Sámúẹ́lì Kìíní 6:1-21

  • Àwọn Filísínì dá Àpótí náà pa dà sí Ísírẹ́lì (1-21)

6  Oṣù méje ni Àpótí+ Jèhófà fi wà ní ìpínlẹ̀ àwọn Filísínì.  Àwọn Filísínì pe àwọn àlùfáà àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ wọ́n béèrè pé: “Kí ni ká ṣe sí Àpótí Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká mọ bí a ṣe máa dá a pa dà sí àyè rẹ̀.”  Wọ́n fèsì pé: “Bí ẹ bá máa dá àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa dà, ẹ má ṣe dá a pa dà láìsí ọrẹ. Ẹ gbọ́dọ̀ dá a pa dà pẹ̀lú ọrẹ ẹ̀bi.+ Ìgbà yẹn ni ara yín máa tó yá, tí ẹ sì máa mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ ṣì fi le mọ́ yín.”  Ni wọ́n bá béèrè pé: “Ọrẹ ẹ̀bi wo ni ká fi ránṣẹ́ sí i?” Wọ́n sọ pé: “Ẹ fi jẹ̀díjẹ̀dí* wúrà márùn-ún àti eku wúrà márùn-ún ránṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn alákòóso Filísínì,+ nítorí irú àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọ lu ẹnì kọ̀ọ̀kan yín àti àwọn alákòóso yín.  Ẹ ṣe àwọn ère jẹ̀díjẹ̀dí yín àti àwọn ère eku yín+ tó ń pa ilẹ̀ náà run, kí ẹ sì bọlá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Bóyá ó lè dẹ ọwọ́ rẹ̀ lára yín, lára ọlọ́run yín àti ilẹ̀ yín.+  Kí nìdí tí ẹ ó fi mú kí ọkàn yín le bí Íjíbítì àti Fáráò ṣe mú kí ọkàn wọn le?+ Nígbà tí Ọlọ́run fìyà jẹ wọ́n,+ ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí Ísírẹ́lì máa lọ, wọ́n sì lọ.+  Ní báyìí, ẹ ṣètò kẹ̀kẹ́ tuntun kan àti abo màlúù méjì tó ní ọmọ, tí a kò ti àjàgà bọ̀ lọ́rùn rí. Kí ẹ wá so àwọn abo màlúù náà mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, àmọ́ kí ẹ kó àwọn ọmọ màlúù náà kúrò lọ́dọ̀ wọn pa dà sílé.  Ẹ gbé Àpótí Jèhófà sórí kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì kó àwọn ère wúrà tí ẹ fẹ́ fi ránṣẹ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi sínú àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.+ Kí ẹ wá rán an lọ,  kí ẹ sì máa wò ó: Tó bá jẹ́ pé ọ̀nà Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ ló lọ, ní ìpínlẹ̀ rẹ̀, á jẹ́ pé Ọlọ́run wọn ló fa ibi ńlá tó bá wa yìí. Àmọ́ tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a ó mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ló kọ lù wá; ó kàn ṣèèṣì wáyé bẹ́ẹ̀ ni.” 10  Àwọn ọkùnrin náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Wọ́n mú abo màlúù méjì tó ní ọmọ, wọ́n sì so wọ́n mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n kó àwọn ọmọ wọn sínú ọgbà ẹran nílé. 11  Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé Àpótí Jèhófà sórí kẹ̀kẹ́ náà àti àpótí tí àwọn eku wúrà àti àwọn ère jẹ̀díjẹ̀dí wọn wà nínú rẹ̀. 12  Àwọn abo màlúù náà lọ tààràtà sí ọ̀nà Bẹti-ṣémẹ́ṣì.+ Ojú ọ̀nà ni wọ́n ń gbà lọ, tí wọ́n ń ké mùúù bí wọ́n ṣe ń lọ; wọn ò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn alákòóso Filísínì ń rìn tẹ̀ lé wọn títí dé ààlà Bẹti-ṣémẹ́ṣì. 13  Àwọn èèyàn Bẹti-ṣémẹ́ṣì ń kórè àlìkámà* ní àfonífojì.* Nígbà tí wọ́n gbójú sókè, tí wọ́n rí Àpótí náà, inú wọn dùn gan-an bí wọ́n ṣe rí i. 14  Kẹ̀kẹ́ náà wọnú pápá Jóṣúà ará Bẹti-ṣémẹ́ṣì, ó sì dúró síbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkúta ńlá kan. Wọ́n wá la igi kẹ̀kẹ́ náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì fi àwọn abo màlúù+ náà rú ẹbọ sísun sí Jèhófà. 15  Àwọn ọmọ Léfì+ sọ Àpótí Jèhófà kalẹ̀ àti àpótí tó wà pẹ̀lú rẹ̀, èyí tí àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà ṣe wà nínú rẹ̀, wọ́n sì gbé wọn sórí òkúta ńlá náà. Àwọn ọkùnrin Bẹti-ṣémẹ́ṣì+ rú àwọn ẹbọ sísun, wọ́n sì tún rú àwọn ẹbọ sí Jèhófà ní ọjọ́ yẹn. 16  Nígbà tí àwọn alákòóso Filísínì márààrún rí i, wọ́n pa dà sí Ẹ́kírónì ní ọjọ́ yẹn. 17  Àwọn jẹ̀díjẹ̀dí wúrà tí àwọn Filísínì fi ránṣẹ́ láti fi ṣe ọrẹ ẹ̀bi fún Jèhófà nìyí:+ ọ̀kan fún Áṣídódì,+ ọ̀kan fún Gásà, ọ̀kan fún Áṣíkẹ́lónì, ọ̀kan fún Gátì,+ ọ̀kan fún Ẹ́kírónì.+ 18  Iye àwọn eku wúrà náà jẹ́ iye gbogbo àwọn ìlú Filísínì tí wọ́n jẹ́ ti àwọn alákòóso márààrún, ìyẹn àwọn ìlú olódi àti àwọn abúlé tó wà ní ìgbèríko. Òkúta ńlá tí wọ́n gbé Àpótí Jèhófà lé sì jẹ́ ẹ̀rí títí di òní yìí ní pápá Jóṣúà ará Bẹti-ṣémẹ́ṣì. 19  Àmọ́ Ọlọ́run pa àwọn ọkùnrin Bẹti-ṣémẹ́ṣì, torí pé wọ́n wo Àpótí Jèhófà. Ó pa ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta ó lé àádọ́rin (50,070)* lára àwọn èèyàn náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀fọ̀ nítorí pé Jèhófà ti pa wọ́n lọ rẹpẹtẹ.+ 20  Torí náà, àwọn èèyàn Bẹti-ṣémẹ́ṣì béèrè pé: “Ta ló lè dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run mímọ́ yìí,+ ọ̀dọ̀ ta ló sì máa lọ tí á fi kúrò lọ́dọ̀ wa?”+ 21  Ìgbà náà ni wọ́n rán àwọn òjíṣẹ́ sí àwọn tó ń gbé ní Kiriati-jéárímù+ pé: “Àwọn Filísínì ti dá Àpótí Jèhófà pa dà o. Ẹ wá gbé e lọ sọ́dọ̀ yín.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìdí yíyọ.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ní Héb., “àwọn 70 ọkùnrin àti àwọn 50,000 ọkùnrin.”