Sámúẹ́lì Kìíní 2:1-36

  • Àdúrà Hánà (1-11)

  • Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Élì méjèèjì (12-26)

  • Jèhófà dá ilé Élì lẹ́jọ́ (27-36)

2  Nígbà náà, Hánà gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ nínú Jèhófà;+Jèhófà ti fún mi lágbára.* Ẹnu mi gbọ̀rọ̀ lójú àwọn ọ̀tá mi,Nítorí àwọn iṣẹ́ ìgbàlà rẹ ń mú inú mi dùn.   Kò sí ẹni tí ó mọ́ bíi Jèhófà,Kò sí ẹlòmíràn, àfi ìwọ,+Kò sì sí àpáta tí ó dà bí Ọlọ́run wa.+   Ẹ má ṣe máa fọ́nnu;Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìgbéraga ti ẹnu yín jáde,Nítorí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìmọ̀,+Òun sì ni ó ń ṣàyẹ̀wò nǹkan lọ́nà tó tọ́.   Ọfà* àwọn alágbára ọkùnrin ti ṣẹ́ sí wẹ́wẹ́,Ṣùgbọ́n àwọn tó ń kọsẹ̀ ni a ti fún ní agbára.+   Àwọn tó ń jẹ àjẹyó á fi ara wọn ṣe alágbàṣe nítorí oúnjẹ,Àmọ́ ebi ò ní pa àwọn tí ebi ń pa mọ́.+ Ẹni tó ya àgàn ti bímọ méje,+Àmọ́ ẹni tó ní ọmọ púpọ̀ ti wá di aláìlọ́mọ.*   Jèhófà ń pani, ó sì ń dá ẹ̀mí ẹni sí;*Ó múni sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú,* ó sì ń gbéni dìde.+   Jèhófà ń sọni di aláìní, ó sì ń sọni di ọlọ́rọ̀;+Ó ń rẹni wálẹ̀, ó sì ń gbéni ga.+   Ó ń gbé aláìní dìde látinú eruku; Ó ń gbé tálákà dìde látinú eérú,*+Láti mú kí wọ́n jókòó pẹ̀lú àwọn olórí,Ó fún wọn ní ìjókòó iyì. Ti Jèhófà ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé,+Ó sì gbé ilẹ̀ tó ń mú èso jáde ka orí wọn.   Ó ń dáàbò bo ìṣísẹ̀ àwọn adúróṣinṣin rẹ̀,+Ṣùgbọ́n a ó pa àwọn ẹni burúkú lẹ́nu mọ́ nínú òkùnkùn,+Nítorí kì í ṣe nípa agbára ni èèyàn fi ń borí.+ 10  Jèhófà yóò fọ́ àwọn tó ń bá a jà sí wẹ́wẹ́;*+Yóò sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run.+ Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ títí dé gbogbo ìkángun ayé,+Yóò fún ọba rẹ̀ ní agbára+Yóò sì gbé ìwo* ẹni àmì òróró rẹ̀ ga.”+ 11  Ìgbà náà ni Ẹlikénà lọ sí ilé rẹ̀ ní Rámà, àmọ́ ọmọdékùnrin náà di òjíṣẹ́* Jèhófà+ níwájú àlùfáà Élì. 12  Àwọn ọmọkùnrin Élì jẹ́ èèyàn burúkú;+ wọn ò ka Jèhófà sí. 13  Ohun tí wọ́n ń ṣe sí ìpín tó tọ́ sí àwọn àlùfáà látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn nìyí:+ Nígbàkigbà tí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń rú ẹbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà máa wá pẹ̀lú àmúga oníga mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, nígbà tí ẹran náà ṣì ń hó lórí iná, 14  á sì tì í bọ inú agbada tàbí ìkòkò oníga méjì tàbí ìkòkò irin tàbí ìkòkò oníga kan. Ohunkóhun tí àmúga náà bá mú wá sókè ni àlùfáà yóò mú. Bí wọ́n ṣe ń ṣe nìyẹn ní Ṣílò sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń wá síbẹ̀. 15  Bákan náà, kí ọkùnrin tó ń rú ẹbọ tó mú ọ̀rá rú èéfín rárá,+ ìránṣẹ́ àlùfáà máa wá, á sì sọ fún un pé: “Fún àlùfáà ní ẹran tó máa yan. Kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ rẹ, àfi ẹran tútù.” 16  Nígbà tí ọkùnrin náà bá sọ fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ mú ọ̀rá rú èéfín ná,+ lẹ́yìn ìyẹn, kí o mú ohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́.”* Àmọ́ á sọ pé: “Rárá, fún mi báyìí-báyìí; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá mú un tipátipá!” 17  Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ náà wá pọ̀ gan-an níwájú Jèhófà,+ nítorí àwọn ọkùnrin náà hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọrẹ Jèhófà. 18  Sámúẹ́lì sì ń ṣe ìránṣẹ́+ níwájú Jèhófà, ó wọ* éfódì tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀*+ ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọdékùnrin ni. 19  Bákan náà, ìyá rẹ̀ máa ń dá aṣọ àwọ̀lékè kékeré tí kò lápá fún un, a sì mú un wá fún un lọ́dọọdún nígbà tí òun àti ọkọ rẹ̀ bá wá láti rú ẹbọ ọdọọdún.+ 20  Élì súre fún Ẹlikénà àti ìyàwó rẹ̀, ó sọ pé: “Kí Jèhófà fún ọ ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó yìí kí ó lè dípò èyí tí ẹ fún Jèhófà.”+ Wọ́n sì pa dà lọ sílé. 21  Jèhófà ṣíjú àánú wo Hánà, ó wá lóyún,+ ó sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta sí i àti ọmọbìnrin méjì. Ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì sì ń dàgbà níwájú Jèhófà.+ 22  Élì ti darúgbó gan-an, àmọ́ ó ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe+ sí gbogbo Ísírẹ́lì àti bí wọ́n ṣe ń bá àwọn obìnrin tó ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé sùn.+ 23  Ó sì máa ń sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí? Ohun tí mò ń gbọ́ nípa yín látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn kò dáa. 24  Kò dáa bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ọmọ mi, ìròyìn tí mò ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ láàárín àwọn èèyàn Jèhófà kò dáa. 25  Bí èèyàn bá ṣẹ èèyàn bíi tirẹ̀, ẹnì kan lè bá a bẹ Jèhófà;* àmọ́ tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni èèyàn ṣẹ̀,+ ta ló máa gbàdúrà fún un?” Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sí bàbá wọn, nítorí pé Jèhófà ti pinnu láti pa wọ́n.+ 26  Ní gbogbo àkókò yìí, ọmọdékùnrin náà Sámúẹ́lì ń dàgbà sí i, ó sì túbọ̀ ń rí ojú rere Jèhófà àti ti àwọn èèyàn.+ 27  Èèyàn Ọlọ́run kan wá sọ́dọ̀ Élì, ó sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ǹjẹ́ mi ò fara han ilé baba rẹ nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì, tí wọ́n jẹ́ ẹrú ní ilé Fáráò?+ 28  Mo sì yàn án nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì+ láti ṣe àlùfáà fún mi, kó máa gòkè lọ sórí pẹpẹ mi+ láti rú ẹbọ, kó máa sun tùràrí,* kó sì máa wọ éfódì níwájú mi. Mo sì fún ilé baba ńlá rẹ ní gbogbo àwọn ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* fi iná sun.+ 29  Kí ló dé tí ẹ kò ka ẹbọ mi sí* àti ọrẹ mi tí mo pa láṣẹ ní ibùgbé mi?+ Kí ló dé tí ò ń bọlá fún àwọn ọmọkùnrin rẹ jù mí lọ, tí ẹ̀ ń fi apá tó dára jù lọ lára gbogbo ọrẹ àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bọ́ ara yín sanra?+ 30  “‘Ìdí nìyẹn tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì fi sọ pé: “Lóòótọ́, mo sọ pé ilé rẹ àti ilé baba ńlá rẹ yóò máa sìn níwájú mi nígbà gbogbo.”+ Ṣùgbọ́n ní báyìí, Jèhófà sọ pé: “Kò ní rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tó ń bọlá fún mi ni màá bọlá fún,+ àmọ́ màá kórìíra àwọn tí kò kà mí sí.” 31  Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀ tí màá gba agbára rẹ* àti ti ilé baba rẹ, tí ẹnì kankan nínú ilé rẹ kò fi ní dàgbà.+ 32  Bí mo ti ń ṣe rere fún Ísírẹ́lì, alátakò ni wàá máa rí nínú ibùgbé mi,+ kò tún ní sí ẹni tó máa dàgbà nínú ilé rẹ mọ́ láé. 33  Èèyàn rẹ tí mi ò mú kúrò lẹ́nu sísìn níbi pẹpẹ mi yóò mú kí ojú rẹ di bàìbàì, yóò sì kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ,* idà àwọn èèyàn ló máa pa èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará ilé rẹ.+ 34  Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì yóò jẹ́ àmì fún ọ: Ọjọ́ kan náà ni àwọn méjèèjì máa kú.+ 35  Nígbà náà, màá yan àlùfáà olóòótọ́ kan fún ara mi.+ Ohun tí ọkàn mi bá fẹ́ ni á sì máa ṣe; màá kọ́ ilé kan tó máa wà pẹ́ títí fún un, á sì máa sìn níwájú ẹni àmì òróró mi nígbà gbogbo. 36  Ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ́ kù nínú ilé rẹ yóò wá, yóò sì tẹrí ba fún un, yóò bẹ̀ ẹ́ pé kó fún òun ní iṣẹ́, kó lè rí owó díẹ̀ àti ìṣù búrẹ́dì, yóò sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, fi mí sí ìdí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí n lè máa rí búrẹ́dì jẹ.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “Jèhófà ti gbé ìwo mi ga.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Ní Héb., “Ọrun.”
Ní Héb., “ti rọ dà nù.”
Tàbí “sọni di alààyè.”
Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “ààtàn.”
Tàbí “agbára.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀rù yóò ba àwọn tó ń bá Jèhófà jà.”
Tàbí “ń sin.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ bá fà sí.”
Ní Héb., “sán.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí kó jẹ́, “Ọlọ́run lè parí ìjà fún un.”
Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí kó jẹ́, “láti mú ẹbọ rú èéfín tùù sókè.”
Ní Héb., “tàpá sí ẹbọ mi.”
Ní Héb., “gé apá rẹ kúrò.”
Tàbí “mú kí ọkàn rẹ ṣàárẹ̀.”