Sámúẹ́lì Kìíní 31:1-13

  • Ikú Sọ́ọ̀lù àti ti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta (1-13)

31  Nígbà náà, àwọn Filísínì ń bá Ísírẹ́lì jà.+ Àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sá kúrò níwájú àwọn Filísínì, ọ̀pọ̀ lára wọn sì kú sórí Òkè Gíbóà.+  Àwọn Filísínì sún mọ́ Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn Filísínì sì pa Jónátánì,+ Ábínádábù àti Maliki-ṣúà, àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù.+  Ìjà náà le mọ́ Sọ́ọ̀lù, ọwọ́ àwọn tafàtafà bà á, wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára yánnayànna.+  Ni Sọ́ọ̀lù bá sọ fún ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pé: “Fa idà rẹ yọ, kí o sì fi gún mi ní àgúnyọ, kí àwọn aláìdádọ̀dọ́*+ yìí má bàa wá gún mi ní àgúnyọ, kí wọ́n sì hùwà ìkà sí mi.”* Àmọ́, ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ẹ̀rù bà á gan-an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú idà, ó sì ṣubú lé e.+  Nígbà tí ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra rí i pé Sọ́ọ̀lù ti kú,+ òun náà ṣubú lé idà tirẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀.  Bí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àti ẹni tó ń bá a gbé ìhámọ́ra pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ̀ ṣe kú pa pọ̀ ní ọjọ́ yẹn nìyẹn.+  Nígbà tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì tó ń gbé ní agbègbè àfonífojì* àti agbègbè ilẹ̀ Jọ́dánì rí i pé àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì ti sá lọ àti pé Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ;+ lẹ́yìn náà, àwọn Filísínì wá, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.  Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filísínì wá bọ́ àwọn nǹkan tó wà lára àwọn tí wọ́n pa, wọ́n rí Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n ti kú sórí Òkè Gíbóà.+  Wọ́n gé orí rẹ̀ kúrò, wọ́n bọ́ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ sí gbogbo ilẹ̀ àwọn Filísínì pé kí wọ́n ròyìn rẹ̀ ní àwọn ilé*+ òrìṣà wọn+ àti láàárín àwọn èèyàn náà. 10  Wọ́n wá gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sínú ilé àwọn ère Áṣítórétì, wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ ògiri Bẹti-ṣánì.+ 11  Nígbà tí àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì+ gbọ́ ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù, 12  gbogbo àwọn jagunjagun gbéra, wọ́n sì rìnrìn àjò ní gbogbo òru, wọ́n gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára ògiri Bẹti-ṣánì. Wọ́n pa dà sí Jábéṣì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀. 13  Wọ́n wá kó egungun wọn,+ wọ́n sin wọ́n sábẹ́ igi támáríkì ní Jábéṣì,+ wọ́n sì fi ọjọ́ méje gbààwẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “aláìkọlà.”
Tàbí “ṣe mí ṣúkaṣùka.”
Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “tẹ́ńpìlì.”