Sámúẹ́lì Kìíní 26:1-25

  • Dáfídì tún dá ẹ̀mí Sọ́ọ̀lù sí (1-25)

    • Dáfídì bọ̀wọ̀ fún ẹni àmì òróró Jèhófà (11)

26  Nígbà tó yá, àwọn ọkùnrin Sífù+ wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù ní Gíbíà,+ wọ́n sọ pé: “Dáfídì fara pa mọ́ sórí òkè Hákílà tó dojú kọ Jéṣímónì.”*+  Sọ́ọ̀lù bá dìde, òun àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àṣàyàn ọkùnrin ní Ísírẹ́lì sì lọ sí aginjù Sífù láti wá Dáfídì nínú aginjù náà.+  Sọ́ọ̀lù pàgọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà lórí òkè Hákílà tó dojú kọ Jéṣímónì. Nígbà náà, Dáfídì ń gbé ní aginjù, ó sì gbọ́ pé Sọ́ọ̀lù ti wá òun wá sínú aginjù náà.  Torí náà, Dáfídì rán àwọn amí kí wọ́n lè lọ wò ó bóyá Sọ́ọ̀lù ti wá lóòótọ́.  Lẹ́yìn náà, Dáfídì lọ sí ibi tí Sọ́ọ̀lù pàgọ́ sí, Dáfídì sì rí ibi tí Sọ́ọ̀lù àti Ábínérì+ ọmọ Nérì olórí ọmọ ogun rẹ̀ sùn sí; Sọ́ọ̀lù sùn sílẹ̀ ní gbàgede ibùdó pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tó dó yí i ká.  Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún Áhímélékì ọmọ Hétì+ àti Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà,+ ẹ̀gbọ́n Jóábù pé: “Ta ló máa tẹ̀ lé mi lọ sí ibùdó lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù?” Ábíṣáì fèsì pé: “Màá tẹ̀ lé ọ.”  Ni Dáfídì àti Ábíṣáì bá lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà lóru, wọ́n sì rí Sọ́ọ̀lù tó sùn sílẹ̀ ní gbàgede ibùdó, tó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ síbi orí rẹ̀; Ábínérì àti àwọn ọmọ ogun sì sùn yí i ká.  Ábíṣáì wá sọ fún Dáfídì pé: “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí.+ Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan péré, mi ò ní ṣe é lẹ́ẹ̀mejì.”  Àmọ́, Dáfídì sọ fún Ábíṣáì pé: “Má ṣe é ní jàǹbá, ṣé ẹnì kan lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà,+ kó má sì jẹ̀bi?”+ 10  Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa mú un balẹ̀,+ ó sì lè kú lọ́jọ́ kan+ tàbí kó lọ sójú ogun kó sì kú síbẹ̀.+ 11  Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo gbé ọwọ́ mi sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà!+ Ní báyìí, jọ̀wọ́ jẹ́ ká mú ọ̀kọ̀ àti ìgò omi tó wà níbi orí rẹ̀, kí a sì máa bá tiwa lọ.” 12  Torí náà, Dáfídì mú ọ̀kọ̀ àti ìgò omi tó wà níbi orí Sọ́ọ̀lù, wọ́n sì lọ. Kò sí ẹni tó rí wọn,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹnì kankan ò kíyè sí wọn, kò tiẹ̀ sí ẹni tó jí, gbogbo wọn ti sùn lọ, nítorí oorun àsùnwọra láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ó kùn wọ́n. 13  Ìgbà náà ni Dáfídì sọdá sí òdìkejì, ó dúró sórí òkè ní òkèèrè, àyè tó wà láàárín wọn sì pọ̀ gan-an. 14  Dáfídì nahùn pe àwọn ọmọ ogun náà àti Ábínérì+ ọmọ Nérì, ó ní: “Ábínérì, ṣé o ò ní dáhùn ni?” Ábínérì dáhùn pé: “Ìwọ ta ló ń pe ọba?” 15  Dáfídì sọ fún Ábínérì pé: “Ṣebí ọkùnrin ni ọ́? Ta sì ni ó dà bí rẹ ní Ísírẹ́lì? Kí wá nìdí tó ò fi máa ṣọ́ olúwa rẹ ọba? Torí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun wọlé wá láti pa olúwa rẹ ọba.+ 16  Ohun tí o ṣe yìí kò dára. Bí Jèhófà ti wà láàyè, ikú tọ́ sí yín, torí ẹ ò ṣọ́ olúwa yín, ẹni àmì òróró Jèhófà.+ Ní báyìí, ẹ wò yí ká! Ibo ni ọ̀kọ̀ ọba àti ìgò omi+ tó wà níbi orí rẹ̀ wà?” 17  Sọ́ọ̀lù wá mọ̀ pé ohùn Dáfídì ni, ó sọ pé: “Ṣé ohùn rẹ nìyí, Dáfídì ọmọ mi?”+ Dáfídì fèsì pé: “Ohùn mi ni, olúwa mi ọba.” 18  Ó tún sọ pé: “Kí ló dé tí olúwa mi fi ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀,+ kí ni mo ṣe, kí sì ni ẹ̀bi mi?+ 19  Kí olúwa mi ọba jọ̀wọ́ fetí sí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀: Tó bá jẹ́ pé Jèhófà ni ó fi sí ọ lọ́kàn láti máa lépa mi, kí ó gba* ọrẹ ọkà mi. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn ló fi sí ọ lọ́kàn,+ ègún ni fún wọn níwájú Jèhófà, torí pé wọ́n ti lé mi jáde lónìí, kí n má bàa ní ìpín nínú ogún Jèhófà,+ wọ́n ń sọ pé, ‘Lọ, kí o sì sin àwọn ọlọ́run míì!’ 20  Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi kán sórí ilẹ̀ tí kò sí níwájú Jèhófà, nítorí ọba Ísírẹ́lì ti jáde lọ wá ẹyọ eégbọn kan ṣoṣo,+ àfi bíi pé ẹyẹ àparò ló ń lé lórí àwọn òkè.” 21  Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ pé: “Mo ti ṣẹ̀.+ Pa dà wá, Dáfídì ọmọ mi, mi ò ní ṣe ọ́ ní jàǹbá mọ́, torí pé o ka ẹ̀mí* mi sí ohun iyebíye+ lónìí yìí. Òótọ́ ni pé mo ti hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣe àṣìṣe ńlá.” 22  Dáfídì dáhùn pé: “Ọ̀kọ̀ ọba rèé. Jẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ sọdá wá mú un. 23  Jèhófà ló máa san òdodo àti ìṣòtítọ́ kálukú+ pa dà fún un, torí pé Jèhófà fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ lónìí, àmọ́ mi ò fẹ́ gbé ọwọ́ mi sókè sí ẹni àmì òróró Jèhófà.+ 24  Wò ó! Bí ẹ̀mí* rẹ ṣe ṣeyebíye sí mi lónìí, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀mí* mi ṣeyebíye lójú Jèhófà, kí ó sì gbà mí nínú gbogbo wàhálà.”+ 25  Sọ́ọ̀lù dá Dáfídì lóhùn pé: “Kí Ọlọ́run bù kún ọ, Dáfídì ọmọ mi. Ó dájú pé wàá gbé àwọn ohun ńlá ṣe, wàá sì borí.”+ Ìgbà náà ni Dáfídì bá tiẹ̀ lọ, Sọ́ọ̀lù sì pa dà sí àyè rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀; aginjù.”
Ní Héb., “gbóòórùn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”