì wá sọ fún Jónátánì pé: “Ọ̀la ni òṣùpá tuntun,+ wọ́n á sì máa retí pé kí n jókòó pẹ̀lú ọba láti jẹun. Ní báyìí, jẹ́ kí n lọ fara pa mọ́ sínú pápá títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta.  Tí bàbá rẹ bá ṣàárò mi, kí o sọ fún un pé, ‘Dáfídì tọrọ àyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ sáré lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ìlú òun, torí pé ẹbọ ọdọọdún kan wà tí gbogbo ìdílé+ rẹ̀ máa rú níbẹ̀.’  Bí ó bá sọ pé, ‘Ó dára!’ á jẹ́ pé àlàáfíà wà fún ìránṣẹ́ rẹ. Ṣùgbọ́n bí ó bá bínú, kí o yáa mọ̀ pé ó ti pinnu láti ṣe mí ní jàǹbá.  Fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ,+ nítorí o ti bá ìránṣẹ́ rẹ dá májẹ̀mú níwájú Jèhófà.+ Àmọ́ tí mo bá jẹ̀bi,+ ìwọ fúnra rẹ ni kí o pa mí. Má wulẹ̀ fà mí lé bàbá rẹ lọ́wọ́.”  Jónátánì fèsì pé: “Má tiẹ̀ jẹ́ kí irú èrò bẹ́ẹ̀ wá sí ọ lọ́kàn! Tí mo bá gbọ́ pé bàbá mi fẹ́ ṣe ọ́ ní jàǹbá, ṣé mi ò ní sọ fún ọ ni?”+ 10  Dáfídì bá sọ fún Jónátánì pé: “Ta ló máa wá sọ fún mi bóyá ohùn líle ni bàbá rẹ fi dá ọ lóhùn?” 11  Jónátánì sọ fún Dáfídì pé: “Wá, jẹ́ ká lọ sínú pápá.” Torí náà, àwọn méjèèjì jáde lọ sí pápá. 12  Jónátánì sì sọ fún Dáfídì pé: “Kí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣe ẹlẹ́rìí pé màá bi bàbá mi léèrè ọ̀rọ̀ ní ìwòyí ọ̀la, tàbí ní ọ̀túnla. Tí inú rẹ̀ bá yọ́ sí Dáfídì, màá ránṣẹ́ sí ọ, màá sì jẹ́ kí o mọ ohun tó bá sọ. 13  Àmọ́ tí bàbá mi bá ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní jàǹbá, kí Jèhófà fìyà jẹ èmi Jónátánì gan-an, tí mi ò bá sọ fún ọ, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ,+ bí ó ṣe wà pẹ̀lú bàbá mi tẹ́lẹ̀.+ 14  Àbí, ṣé o ò ní fi ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ hàn sí mi nígbà tí mo ṣì wà láàyè àti nígbà tí mo bá kú?+ 15  Má ṣe dáwọ́ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí agbo ilé mi dúró,+ kódà nígbà tí Jèhófà bá gbá gbogbo àwọn ọ̀tá Dáfídì kúrò lórí ilẹ̀.” 16  Torí náà, Jónátánì bá ilé Dáfídì dá májẹ̀mú, ó ní, “Jèhófà yóò béèrè, yóò sì pe àwọn ọ̀tá Dáfídì wá jíhìn.” 17  Torí náà, Jónátánì ní kí Dáfídì tún búra nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí i, nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara* rẹ̀.+ 18  Jónátánì wá sọ fún un pé: “Ọ̀la ni òṣùpá tuntun,+ àárò rẹ á sọ wá, torí pé ìjókòó rẹ máa ṣófo. 19  Tó bá fi máa di ọjọ́ kẹta, àárò rẹ á ti máa sọ wá gan-an, kí o wá sí ibi tí o fara pa mọ́ sí lọ́jọ́sí,* kí o sì dúró sí tòsí òkúta tó wà níbí yìí. 20  Màá wá ta ọfà mẹ́ta sí apá ibì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bíi pé nǹkan kan wà tí mo fẹ́ ta ọfà sí. 21  Nígbà tí mo bá rán ìránṣẹ́ mi, màá sọ fún un pé, ‘Lọ wá àwọn ọfà náà.’ Tí mo bá sọ fún ìránṣẹ́ náà pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà nìyẹn lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, kó wọn,’ nígbà náà, bí Jèhófà ti wà láàyè, o lè pa dà wá torí pé ó túmọ̀ sí àlàáfíà fún ọ, kò sì séwu. 22  Ṣùgbọ́n tí mo bá sọ fún ọmọkùnrin náà pé, ‘Wò ó! Àwọn ọfà náà ṣì wà níwájú,’ nígbà náà, kí o máa lọ, nítorí pé Jèhófà fẹ́ kí o lọ. 23  Ní ti ìlérí tí èmi àti ìwọ jọ ṣe,+ kí Jèhófà wà láàárín wa títí láé.”+ 24  Torí náà, Dáfídì fara pa mọ́ sí pápá. Nígbà tí òṣùpá tuntun yọ, ọba jókòó sí àyè rẹ̀ nídìí oúnjẹ láti jẹun.+ 25  Ọba jókòó síbi tó máa ń jókòó sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Jónátánì dojú kọ ọ́, Ábínérì+ sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Sọ́ọ̀lù, àmọ́ àyè Dáfídì ṣófo. 26  Sọ́ọ̀lù kò sọ ohunkóhun lọ́jọ́ yẹn, torí ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ tó sọ ọ́ di aláìmọ́.+ Ó dájú pé kò mọ́ ni.’ 27  Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé òṣùpá tuntun, ìyẹn lọ́jọ́ kejì, àyè Dáfídì ṣì ṣófo. Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Jónátánì ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí ọmọ Jésè+ kò fi wá síbi oúnjẹ lánàá àti lónìí?” 28  Jónátánì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Dáfídì tọrọ àyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 29  Ó sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ, torí pé a ní ẹbọ ìdílé tí a fẹ́ rú ní ìlú náà, ẹ̀gbọ́n mi ló sì pè mí. Nítorí náà, tí mo bá rí ojú rere rẹ, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sáré lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nìyẹn tí kò fi wá síbi tábìlì ọba.” 30  Nígbà náà, Sọ́ọ̀lù bínú gan-an sí Jónátánì, ó sì sọ fún un pé: “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ obìnrin, ṣé o rò pé mi ò mọ̀ pé ò ń gbè sẹ́yìn ọmọ Jésè ni, tó sì máa já sí ìtìjú fún ìwọ àti ìyá rẹ?* 31  Ní gbogbo ìgbà tí ọmọ Jésè bá fi wà láàyè lórí ilẹ̀, ìwọ àti ipò ọba rẹ kò ní lè fìdí múlẹ̀.+ Ní báyìí, ní kí wọ́n lọ mú un wá fún mi, nítorí pé ó gbọ́dọ̀ kú.”*+ 32  Àmọ́, Jónátánì sọ fún Sọ́ọ̀lù bàbá rẹ̀ pé: “Kí nìdí tí wọ́n á fi pa á?+ Kí ló ṣe?” 33  Ni Sọ́ọ̀lù bá ju ọ̀kọ̀ sí i láti fi gún un,+ Jónátánì sì wá mọ̀ pé bàbá òun ti pinnu láti pa Dáfídì.+ 34  Lójú ẹsẹ̀, Jónátánì bínú dìde kúrò nídìí tábìlì náà, kò sì jẹ oúnjẹ kankan ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn òṣùpá tuntun, torí inú rẹ̀ bà jẹ́ nítorí Dáfídì+ àti pé bàbá rẹ̀ ti fi àbùkù kàn án. 35  Nígbà tó di àárọ̀, Jónátánì jáde lọ sí pápá nítorí àdéhùn òun àti Dáfídì, ìránṣẹ́ kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 36  Ó wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, sáré lọ wá àwọn ọfà tí mo bá ta.” Ìránṣẹ́ náà bá sáré, Jónátánì sì ta ọfà náà kọjá rẹ̀. 37  Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé ibi tí Jónátánì ta ọfà náà sí, Jónátánì pe ìránṣẹ́ náà, ó ní: “Ọfà náà ṣì wà níwájú!” 38  Jónátánì bá pe ìránṣẹ́ náà pé: “Tètè lọ! Ṣe kíá! Má ṣe jáfara!” Ìránṣẹ́ Jónátánì ṣa àwọn ọfà náà, ó sì pa dà sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. 39  Ìránṣẹ́ náà kò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀; Jónátánì àti Dáfídì nìkan ló mọ ohun tó túmọ̀ sí. 40  Lẹ́yìn náà, Jónátánì kó àwọn ohun ìjà rẹ̀ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Gbà, kó wọn lọ sínú ìlú.” 41  Nígbà tí ìránṣẹ́ náà lọ, Dáfídì dìde láti ibì kan tó wà nítòsí lápá gúúsù. Ó wá kúnlẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ nígbà mẹ́ta, wọ́n fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì sunkún fún ara wọn, àmọ́ Dáfídì ló sunkún jù. 42  Jónátánì sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ ní àlàáfíà, nítorí àwa méjèèjì ti fi orúkọ Jèhófà búra+ pé, ‘Kí Jèhófà wà láàárín èmi àti ìwọ àti láàárín àwọn ọmọ* mi àti àwọn ọmọ* rẹ títí láé.’”+ Dáfídì bá dìde, ó sì lọ, Jónátánì wá pa dà sínú ìlú.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn rẹ.”
Tàbí “ọkàn ara.”
Ní Héb., “ní ọjọ́ iṣẹ́.”
Ní Héb., “ìhòòhò ìyá rẹ?”
Ní Héb., “nítorí pé ọmọ ikú ni.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “èso.”