Sámúẹ́lì Kìíní 9:1-27

  • Sámúẹ́lì pàdé Sọ́ọ̀lù (1-27)

9  Ọkùnrin ará Bẹ́ńjámínì kan wà tó ń jẹ́ Kíṣì,+ ọmọ Ábíélì, ọmọ Sérórì, ọmọ Békórátì, ọmọ Áfíà, ọmọ ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì,+ ó ní ọrọ̀ gan-an.  Ó ní ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù,+ ọ̀dọ́ ni, ó sì rẹwà, kò sí ọkùnrin kankan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rẹwà tó o; tí ó bá dúró, kò sí ẹnì kankan lára àwọn èèyàn náà tó ga dé èjìká rẹ̀.  Nígbà tí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* Kíṣì bàbá Sọ́ọ̀lù sọ nù, Kíṣì sọ fún Sọ́ọ̀lù ọmọ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, mú ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ dání, kí o sì lọ wá àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”  Ni wọ́n bá gba agbègbè olókè Éfúrémù kọjá àti ilẹ̀ Ṣálíṣà, àmọ́ wọn ò rí wọn. Wọ́n rin ìrìn àjò dé ilẹ̀ Ṣáálímù, àmọ́ àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ò sí níbẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ni wọ́n dé, síbẹ̀ wọn ò rí wọn.  Wọ́n dé ilẹ̀ Súfì, Sọ́ọ̀lù wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Wá, jẹ́ ká pa dà, kí bàbá mi má bàa bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú nípa wa dípò àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.”+  Àmọ́ ìránṣẹ́ náà fèsì pé: “Wò ó, èèyàn Ọlọ́run kan wà ní ìlú yìí, ẹni iyì sì ni ọkùnrin náà. Gbogbo ohun tó bá sọ ló dájú pé á ṣẹ.+ Jẹ́ ká lọ síbẹ̀ báyìí. Bóyá ó lè sọ ibi tí a máa wá wọn sí fún wa.”  Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Tí a bá máa lọ, kí ni a máa fún ọkùnrin náà? Kò sí oúnjẹ kankan nínú àpò wa; kò sí ẹ̀bùn kankan tí a lé lọ fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Kí la ní lọ́wọ́?”  Ìránṣẹ́ náà tún dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Wò ó! Ìdá mẹ́rin ṣékélì* fàdákà wà lọ́wọ́ mi. Màá fún èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà, yóò sì sọ ibi tí a máa wá wọn sí fún wa.”  (Láyé àtijọ́ ní Ísírẹ́lì, ohun tí ẹni tó bá fẹ́ wá Ọlọ́run máa sọ nìyí: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sọ́dọ̀ aríran.”+ Nítorí àwọn tí wọ́n ń pè ní aríran láyé àtijọ́ ni à ń pè ní wòlíì lóde òní.) 10  Sọ́ọ̀lù wá sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ dára. Jẹ́ ká lọ.” Torí náà, wọ́n lọ sí ìlú tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ náà wà. 11  Bí wọ́n ṣe ń gòkè lọ sí ìlú náà, wọ́n pàdé àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n fẹ́ lọ pọn omi. Torí náà, wọ́n béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ṣé aríran+ wà ní ibí yìí?” 12  Wọ́n ní: “Ó wà níbí. Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn-ún yẹn níwájú yín. Ẹ ṣe kíá, torí pé ó wà ní ìlú yìí lónìí, nítorí àwọn èèyàn máa rú ẹbọ+ lónìí ní ibi gíga.+ 13  Gbàrà tí ẹ bá ti wọ ìlú náà, ẹ máa rí i kó tó gòkè lọ sí ibi gíga láti jẹun. Àwọn èèyàn náà kò ní jẹun títí á fi dé, nítorí òun ló máa gbàdúrà* sí ẹbọ náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àwọn tí a pè tó lè jẹun. Torí náà, ẹ tètè gòkè lọ, ẹ máa rí i.” 14  Ni wọ́n bá gòkè lọ sí ìlú náà. Bí wọ́n ṣe ń dé àárín ìlú náà, Sámúẹ́lì rèé tó ń bọ̀ wá pàdé wọn láti gòkè lọ sí ibi gíga. 15  Ní ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Sọ́ọ̀lù dé, Jèhófà ti sọ fún Sámúẹ́lì* pé: 16  “Ní ìwòyí ọ̀la, màá rán ọkùnrin kan láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì sí ọ.+ Kí o fòróró yàn án ṣe aṣáájú lórí àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ yóò sì gba àwọn èèyàn mi lọ́wọ́ àwọn Filísínì. Nítorí mo ti rí ìpọ́njú àwọn èèyàn mi, igbe ẹkún wọn sì ti dé ọ̀dọ̀ mi.”+ 17  Nígbà tí Sámúẹ́lì rí Sọ́ọ̀lù, Jèhófà sọ fún un pé: “Ọkùnrin tí mo sọ nípa rẹ̀ fún ọ nìyí pé, ‘Òun ló máa ṣàkóso àwọn èèyàn mi.’”*+ 18  Ìgbà náà ni Sọ́ọ̀lù sún mọ́ Sámúẹ́lì ní àárín ẹnubodè, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún mi, ibo ni ilé aríran wà?” 19  Sámúẹ́lì dá Sọ́ọ̀lù lóhùn pé: “Èmi ni aríran náà. Máa gòkè lọ níwájú mi sí ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí.+ Màá jẹ́ kí ẹ máa lọ láàárọ̀ ọ̀la, màá sì sọ gbogbo ohun tí o fẹ́ mọ̀* fún ọ. 20  Ní ti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó sọ nù lọ́jọ́ mẹ́ta sẹ́yìn,+ má dààmú nípa wọn, nítorí wọ́n ti rí wọn. Ó ṣe tán, ta ló ni gbogbo ohun tó ṣeyebíye ní Ísírẹ́lì? Ǹjẹ́ kì í ṣe ìwọ àti gbogbo ilé bàbá rẹ ni?”+ 21  Ni Sọ́ọ̀lù bá dáhùn pé: “Ṣebí ọmọ Bẹ́ńjámínì tó kéré jù nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni mí,+ tó sì jẹ́ pé ìdílé mi kò já mọ́ nǹkan kan láàárín gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Torí náà, kí nìdí tí o fi bá mi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?” 22  Lẹ́yìn náà, Sámúẹ́lì mú Sọ́ọ̀lù àti ìránṣẹ́ rẹ̀ wá sí gbọ̀ngàn ìjẹun, ó fi wọ́n sí àyè tó ṣe pàtàkì jù láàárín àwọn tí a pè. Nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọkùnrin ni wọ́n. 23  Sámúẹ́lì sọ fún alásè pé: “Mú ìpín tí mo fún ọ wá, èyí tí mo sọ fún ọ pé, ‘Fi í pa mọ́.’” 24  Ni alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ẹran àti àwọn ohun tó wà lórí rẹ̀ síwájú Sọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì sì sọ pé: “Ohun tí a tọ́jú dè ọ́ ló wà níwájú rẹ yìí. Jẹ ẹ́, nítorí àkókò pàtàkì yìí ni wọ́n ṣe tọ́jú rẹ̀ dè ọ́. Mo ti sọ fún wọn pé, ‘mò ń retí àwọn àlejò.’” Torí náà, Sọ́ọ̀lù bá Sámúẹ́lì jẹun ní ọjọ́ yẹn. 25  Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ̀ kalẹ̀ láti ibi gíga+ lọ sí ìlú náà, ó sì ń bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ní orí ilé. 26  Wọ́n dìde ní kùtùkùtù, nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Sámúẹ́lì pe Sọ́ọ̀lù ní orí ilé pé: “Múra, kí n lè sìn ọ́ dé ọ̀nà.” Torí náà, Sọ́ọ̀lù múra, òun àti Sámúẹ́lì sì jáde síta. 27  Bí wọ́n ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ẹ̀yìn ìlú náà, Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Sọ fún ìránṣẹ́+ yìí pé kó kọjá síwájú wa,” torí náà, ó lọ síwájú. “Àmọ́ ìwọ, dúró sí ibí yìí, kí n lè sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”
Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.
Ní Héb., “súre.”
Ní Héb., “ṣí Sámúẹ́lì létí.”
Tàbí “ṣèkáwọ́ àwọn èèyàn mi.”
Ní Héb., “gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ.”